Ìlàkàkà Mímọ́: Dìrọ̀mọ́ Ìgbé-Ayé Iṣẹ́-àṣekára, àti ti Ìsinmi Àpẹrẹ
Wọn a máa sọ wípé "ẹnìkan ló bímọ, igba ojú ló n wò" èyí kò já mó ìtọjú ọmọ nìkan, sùgbón a le lòó láti yí iṣẹ́ àṣẹ kara lásán padà sí ohun mimọ tí o bu ìyìn fún Ọlọrun
Ifiwera. Ifagagbaga. Ẹgbẹ. Tí mo bá n wo àwọn ọrọ nípa iṣẹ́ àṣẹ kára tí àwọn èniyàn n so lóde òní, ifiwera túmọ̀ sí kí a máa fi ìdí tí wọn fi yan wá dipo àwọn oludije wa hàn fún gbogbo ayé. Ifagagbaga túmọ̀ sí ìlàkàkà lairi láti ríi dájú pé ọjà a wa, iṣẹ́ wa, tàbí àwọn ọrọ wa kìí se èyí tí o dára jùlọ nìkan, sùgbón alailẹgbẹ jùlọ àti láti wa ṣáájú ẹnikẹni. O nkigbe wípé "Èmi ni mo kókó dé ibí!" Ẹgbẹ́ túmọ̀ sí ọrọ tí o wuyi fún àwọn onibara tí o di àwọn ibi-afede ti ìpolówó wa, títa ọjà, àti àwọn ìwé ìròyìn ímeèlì.
Léhìn tí mo ti ṣiṣẹ ní ibi ìtajà fún ọdún mẹwa, mo ti mọ. Ọpọlọ mi má padà sí àwọn ìtumò ode òní tí mo bá ti gbàgbé ìdí tí mo fi n ṣiṣẹ́. Kàkà kí n má ṣiṣẹ́ iransẹ, mo kàn n ta ọjà lásán àti pé ní ìlànà yìí ere níye lórí ju àwọn ènìyàn lo lójú mii. Sùgbón ọna mìíràn wa. Nínú iṣẹ́ ajé mimọ ase kára, ifiwera túmọ̀ sí kí a wo iṣẹ wa, kí a sì má bi Ọlọrun kí o fi bí o se bá ìfẹ rẹ mu àti bí kò se báa mu hàn wá. Báwo ni ase n fi ayé wa we ti Kristi, ẹni tí o yẹ kí a máa wo awokọṣe rẹ̀? Ifagagbaga o túmọ̀ sí wípé a gbọdọ rí dájú pé a sẹgun, ṣugbọn kí a máa wá ònà láti jẹ́ kí àwọn ẹlòmíràn yọrí sókè, kí a máa se jù wọn lọ pẹlu ibọwọ. Ẹgbẹ́ jẹ́ ohun èlò pàtàkì tí o ya iṣẹ mimọ ase kára sí ọtọ kúrò ní ọna tí ayé fi n ṣiṣẹ. O dàbí kí a máa ṣiṣẹ papọ, kí a máa se itọju, kí a máa bára ẹni sọrọ ju kí a saa máa wá onibara.
O le rí bíi iṣẹ idọti, sùgbón iṣẹ ase kára tọ fún ṣíṣe ẹgbẹ́. Ọlọrun o dá wa láti gbé ayé fún rara wa nìkan, èyí jẹ mọ́ iṣẹ́ wa náà. A o se iṣẹ́ púpò síi fún Ìjọba Ọlọrun nígbà tí a bá dawọ láti máa figagbaga tí a bẹrẹ sí ní sisé pọ.
Titẹle ariwo ọjà, ìbéèrè àti ìrètí ti ayé yóò fún wa ní aifọkanbalẹ bí a bá se n se àfiwé ipò tí awa nínú ero Ọlọrun pẹ̀lú ti àwọn tí owa ní àyíká wa. Dípò eléyìí, ejeki a yàn láti gbẹkẹle Ọlọrun, ẹni tí o mọn wá, tí o mọ ìgbà, báwo, àti ìdí, àti awe tí yíò lo láti se ohun ọtun àti ohun tí o fokanbale tí yíò pẹ́ fún gbogbo ọjọ ayé wa.
Mú ìpinu Ọlọrun fún ayé rẹ ní okunkundun kí osi gbéra sínú iṣẹ́ ase kára, ìsinmi dáadáa, àti gbígbé aye mimọ iṣẹ́ ase kára tí Ọlọrun pe o sí, ní ibití o wà.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Iwọntunwọnsi. O jẹ ohun tí a nfẹ nínú ayé wa bí a se ngbo ariwo ti "iṣẹ́ asekara" létí kan, àti iṣọrọ kelekele ti "sinmi díẹ̀ sí" létí Kejì. Tó bá jẹ́ wípé èrò Ọlọ́run fún wa kìí kàn se ọna kan tàbí èkejì nkọ? Ẹjẹ́ kí a wo iṣẹ́ ṣíṣe ní ònà mimọ - ìgbé ayé tí Iṣẹ́ asekara àti isinmi dáradára ní àwọn ọ̀nà tí o bu Ọlá fún Ọlọrun.
More