Ìlàkàkà Mímọ́: Dìrọ̀mọ́ Ìgbé-Ayé Iṣẹ́-àṣekára, àti ti Ìsinmi Àpẹrẹ
Ní àárọ̀ ọjọ́ Àìkú kan a jókòó sórí ìjókòó tó ṣeé ká nínú yàrá-ìdárayá ilé-ìjọsìn wa, lẹ́yìn tí a ti pinu láti ṣe ìsìn ọjọ́ náà lọ́nà ìgbàlódé dípò irú èyí ta máa ńṣe nínú gbọ̀ngàn-ìjọsìn. Pẹ̀lú ìsìn òwúrọ̀ márùn-ún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ láti yàn nínú rẹ̀, ìjọ wa ti rí ọ̀nà láti jẹ́ ìríjú tí ó dára fún àmúlò ààyè, àwọn àlùmọ́ọ́nì, àti ìpéjọpọ̀ ènìyàn nípasẹ̀ ṣíṣe àgbékalẹ̀ àwọn ọ̀nà tí oníkálukú lè yàn tí yóò mú ogunlọ́gọ̀ wá pẹ̀lú ìdúróṣinṣin nínú ẹ̀kọ́ Bíbélì tó múná-dóko nínú gbogbo ẹ̀ka-ìránṣẹ́ wọn. O lè wà nínú yàrá-ìdárayá pẹ̀lú oníwàásù tó wọ sọmọdọ̀bọ, ṣùgbọ́n ìwàásù tí o máa gbọ́ yóò yanrantí bíi ti olùṣọ́-àgùntàn tó wọ kóòtù.
Ní Àìkú tó kọjá èmi àti ọkọọ̀ mi ń gbọ́ ìwàásù kan tó lágbára nípa ìtọrẹ-àánú. Lẹ́yìn ìjọsìn ọjọ́ náà ni oníwàásù bèrè ohun tí a ó ṣe pẹ̀lú $100 tí a kù gìrì ní—tí a sì lè ná bó ti wù wá. Kíni ẹbíi wa nílò jù ní àkókò náà? Báwo ni $100 yóò ti yí ìgbàa wa padà? Àwọn ènìyàn nínú ìjọsìn ọjọ́ náà sọ ǹkan mélòó kan—àwọn yóò ṣe ìtọ́jú ilé, ra aṣọ titun fún ilé-ìwé, ra oúnjẹ láti pín pẹ̀lú ẹbí lápapọ̀ àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ. Ṣùgbọ́n ní kọ̀ọ̀rọ̀ gbọ̀ngàn lọ́jọ́ náà láti rí obìnrin kan tó bú sẹ́kún bó ti ń gbìyànjú láti sọ̀rọ̀. Ó ní òhun yóò fi owó yìí kò àwọn ọmọ òhun lọ sí ilé ìgbafẹ́ tó ní odò-àtọwọ́dá fún àṣálẹ́ kan láti rẹ́ẹ̀rín, ṣeré àti ní ìtura, bó tilẹ̀ jẹ́ fún wákàtí díẹ̀, kúrò níbi ìjìyà àti ẹ̀rùu alaalẹ́ tí wọ́n ń kojú nílé. Ọ̀rọ̀ náà wá láti oókan àyà rẹ̀, ó sì jẹ́ ohun tó bani lọ́kàn jẹ́.
Olùṣọ̀ágùntàn ọjọ́ náà pe obìnrin yìí wá síwájú, ó fa $100 jáde látinú àpòo rẹ̀, ó sì fi fún-un. Láì retí ohun kan. “Ohun ojú mi tirí. Ohun ojú mi tirí,” èyí l'obìnrin yìí ń sọ pẹ̀lú omijé lójú. Àwọn ọmọ-ìjọ tó wà nítòsí dìde láti rọ̀gbà yíiká, láti pagbo àdúrà àti ìkíni-lẹ́yìn yí ọmọbìnrin náà ká bo ti ń sọkún. Wọn kò ṣètò fún irú nkan báyìí nínú ìjọsìn ọjọ́ náà, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ìpènijà tó lágbára.
Ǹjẹ́ ìwọ lè ṣe irúu ìrànlọ́wọ́ yìí? Ǹjẹ́ o lèlo $100 láti ru ẹlòmíràn sókè nínú ìbọláfún àti ìfẹ́ nípasẹ̀ bíbùkún fún wọn nígbà tí Ọlọ́run bá taọ́ lólobó láti “Fifún ni”? Bóyá o tilẹ̀ ní owó náà lọ́wọ́, tàbí o nílò láti ṣe àkójọ rẹ̀ fún oṣù mẹ́fà, ǹjẹ́ èmi àtìrẹ lè ṣe ìpinnu lónìí láti ṣiṣẹ́ lórí ìpènijà náà? Bí a ti ń ṣiṣẹ́ t'Ọ́lọ́run gbé ka iwájú wa, ẹ jẹ́ kí a ṣòótọ́ nínú iṣẹ́ ìríjú wa pẹ̀lú àwọn àlùmọ́ọ́nì tó ti ṣètò àti láti fihàn fún àwọn mìíràn wípé ìlàkàkà mímọ́ yàtọ̀ nítorí ó nííṣe pẹ̀lú ìtọ́jú àwọn ènìyàn ju iṣẹ́ ìsìn lásán.
Ìkáàánú ṣe pàtàkì.
Nípa Ìpèsè yìí
Iwọntunwọnsi. O jẹ ohun tí a nfẹ nínú ayé wa bí a se ngbo ariwo ti "iṣẹ́ asekara" létí kan, àti iṣọrọ kelekele ti "sinmi díẹ̀ sí" létí Kejì. Tó bá jẹ́ wípé èrò Ọlọ́run fún wa kìí kàn se ọna kan tàbí èkejì nkọ? Ẹjẹ́ kí a wo iṣẹ́ ṣíṣe ní ònà mimọ - ìgbé ayé tí Iṣẹ́ asekara àti isinmi dáradára ní àwọn ọ̀nà tí o bu Ọlá fún Ọlọrun.
More