Ìlàkàkà Mímọ́: Dìrọ̀mọ́ Ìgbé-Ayé Iṣẹ́-àṣekára, àti ti Ìsinmi Àpẹrẹ
Gbígba ìhà àti ìrísí titun nípa ìlàkàkà ma ń gba àkókò. Ṣùgbọ́n tó bá jẹ́ ti ìyípadà àti àwọn ohun ọ̀tun tí Ọlọ́run fẹ́ gbé ṣe láyé wa, ọ̀kan nínú ohun méjì ni a lè yàn: fàsẹ́yìn tàbí lépa ìdàgbàsókè. Èmi gẹ́gẹ́bí ẹnìkan ma ń gbà wípé fífà sẹ́yìn ló suwọ̀n jù àfi tí Ọlọ́run bá fi ìwúrí hàn sími. Nígbà tí ìyípadà bá ń bamileru, ìdí rẹ̀ ni wípé mò ń gbójúlé ipáà mi láti yege. Mo máa ń lérò wípé mo lè dá mú ohun gbogbo ṣiṣẹ́ sì rere, láti ri wípé ó yanjú sí àṣeyọrí, láti ri wípé a kò rí mi bíi aláìmọ̀ọ̀ọ́ṣe—l'ẹ́ẹ̀kan si. Nígbà tí mo bá yàn láti fàsẹ́yìn èyí jẹ́ nítorí à ń muwá sí ìrántí mi wípé tí a bá dá mi dáa, nínú ìsapá mi, nkò nílè mu yọrí sí bí motifẹ́.
Nígbà náà ni n ó wá kò ìsapá mi ni ìjánu tí n ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í lépa, ní ìjẹ́rìí wípé Ọlọ́run ńṣe ètò fún ohun ọ̀tun nítorí Ó ní àwọn ètò rere fún mi, àwọn ètò tí yóò mú ògo Rẹ̀ búyọ tí yó sì mú ìjọba Rẹ̀ gbèrú síi.
Ǹjẹ́ ìwọ ma lọ ní ipasẹ̀ tóti làálẹ̀ fún ọ, níbi tí ìlàkàkà mímọ́ yóò ti rọ́pò ìsapá asán? Tàbí ìwọ yóò fàsẹ́yìn, ní ìfẹ́ sí ìtura ohun tí a mọ̀ ju ìnira ìgbà tí a kò mọ?
Àwọn ìdánilójú mẹ́ta nìyí tí a lè fi ìgboyà mú dání pẹ̀lú wa lọ sí ọjọ́ọ-wájú: Ọlọ́run kò tíì parí iṣẹ́ lórí wa, Ó ṣe tán láti ṣe ohun titun, àti wípé yóò wà níbẹ̀ pẹ̀lú wa bí a ti ńgbé ìṣísẹ̀ kàànkan.
Ìlàkàkà mímọ́ a máa gbà wá láàyè láti ṣiṣẹ́ takuntakun pẹ̀lú gbogbo ipáa wa lórí àwọn iṣẹ́ tí Ọlọ́run ti fífún ìṣẹ̀dá wa. Èyí jẹ́ iṣẹ́ ọkàn, iṣẹ́ tó ní ipa nínú ìjọba Ọlọ́run. Èyí fún wa ní àyè láti mọ̀ wípé iṣẹ́ tí àwọn mìíràn ńṣe yẹ wọ́n, ṣùgbọ́n kò ríbẹ̀ fún àwa, pàápàá lásìkò yí. Ìlàkàkà mímọ́ a máa ràn wá lọ́wọ́ láti lè gbọ́ Ọlọ́run nínú gbogbo ariwo ayé yìí, kí a ba lè jẹ́ Ọlọ́run ní òho fún gbogbo iṣẹ́ tó ti pèsè ọkàn wa sílẹ̀ fún àti rárá sí àwọn iṣẹ́ tó lè ṣe ìṣẹ̀dá wa ni jàmbá.
Ààlà tówà láàrín ìlàkàkà àti ìsapá-asán, ìsinmi àti ìmẹ́lẹ́, jẹ́ ibi to léwu láti fi ìkàlẹ̀ sí. Nígbà tí a bá fì sápá kan, la ó bẹ̀rẹ̀ sí ní gbójú lé ipáa tiwa dípò mímú wá sí ìrántí wípé Òhun ni ipáa wa. Gbèdéke ìlàkàkà yìí kìí ṣe fún fífi àyè sílẹ̀ lóóòjọ́ láti lè ṣe ju tàná lọ, bíkòṣe láti ṣe àwárí ohun tí Ọlọ́run ń pè wá láti ṣe fún ìsìn síwájú síi, láti fifún-ni síi, gbani níyànjú síi—ni àwọn ọ̀nà àti ibi tíó tọ́.
Nípa Ìpèsè yìí
Iwọntunwọnsi. O jẹ ohun tí a nfẹ nínú ayé wa bí a se ngbo ariwo ti "iṣẹ́ asekara" létí kan, àti iṣọrọ kelekele ti "sinmi díẹ̀ sí" létí Kejì. Tó bá jẹ́ wípé èrò Ọlọ́run fún wa kìí kàn se ọna kan tàbí èkejì nkọ? Ẹjẹ́ kí a wo iṣẹ́ ṣíṣe ní ònà mimọ - ìgbé ayé tí Iṣẹ́ asekara àti isinmi dáradára ní àwọn ọ̀nà tí o bu Ọlá fún Ọlọrun.
More