Ìlàkàkà Mímọ́: Dìrọ̀mọ́ Ìgbé-Ayé Iṣẹ́-àṣekára, àti ti Ìsinmi Àpẹrẹ

Holy Hustle: Embrace A Work-Hard, Rest-Well Life

Ọjọ́ 6 nínú 10

Tí o bá ti wo eré ti akọle rẹ̀ njẹ Monsters, Inc., Iwọ yíò mọ ohun tí mo nṣọ nígbàtí mo sọ wípé ìrìn àjò ayé mi rí bíi apá kan nínú eré náà. Mike, Sulley, àti Boo n mi jolojolo lori okùn tí o kún fún ẹgbẹgbẹrun ìlèkùn. Ṣùgbọ́n wọn o kàn le ṣí ikankan nínú àwọn ìlèkùn yìí. Tí wọ́n bá sí ìlèkùn tí kò yẹ kí wọ́n sí, yíò já wọn sí inú òtútù tó lágbára tàbí ile oorun aṣálẹ̀. Wọ́n gbọ́dọ̀ sí èyí tí yíò mú wọn lọ sí ònà ilé. Nítorí ìdí èyí, wọ́n dúró pèlú gbogbo agbára wọn, wọ́n n bá ọta tí o fẹ́ sì wọ́n l'ọna, tí o fẹ́ ṣe wọ́n ní ewu, títí tí wọn o fi dé ibi ìlèkùn kan tí wọ́n mọ pé o jẹ́ ibi isadi fún wọn.

Ẹ̀rọ ayélujára fún wa ní ànfàní láti rí àwọn ìlèkùn tí Ọlọ́run n sí fún àwọn ènìyàn káàkiri àgbáyé, a sì ti gbàgbé ìlèkùn kan tí Olórun fẹ́ kí a tẹ pẹ̀lú ìgbàgbọ́. Kìí ṣe gbogbo ìlèkùn ni o jẹ́ tiwa, kìí sì í ṣe gbogbo ìlèkùn tàbí ọna ló já sí ilé.

Mo ti lo bíi ọdún mẹwàá nínú laala láti se àṣeyọrí - bí mo ṣe jáde ní ilé ìwé gíga, mo wá iṣẹ́, mo gbeyawo, mo n ṣe gbogbo è nínú wàhálà tí ayé túmọ̀ sí iṣẹ́ asekara, mo pàdánù iṣẹ́ mii, mo se wàhálà láti wá ohun tó sẹku fúnmi láti ṣe, mo bẹrẹ iṣẹ́ titemi, mo bẹrẹ iṣẹ́ iransẹ tí o lágbára púpọ̀, iṣẹ́ iransẹ yìí dára, o sì tún jẹ́ kí n dá wà lásán, mo kúrò níbi isé iransẹ yìí, motun dá iṣẹ́ kan sílẹ̀ làti le tọju ìdílé mii.

Mo ti lo ọpọ ìgbà tí mo ṣì n gbìyànjú kí n má ṣ'ofo àwọn ànfàní tí o sí sílè, ṣùgbón èyí kò jẹ́ kí n rí àwọn ìlèkùn tí Ọlọrun n sí sílẹ̀ fún mi ní gbogbo ọ̀nà mii.

Bí mo ṣe bẹrẹ sínú kọ bí a ṣe n jọwọ gbogbo nkan sílè fún Ọlọrun, Ọlọrun fí èrò kan simi l'ọkan tí o yí gbogbo nkan padà. Mo ti n wá àwọn ọna tí yíò dára fún mi, mo n lo gbogbo imọ miàti wọn ọna tí mo rò pé o tóbi, tí o sì dára jù.

Ní àwọn ìgbà tí mo n gbìyànjú lásán nínú ara, mo tilẹ̀ le máa ṣiṣẹ́ fún ara mii, ṣùgbón Ọlọrun jẹ́ olóòótọ tí o sì n tẹsi iwájú, tí o n ṣiṣẹ́ nínú mii. Àwọn ọgbọn tí a kọ, ìmọ̀ tí a gbà, àwọn ènìyàn tí a n pàdé, àti ìdàgbàsókè tí a ní lè jẹ́ ìbùkún. Ọlọ́run ti fún wa ní ààyè láti gbèrò ọna tí a o tọ láì ṣe àníyàn wípé a o bá ara wa ní ọna tí kìí ṣe ìfẹ e rẹ̀ ní odi keji. Oseese kí a ma bá ara wa nínú iṣẹ́ àsàyàn tí o pé, tàbí iṣẹ́ tí o jọ pé o jẹ́ ìpè Ọlọ́run fún wa, ṣùgbọ́n Ọlọrun yóò bá wa níbẹ̀.

Ọjọ́ 5Ọjọ́ 7

Nípa Ìpèsè yìí

Holy Hustle: Embrace A Work-Hard, Rest-Well Life

Iwọntunwọnsi. O jẹ ohun tí a nfẹ nínú ayé wa bí a se ngbo ariwo ti "iṣẹ́ asekara" létí kan, àti iṣọrọ kelekele ti "sinmi díẹ̀ sí" létí Kejì. Tó bá jẹ́ wípé èrò Ọlọ́run fún wa kìí kàn se ọna kan tàbí èkejì nkọ? Ẹjẹ́ kí a wo iṣẹ́ ṣíṣe ní ònà mimọ - ìgbé ayé tí Iṣẹ́ asekara àti isinmi dáradára ní àwọn ọ̀nà tí o bu Ọlá fún Ọlọrun.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Crystal Stine àti ilé-iṣẹ́ẹ Harvest House Publishers fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú si, jọ̀wọ́ lọ sí: https://www.harvesthousepublishers.com/books/holy-hustle-9780736972963