Ìlàkàkà Mímọ́: Dìrọ̀mọ́ Ìgbé-Ayé Iṣẹ́-àṣekára, àti ti Ìsinmi Àpẹrẹ
Njẹ́ iwọ má nro bóyá o nṣe ohun tí o tọ? Tàbí bóyá o wà ní ibi tí Ọlọ́run fẹ́ kí o wà? Tàbí bóyá ohun kan wà tí iwọ o tíì gbámú, tí o pọju bí o se wà, tàbí tí o yatọ, tàbí tí o dára jù, tàbí ti o tóbi ju bí o se wà? Tàbí bóyá o nro wípé ipe rẹ̀ níye bí àwọn àsìkò tí iwọ nrò pé o o tíì kún ojú osunwon.
Àwọn ìgbà púpò ni ìgbésí ayé má nri bí ìgbàtí a wà nínú yàrá kàn tí kò sí iná kankan, tí a sì nwa fìtílà, tàbí iná láti darí ìgbésẹ̀ wa. Ní inú àwọn àkókò báyìí, gbẹkẹle Ọlọrun. Di ọwọ rẹ mú ṣinṣin kí o sì gbagbọ wípé yíò darí rẹ̀ sí ọ̀nà tí okan tí o ti pèsè fún o láti gbà. Kò ye kí eru òkùnkùn yí b'awa nígbàtí aní imọlẹ ayé l'ẹgbẹ wa tí a lè bá rìn.
Sùgbón gbogbo àwọn ìbéèrè tí o nbi ara rẹ o lòdì sí ìbéèrè tí o yẹ kí ènìyàn bi ara rẹ̀. Kò yẹ kí àwọn ìbẹrù àti ìṣòro rẹ jẹ́ ohun itiju. Bí gbogbo wa bá le joko papọ̀ láti sọ nípa iṣẹ́ wa, àwọn ohun tí a féràn láti se àti ìgbàgbọ́ wa, yíò jé ohun ìyàlẹ́nu tí a bá rí ẹnikan tí o sọ wípé gẹgẹ bí òhun se pinnu ni ayé òhun já sí. Kínni iwọ yóò sọ fún ọrẹ tí o bá bi ọ ní irú àwọn ìbéèrè wọ̀nyí?Njẹ́ iwọ yóò sọ fún wípé tootọ ni gbogbo ìbéèrè rẹ já sí, kí o jọwọ ìlépa sílẹ̀?
I Mo n'ireti pé iwọ kò ní sọ irú nkan báyìí fún ọrẹ rẹ.
A o féràn rẹ, a o sí gbàdúrà fún. A o gbàá níyànjú, a o sì wá ònà láti sọ fún wípé ohun tí o nṣe dára, o tọ, o sì níye lórí, tí o bá sì mọ̀ nínú èmí rẹ wípé ibi tí Ọlọ́run fẹ́ kí o wà ní àsìkò ayé rẹ ni o wà, nigbanaa kòsí àṣìṣe.
Èmí gbàgbọ́ nítòótó wípé Ọlọrun má n mú ohun irẹlẹ, yíò sì sọ di mimọ, a ti wípé ìgbọràn (kìí ṣe ní títóbi, liloruko, tàbí ti idanimọ) ni o se pàtàkì nínú ipa tí a ní nínú iṣẹ́ ti ìjọba Ọlọrun tí a nse
Ọlọrun jẹ́ olotitọ nínú gbogbo ohun tí o nṣe. Ibi tí o wà, ohun tí o nṣe, àti àwọn ènìyàn tí o wà níwájú rẹ, tí Ọlọrun ti sọ wípé kí o se iṣẹ́ iransẹ fún kò nṣe àṣìṣe. Àwọn ìṣòro, ibanujẹ, ikuna kìí se àsìse.
Ọlọ́run yóò lo gbogbo ẹsẹ irin-ajo wa láti tan ògo rẹ̀.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Iwọntunwọnsi. O jẹ ohun tí a nfẹ nínú ayé wa bí a se ngbo ariwo ti "iṣẹ́ asekara" létí kan, àti iṣọrọ kelekele ti "sinmi díẹ̀ sí" létí Kejì. Tó bá jẹ́ wípé èrò Ọlọ́run fún wa kìí kàn se ọna kan tàbí èkejì nkọ? Ẹjẹ́ kí a wo iṣẹ́ ṣíṣe ní ònà mimọ - ìgbé ayé tí Iṣẹ́ asekara àti isinmi dáradára ní àwọn ọ̀nà tí o bu Ọlá fún Ọlọrun.
More