Ìlàkàkà Mímọ́: Dìrọ̀mọ́ Ìgbé-Ayé Iṣẹ́-àṣekára, àti ti Ìsinmi Àpẹrẹ
Ní àyíká ilé wa, Iṣẹ́ àṣe taratara kìí ṣe ọrọ tí o bani lérù.
O jẹ́ ohun tí mo má n ṣe.Bí a bá wo ìtumò isé àṣe taratara, gbogbo ohun tí o túmọ̀ sí jẹ́ "kí a ṣe iṣẹ́ ní kíákíá tàbí pẹ̀lú agbára". Njẹ́ eléyìí kò ha rán wa létí Kolose 3:23? "Ohunkóhun tí ẹ̀yin bá ń ṣe, ẹ máa fi tọkàntọkàn ṣe é fún Olúwa, kí í ṣe fún ènìyàn" (YCB). Bí mo bá tí nro pé mo ti ṣiṣẹ́ taratara jù, tí mo ṣì fẹ́ tẹle ìlànà tii ìsinmi àti ìtọjú tí o dàbí wípé o ti di gbajugbaja nísìsiyìí, mo má nri pé mo ti fẹ́ máa ṣe ọ̀lẹ. Bí mo bá tún gba ònà Kejì ti iṣẹ ase taratara, tí mo ṣì nṣiṣẹ́ lai dúró, tí kò tẹle ìtumò tí ayé fún iṣẹ́ ase taratara, mo nri pé o rẹmi.
Lọ́nà méjèèjì, lẹyìn gbogbo nkan, inú mi kìí dùn.
A nsin Ọlọrun tí o dá gbogbo ayé àti gbogbo ohun tí o wà lórí rẹ̀ láti inú asán ní ọjọ́ mẹfa. Ọlọrun ṣe awoṣe iṣẹ́ fún wa- iṣẹ́ pẹ̀lú agbára, atinuda, àṣe taratara, lẹ́yìn náà ìsinmi. Bí mo ṣe ti gbàdúrà nípa bí awoṣe yìí se bá iṣẹ́ Ìgbàlódé mu, Ọlọ́run fi àwọn ohun kan hàn mí:
- Iṣẹ́ àṣẹ taratara kò burú bí a bá nṣee fún ohun tí o bu ògo fún Ọlọrun tí o sì jẹ́ fún ìjọba rẹ̀.
- Ọrọ Ọlọrun se àpẹrẹ ìbùkún tí o wà nínú iṣẹ́ àṣẹ taratara.
- A kọ le gbé gbogbo ayé wa pẹ̀lú awoṣe ọjọ́ mẹfa kínní kí a f'ojú fo ọjọ́ keje.
Iṣẹ àṣẹ taratara kò túmọ̀ sí kí a jẹ gaba lórí àwọn tí a jọ nṣiṣẹ́, kìí síi se iṣẹ́ nípa ti ara wa nìkan. Iṣẹ mímọ̀ ti àṣẹ taratara jé sise iṣẹ́ taratara bí Kolose 3:23 ṣe pàṣẹ, kí a má gbé ní ònà tí Ọlọrun fi wá sí àti kí a ṣe àwárí iwontunwonsi iṣẹ́ àti ìsinmi.
L'oni, wá àyè láti gbàdúrà nípa iwontunwonsi iṣẹ́ àti ìsinmi tìrẹ. Bèèrè lọwọ Ọlọrun kí o fi hàn ọ́ ọna tàbí igbesẹ tí kò sí nínú ìfẹ́ rẹ̀ fún ayé rẹ̀, àwọn ibi tí o ti nṣiṣẹ taratara pẹ̀lú ìsinmi kékeré, tàbí ibi tí ìsinmi ti pọju iṣẹ́ lọ. Lo àsìkò láti kọ àwọn ìpinnu rẹ sínú ìwé, gbogbo ohun tí o fẹ́ ṣe, bóyá ní ọdún tí o nbọ, gbé gbogbo ìpinnu yìí lé Ọlọrun lọwọ ní kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́.
Yọ gbogbo ohun tí o bá ní kí o yọ kúrò, kí o ṣàfikún gbogbo ohun titun tí o bá fi s'ọkan rẹ. Bèèrè kí Ọlọrun fi bí iwọ yóò ṣe gbé orúkọ rẹ̀ ga nínú iṣẹ́ tí o nṣe, kí o sì bèèrè fún Idariji fún àwọn ìgbà tí o jẹ́ pé okanjuwa, a fẹ́ ní okiki, tàbí ifagagbaga ni o jẹ́ ìwúrí fún ọ láti ṣe iṣẹ́.
* * *
Àwọn ètò yìí wá láti Holy Hustle: Embracing a Work-Hard, Rest-Well Life by Crystal Stine. Ti o bá fẹ́ kó sí nípa bí a se nṣiṣẹ́ láìsí itiju àti ìsinmi láìsí ẹsẹ, lọ sí https://amzn.to/2I3ow1d.
Nípa Ìpèsè yìí
Iwọntunwọnsi. O jẹ ohun tí a nfẹ nínú ayé wa bí a se ngbo ariwo ti "iṣẹ́ asekara" létí kan, àti iṣọrọ kelekele ti "sinmi díẹ̀ sí" létí Kejì. Tó bá jẹ́ wípé èrò Ọlọ́run fún wa kìí kàn se ọna kan tàbí èkejì nkọ? Ẹjẹ́ kí a wo iṣẹ́ ṣíṣe ní ònà mimọ - ìgbé ayé tí Iṣẹ́ asekara àti isinmi dáradára ní àwọn ọ̀nà tí o bu Ọlá fún Ọlọrun.
More