Ìlàkàkà Mímọ́: Dìrọ̀mọ́ Ìgbé-Ayé Iṣẹ́-àṣekára, àti ti Ìsinmi Àpẹrẹ
Ìsinmi kò rọrùn fún mi nítorí iṣẹ́ àṣẹ kara ti mó mi lára. O ti pẹ tí mo ti ngbé pẹ̀lú aleebu yìí, tí o jẹ wípé nínú ọkàn mi mo tí wà gbàgbó wí pé bí mi o bá ṣiṣẹ, mo n kùnà. Àti wípé bí mo bá n kùnà, mí o já mo nkan kan. Sùgbón ní ọna kanna mo gbàgbó wí pé a le sin Ọlọrun nínú iṣẹ́ wa, mo gbàgbó wípé a n bu ọlá fún Ọlọrun nígbàtí a bá nsinmi
A ní láti ṣe díẹ díẹ, kí a lo àkókò nínú ọrọ Ọlọrun, kí a sì dáké jẹ béè, kí a lè gbọ ohùn Ọlọrun, èyí yíò fún wa lágbára láti se isẹ́ tí Ọlọ́run pè wá láti ṣe. Nígbà tí mo bá ṣiṣẹ fún gbogbo ọjọ́ lai sinmi, yóò rẹ̀ mi, mi kò sì ní pèsè àsìkò láti wà pẹ̀lú ebi mii, mi kò tún ní tọjú ara mi. Máà bẹrẹ sini ṣe àwọn ìpinnu ai ro nípa àwọn ètò mii, dipo kí nfi eti s'ilẹ kí Ọlọrun tọ mi sónà.
Charles Swindoll ko wípé, "Ọlọrun kò fẹ kí a dojú kọ laala ayé nípa ọgbọn wa, tàbí kí a gbẹkẹle agbára wa. Kò sì fẹ́ kí a máa wá ojú rẹ nípa àwọn ohun rere tí a ti ṣe. Ṣugbọn, o npè wá kí a wọnú ìsinmi rẹ̀."
Ọlọ́run ṣiṣẹ, o sì pè é ní dáradára, o sinmi o sì pè é ní mimọ
A pè wá láti darapọ pẹ̀lú rẹ nínú ìsinmi yìí, nítorí ní àwọn àkókò yìi a lè gbé àwọn ẹrù wuwo wa s'ilẹ, a lè gbé pẹlu rẹ̀, kí a sì máa ṣe àwọn ohun tí o dá wa láti ṣe, kí a lè fún ọkàn wa ní ìsinmi fún àwọn ọjọ tí o nbọ.
Télètélè mo má nsinmi lórí ijoko, maa jẹ ipapanu, tàbí kí n máa wo tẹlifísàn lai bikita. Sùgbón èyí kò rí bíi ìsinmi lójú mi. Mo má nro pé ìsinmi ní tòótọ́ já mo kí n má ṣe ohunkóhun Lọpọ ìgbà o tubọ rẹ mi síi, adidun ara ipapanu tí mo ti jẹ tún njẹ́ kí o rẹ mi síi, ara mi o sì fé se ohunkóhun rárá.
Ọna tí Olukaluku ngbà láti sinmi yatọ sí ara wọn. Mo ní àwọn ọrẹ tí o jé wípé eré s'isa l'owurọ, kí wón lè dáwà pẹ̀lú ara wọn àti èrò wọn, àti láti gbàdúrà ni o jẹ́ ìsinmi fún wọn. Mo tún ní àwọn ọrẹ tí o jẹ́ wípé kí won se apeje, se oúnjẹ, se àwàdà pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn ni o jẹ́ ìsinmi fún wọn. O si le jẹ́ wípé fún iwọ, kíkà ìwé, orin gbigbọ tàbí iṣẹ́ oko ni o fí n sinmi.
Ọlọrun dá wa pẹ̀lú abojuto tí o jẹ́ pé ọna tí a fi n sinmi náà ni ọna tí a fí n ṣiṣẹ
* * *
Bi o bá gbádùn àwọn ẹtọ yìí láti ọwọ́ Holy Hustle: Embracing a Work-Hard, Rest-Well Life by Crystal Stine, ti o sì fẹ mọ si nípa ìpinnu Ọlọ́run fún ayé rẹ̀, lọ sí https://amzn.to/2I3ow1d.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Iwọntunwọnsi. O jẹ ohun tí a nfẹ nínú ayé wa bí a se ngbo ariwo ti "iṣẹ́ asekara" létí kan, àti iṣọrọ kelekele ti "sinmi díẹ̀ sí" létí Kejì. Tó bá jẹ́ wípé èrò Ọlọ́run fún wa kìí kàn se ọna kan tàbí èkejì nkọ? Ẹjẹ́ kí a wo iṣẹ́ ṣíṣe ní ònà mimọ - ìgbé ayé tí Iṣẹ́ asekara àti isinmi dáradára ní àwọn ọ̀nà tí o bu Ọlá fún Ọlọrun.
More