Ìlàkàkà Mímọ́: Dìrọ̀mọ́ Ìgbé-Ayé Iṣẹ́-àṣekára, àti ti Ìsinmi Àpẹrẹ
![Holy Hustle: Embrace A Work-Hard, Rest-Well Life](/_next/image?url=https%3A%2F%2Fimageproxy.youversionapi.com%2Fhttps%3A%2F%2Fs3.amazonaws.com%2Fyvplans%2F11797%2F1280x720.jpg&w=3840&q=75)
Mo ti ka ìtàn Rúùtù nínú Bíbélì lọ́pọ̀ ìgbà sẹ́yìn, ṣùgbọ́n lọ́jọ́ Àìkú kan mo ṣe àkíyèsí ohun tí nkò lérò. Rúùtù ò kàn ṣe iṣẹ́ ràlẹ̀-rálẹ̀ tóbá rí. Ó làkàkà. Ó ṣiṣẹ́ kárakára, pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀, pẹ̀lú ìsinmi nígbà tí ó yẹ, àti píparí gbogbo ìṣe tí a gbé ka iwájú rẹ. Ó máa ń ṣiṣẹ́ di àṣálẹ́, tí yóò sì kórè ìṣùwọ̀n mẹ́rìn-dín-lọ́gbọ̀n ọkà-báálì fún ìtọ́jú ebíi rẹ̀. Rúùtù ò sá fúnṣé, Ọlọ́run pẹ̀lú wá ṣètò ìlànà fún ayée rẹ̀ èyí tí ó yọrí sí ìgbéyàwó rẹ̀ pẹ̀lú Bóásì àti ìmúbọ̀sípò rẹ̀ nínú ìran Jésù.
Ìlàkàkà mímọ́ ni èyí. Kìí ṣe gbajúmọ̀ tàbí òkìkí lómú ìwúrí bá Rúùtù. Ìkórè ọkà kò rọrùn, iṣẹ́ ẹ̀yìn tún ni. Kìí ṣe ohun tí à ń fakọ ṣe. Iṣẹ́ tíí rẹni sílẹ̀ ni. Iṣẹ́ẹ Rúùtù ní ìtumọ̀ àti àmúlò, mo sì lérò wípé iṣẹ́ tiwa pẹ̀lú ni àwọn àmúyẹ wọ̀nyí.
Kání ṣeni Rúùtù wò yíká ilé kékeré tí ohun àti Náómì ń gbé tó sì wá fi àìní wọn ṣe àfojúsùn rẹ̀ dípò ohun tí ó lè gbé ṣe? Kání ṣeni Rúùtù jáde láti wá iṣẹ́ tí yóò múu dàbí ènìyàn pàtàkì dípò iṣẹ́ tí yóò fi sí ipò tí Ọlọ́run fẹ́ kí ó wà? Óṣeéṣe kíó tipasẹ̀ èyí pàdánù ìkórè náà pátápátá, tòun ti ìbùkún tí Ọlọ́run ti ṣètò láti fi fún-un bí A ti ra ẹbíi rẹ̀ padà.
Ó lè má rọrùn láti jáde fún iṣẹ́ àṣekára tí Ọlọ́run ti pèwá sí. Bóyá a ti pè ọ́ láti ṣiṣẹ́ níbi tí kò bọlá f'Ọ́lọ́run tààrà, o sì wá dà bíi àjèjì ní ilẹ̀-òkèèrè láàárín wọn. Tàbí bóyá ṣeni Ọlọ́run mú ọ wá sí ibi titun, tí a sì ti rọ́pò ìpinnu rẹ láti ṣiṣẹ́ tí yóò mú ka dá ọ mọ̀ nínú òkìkí pẹ̀lú ìpè láti ṣiṣẹ́ ní ibi kọ̀rọ̀ tí kò mú òkìkí dání. Bóyá ṣeni ìwọ ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ìsòótọ́ ni àyè tí o fẹ́ràn ṣùgbọ́n àìsí èso tàbí ìwúrí fún iṣẹ́ yìí tí mú ọ rẹ̀wẹ̀sì.
Àfi tí a bá bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe ìsìn tí a sì pa ìlàkàkà asán tí, kí a tó lè jẹ́rìí Ọlọ́run fún ìkórè ohun tí a ti gbìn pẹ̀lú ìsòótọ́. Ìkáàánú tí o bá ṣe níbiṣẹ́ lè jẹ́ ohun tí yóò mú ẹnì kan fà súnmọ́ Ọlọ́run. Ìfẹ́ òtítọ́, àìlẹ́tàn tí o fihàn sì àwọn mìíràn lè jẹ́ àtẹ̀gùn tí Ọlọ́run yóò lò láti fà wọ́n mọ́ra. Àti àwọn irúgbìn tobá gbìn lè jẹ́, ohun tí yóò rú ẹ̀bùn tí Ọlọ́run fẹ́ fún ọ̀pọ̀ ènìyàn lẹ́yìn rẹ jáde, ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìran lẹ́yìn tobá kúrò láyé, fi ayéè rẹ ṣe ìfilọ́lẹ̀ ẹ̀bùn tó rẹwà tí Ọlọ́run fẹ́ pín fún aráyé.
Nípa Ìpèsè yìí
![Holy Hustle: Embrace A Work-Hard, Rest-Well Life](/_next/image?url=https%3A%2F%2Fimageproxy.youversionapi.com%2Fhttps%3A%2F%2Fs3.amazonaws.com%2Fyvplans%2F11797%2F1280x720.jpg&w=3840&q=75)
Iwọntunwọnsi. O jẹ ohun tí a nfẹ nínú ayé wa bí a se ngbo ariwo ti "iṣẹ́ asekara" létí kan, àti iṣọrọ kelekele ti "sinmi díẹ̀ sí" létí Kejì. Tó bá jẹ́ wípé èrò Ọlọ́run fún wa kìí kàn se ọna kan tàbí èkejì nkọ? Ẹjẹ́ kí a wo iṣẹ́ ṣíṣe ní ònà mimọ - ìgbé ayé tí Iṣẹ́ asekara àti isinmi dáradára ní àwọn ọ̀nà tí o bu Ọlá fún Ọlọrun.
More