Ìlàkàkà Mímọ́: Dìrọ̀mọ́ Ìgbé-Ayé Iṣẹ́-àṣekára, àti ti Ìsinmi Àpẹrẹ
Àwọn ohun isere ọmọdé pọ nínú ilé wa. A bèrè sí ní ko wọn jọ ní àsìkò kérésìmesì ọdún kan sẹyin, nisisiyi a ti ní àkójọ àwọn ohun isere yìí l'ọna púpò. Bí ọmọbìnrin wa bá ti nto áwọn ohun isere yìí, o má n kókó lo àwọn tí o tóbi. Àwọn kan wà tí yóò kọkọ bẹrẹ sí ní lò, àwọn yẹn ni wọ́n bo gbogbo áwọn ohun iṣere kékèké mọlẹ, àwọn yìí kékeré ṣùgbọ́n wọ́n ní iṣẹ́ tí wọ́n n se.
Nígbà míràn mo fẹ́ láti rí bíi àwọn ohun isere èyí tí o tóbi jù, àwọn tí oseeri nítorí i bí wọn se tóbi. Sùgbón àwọn ohun isere títóbi kò fi bẹ́ẹ̀ yatọ tí a bá ti to wọ́n tan, kò rí bí a ṣe rò wípé wọn máa rí. Bí mo bá tí n sa àwọn ohun isere oríṣiríṣi yìí, mo rí wípé àwọn tí o kékeré ni wón ṣe pàtàkì jù.
Àwọnike kékèké, tí wọn fẹ ṣé má ri ni wón fí n kọ ojú fèrèsé.
Nínú àwọn ohun isere yìí, a nfi àwọn míràn kọ òrùlé àti àwọn tábìlì.
A nfi àwọn kan to ènìyàn, àwọn míràn ni a nfi to ẹsẹ.
Nígbà púpò èmi ni ẹya tí o nṣe ìrànwọ́ kékèké. Èmi ni ènìyàn tútù tí àwọn tí wọ́n loyaya má n bo mọlẹ. Èmi ni mo má nrò pé wọ́n le tètè fi ẹlòmíràn rọ́pò iṣẹ́ tí mo nṣe, tàbí tí mi o wúlò fún àṣeyọrí ohun tí wọ́n nṣẹ. Ẹni tí a fẹ́, ṣùgbọ́n tí kìí ṣe dandan. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run jẹ́ alaanu, o mọọmọ ṣẹda ẹ̀yà ara Kristi ní ọkọọkan kí a lè nilo gbogbo ẹya. Kò sí bí o ṣẹ kékeré tàbí tí o tóbi.
Njẹ́ iwọ rí ara rẹ bíi ẹya kékeré nínú gbogbo àwọn ẹ̀yà? Ṣé kò tíì dá o lójú wípé àwọn nkan lásán, ìdòtí le jẹ́ ara iṣẹ́ ìjọba mimọ tí ọkàn rẹ fẹ fún ayé? Njẹ́ o jẹ́ ìyàlẹ́nu fún o bí Iwọ ṣe lè wà ní ibi tí Ọlọ́run pè o sí nígbàtí kò tíì dá o lójú wípé iṣẹ́ tí a fún ọ kò dára tó.
Ìdúró rẹ àti Ìrètí rẹ ṣe pàtàkì. Bóyá àwa ni eya tí o seeri jù nínú gbogbo àwọn ìyókù(tí o nràn àwọn yòókù lọwọ b wọn o ṣe dúró sinsin!) Tàb èyí tí o kékeré jùlọ( tí o n tàn). A nyin Ọlọrun l'ogo bí a ba korajo fún ìjọba rẹ̀ A kò le rọpo rẹ, a ti fún ọ tí ohun tí o tó, o sì ṣe iyebiye fún iṣẹ ti Ọlọrun ti ṣètò fún ọ. Nínú Kristi, a lè ṣe síi ju bí a ṣe lérò.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Iwọntunwọnsi. O jẹ ohun tí a nfẹ nínú ayé wa bí a se ngbo ariwo ti "iṣẹ́ asekara" létí kan, àti iṣọrọ kelekele ti "sinmi díẹ̀ sí" létí Kejì. Tó bá jẹ́ wípé èrò Ọlọ́run fún wa kìí kàn se ọna kan tàbí èkejì nkọ? Ẹjẹ́ kí a wo iṣẹ́ ṣíṣe ní ònà mimọ - ìgbé ayé tí Iṣẹ́ asekara àti isinmi dáradára ní àwọn ọ̀nà tí o bu Ọlá fún Ọlọrun.
More