JÉSÙ ỌBA NÁÀ: Ètò Ìfọkànsìn fún Àjíǹde láti ọwọ́ Timothy KellerÀpẹrẹ
“Sísọ Kò-ṣeé-ṣé Di Ṣíṣe”
Nínú ibàpàdé yìí, Jésù ń fi yé wa wípé gbogbo wa pátá ni ayé yìí ló kù díẹ̀ káàtó—àmọ́ owó ní ipá láti mú wa kọ ojú-dídi sí òtítọ́ yìí. Kódà, owó ní agbára láti tàn wá jẹ láti mọ ipò wo ni ìgbé-ayé ẹ̀mí wa dé dúró tó pè fún ìwúlò ore-ọ̀fẹ́, àti ìfọwọ́tọ́ ìyanu láti mọ ǹkan tó ń ṣẹlẹ̀. Kò ṣeé ṣe láìsí Ọlọ́run, láìsí iṣẹ́ ìyanu. Láìsí ore-ọ̀fẹ́.
Ẹ wo bí Jésù ṣe gba ọ̀dọ́mọkùnrin yìí nímọ̀ràn. Bẹ́ẹ̀ni, ọkùnrin náà nílò ìmọ̀ràn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó jọ ènìyàn tí kò nílò ohunkóhun. O ní ọrọ̀, ọ̀dọ́mọkùnrin ni, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ arẹwà-ọkùnrin—kò wọ́pọ̀ fún ọ̀dọ́mọkùnrin tó lọ́rọ̀ láti ma rẹwà. Àmọ́ ǹkan kò fi gbogbo ara gún-régé fún un. Kání kò nílò ohunkóhun ni, ìbá má tọ Jésù wá láti béèrè wípé, “Kíni ẹ̀mí ní láti ṣe láti lè jèrè ayérayé?”
Kòsí ọmọ Júù kan tó jẹ́ olùfọkànsìn tí kò ní mọ ìdáhùn sí ìbéèrè yí. Àwọn olùkọ́ wọn máa ń sábà bèrè ìbéèrè yí nínú àkọsílẹ̀ àti ẹ̀kọ́ wọn. Èsì wọn kò sì fi ìgbà kankan tàsé rí; ẹnu wọ́n kò nípa èyí. Ìdáhùn rẹ̀ ni wípé “Ṣe ìgbọràn sí àwọn ìlànà Ọlọ́run kí o sì yẹra fún ẹ̀sẹ̀.” Ọ̀dọ́mọkùnrin náà ma mọ èsì yí. Èíṣe tí ó fi wá ń bèrè lọ́wọ́ Jésù?
Àkíyèsí tó hàn sí Jésù “Ohun kàn yìí ló kù ọ́ ku” ló jẹ́ kí a mọ irúfẹ́ ǹkan tí ń bá ọ̀dọ́mọkùnrin náà fínra. Ọkùnrin náà ń sọ wípé, “Ṣé ẹ ríi, mo ti ṣe ohun gbogbo bó ti yẹ: mo ti ṣe àṣeyọrí nípa ìṣúná, nípa ìbágbé láwùjọ, ìhùwàsí, àti nípa iṣẹ́ ìsìn. Mo ti gbọ́ wípé olùkọ́ rere ni ọ́, mo sì wá ń gbàárò bóyá ohun kan wà tó tàsé. Bíi ìgbà tí ǹkankan bá sì kù ló ń ṣe mí."
Lóòótọ́ ni ǹkankan sì kù. Nítorí ẹnikẹ́ni tó bá gbójú lé ǹkan tí wọ́n ńṣe láti lẹ́tọ̀ọ́ sí ìyè àìnípẹ̀kun máa ṣe àkíyèsí wípé, pẹ̀lú pẹ̀lú ohun gbogbo tí wọ́n ti gbé ṣe, òfìfo kan wà, àìbalẹ̀ ọkàn, àti iyèméjì. Ohun kan ma kù ni ṣá. Báwo ni ẹnikẹ́ni ṣe lè mọ̀ bóyá àwọn pójú àmì?
Báwo lo ṣe lè lépa àṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ láì kó sí páńpẹ́ tí ọrọ̀ máa ń dẹ? Àwọn ọ̀nà wo ni ìhìnrere ti gbà mú ìyípadà—tàbí lè gbà fa àyípadà—sí ìhà tí o kọ sí owó?
Àyọkà kan láti inú ìwé JESUS THE KING, látọwọ́ Timothy Keller
A tẹ̀ ẹ́ padà ní ìbámu pẹ̀lú àdéhùn pẹ̀lú Riverhead Books, ọmọ ẹgbẹ́ Penguin Group (USA) LLC, A Penguin Random House Company. Àṣẹ ìkọ̀wé © 2011 látọwọ́ Timothy Keller
Àti láti inú ìwé JESUS THE KING STUDY GUIDE látọwọ́ Timothy Keller àti Spence Shelton, Àdàkọ: Copyright (c) 2015 látọ̀dọ̀ Zondervan, ẹ̀ka kan ti HarperCollins Christian Publishers.

Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Ònkọ̀wé atàwàràwàrà ilé ìtẹ̀wé New York Times tí ó tún jẹ́ oníwàásù Timothy Keller pín àwọn àkàwé àtẹ̀lé ra nípa ayé Jésù bí a ti nínú ìwé Máàkù. Tí a bá wo àwọn ìtàn yí fínnífínní, ó mú ìrína ọ̀tun wá sí ìbáṣepọ̀ tó wà láàrin ayé wa àti ayé ọmọ Ọlọ́run, títí lọ àkókò àjíǹde. JÉSÙ ỌBA NÁÀ ti di ìwé báyìí àti ìlànà ẹ̀kọ́ fún àwọn agbo kéékèèké, ó ńtà kiri ní gbogbo ilé ìtàwé.
More
Àyọkà láti inú àwọn ìwé Riverhead, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Penguin Random House, Ìlànà ẹ̀kọ́ láti ọwọ́ HarperCollins Christian Publishers. Fún àlàyé síi, jọ̀wọ́ lọsí: http://www.penguin.com/book/jesus-the-king-by-timothy-keller/9781594486661 or http://www.zondervan.com/jesus-the-king-study-guide