JÉSÙ ỌBA NÁÀ: Ètò Ìfọkànsìn fún Àjíǹde láti ọwọ́ Timothy KellerÀpẹrẹ
“Ọba Tí A Kàn M'ọ́gi”
Nígbàtí olórí àlùfáà bèèrè lọ́wọ́ Rẹ̀, “Ṣe ìwọ ni Krístì náà, Ọmọ Olùbùkún nì?” Jésú sọ pé, “Èmi ni.” Nípa ìdáhùn Rẹ̀ yìí, Jésù ńsọ pé: “Máà wá sí ayé nínú ògo tí Ọlọ́run gangan, Màá sì ṣe ìdájọ́ gbogbo ayé.” Ó jẹ́ gbólóhùn tó ya ni lẹ́nu. Ìfiaraẹni pe Ọlọ́run ní
Nínú gbogbo ohun tí Jésù ì báà sọ—bẹ́ẹ́ sì ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ àkọsílẹ̀, kókó-ọ̀rọ̀, àwòrán, àkàwé àti àyọkà Ìwé-mímọ́ l'édè Hébérù ló wà tí Ó lè lò láti sọ ẹni tí Òun jẹ́—Ó sọ ní pàtó pé Òun jẹ́ onídàjọ́. Nípa àṣànyàn ọ̀rọ̀ yìí, Jésù ń mọ́ọ̀mọ̀ mú wá rí àtakò tó wà níbẹ̀. Ìpàdí-ọrẹ́-dà ńlá lèyìí. Òun ni onídàjọ́ gbogbo ayé tí ayé wá ń dá lẹ́jọ́. Òun ni ó yẹ kí Ó wà lórí ìtẹ́ ìdájọ́, kí àwa sì wà nínú igi ìgbẹ́jọ́, nínú ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀. Ohun gbogbo ti d'orí k'odò.
Ní kété tí Jésú sọ pé Òun ni onídàjọ́ yìí, ní kété tí Ó sọ pé ọlọ́run ni Òun, ìdáhùn yìí búrẹ́kẹ́. Máàkù kọ̀wé rẹ̀ pé:
Jésù sì wípé, "Emi ni." "Ẹ̀yin ó sì rí Ọmọ-ènìyàn jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún agbára, yíó sì máa ti inú àwọsánmọ̀ ọ̀run wá." Nígbà náà ni olórí àlùfáà fa aṣọ rẹ̀ ya, ó wípé, "Ẹlẹ́rìí kíni a sì ń wá? Ẹ̀yin gbọ́ ọ̀rọ̀-òdì náà: ẹ̀yín ti rò ó sí?" Gbogbo wọn sì dá A lẹ́bi pé, Ó jẹ̀bi ikú. Àwọn mìráàn sì bẹ̀rẹ̀ síí tutọ́ sí I lára, àti síi bò Ó lójú, àti síi kàn Án lẹ́ṣẹ̀ẹ́, wọ́n sì wí fún Un pé, "Sọtẹlẹ!" Àwọn ẹ̀ṣọ́ sì ń fi àtẹ́lẹwọ́ wọn gbá A lójú.
(Máàkù 14:62–65)
Olórí àlùfáà fa aṣọ ara rẹ̀ ya, àmì ìrunú, ewu àti ọ̀fọ̀ ńlá nìyìí. Lẹ́yìn èyí gbogbo ìgbẹ́jọ́ náà d'ẹnu k'ọlẹ̀. Kódà kìí ṣe ìgbẹ́jọ́ mọ́ bíkòṣe ìjààgboro. Àwọn olùgbẹ́jọ́ àti adájọ́ bẹ̀rẹ̀ síí tutọ́ sí I lára wọn sì ń nà Á. Láàrín ìgbẹ́jọ́, wọn fàrígá gidi. Lójú ẹsẹ̀ ni wọn dá A lẹ́bi ọ̀rọ̀-òdì tí wọn sì ní O lẹ́ẹ̀tọ́ sí ikú.
Bíótilẹ̀jẹ́pé èmi àti ìwọ kò lè tutọ́ sí Jésù lójú ní sàn-án sàn-án, a sì lè fi ṣe ẹlẹ́yà kí a sì kọ̀ Ọ́. Àwọn ọ̀nà wo ní à ń gbà láti kọ Jésù l'Ọ́lọ́run?
Àyọkà kan láti inú ìwé JESUS THE KING, látọwọ́ Timothy Keller
A tẹ̀ ẹ́ padà ní ìbámu pẹ̀lú àdéhùn pẹ̀lú Riverhead Books, ọmọ ẹgbẹ́ Penguin Group (USA) LLC, A Penguin Random House Company. Àṣẹ ìkọ̀wé © 2011 látọwọ́ Timothy Keller
Àti láti inú ìwé JESUS THE KING STUDY GUIDE látọwọ́ Timothy Keller àti Spence Shelton, Àṣẹ ìtẹ̀jáde (c) 2015 látọ̀dọ̀ Zondervan, ẹ̀ka kan ti HarperCollins Christian Publishers.

Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Ònkọ̀wé atàwàràwàrà ilé ìtẹ̀wé New York Times tí ó tún jẹ́ oníwàásù Timothy Keller pín àwọn àkàwé àtẹ̀lé ra nípa ayé Jésù bí a ti nínú ìwé Máàkù. Tí a bá wo àwọn ìtàn yí fínnífínní, ó mú ìrína ọ̀tun wá sí ìbáṣepọ̀ tó wà láàrin ayé wa àti ayé ọmọ Ọlọ́run, títí lọ àkókò àjíǹde. JÉSÙ ỌBA NÁÀ ti di ìwé báyìí àti ìlànà ẹ̀kọ́ fún àwọn agbo kéékèèké, ó ńtà kiri ní gbogbo ilé ìtàwé.
More
Àyọkà láti inú àwọn ìwé Riverhead, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Penguin Random House, Ìlànà ẹ̀kọ́ láti ọwọ́ HarperCollins Christian Publishers. Fún àlàyé síi, jọ̀wọ́ lọsí: http://www.penguin.com/book/jesus-the-king-by-timothy-keller/9781594486661 or http://www.zondervan.com/jesus-the-king-study-guide