Rut 2:5-7

Rut 2:5-7 YBCV

Nigbana ni Boasi wi fun iranṣẹ rẹ̀ ti a fi ṣe olori awọn olukore pe, Ọmọbinrin tani yi? Iranṣẹ na ti a fi ṣe olori awọn olukore dahùn, o si wipe, Ọmọbinrin ara Moabu ni, ti o bá Naomi ti ilẹ Moabu wa. O si wipe, Emi bẹ̀ ọ, jẹ ki emi ma peṣẹ-ọkà, ki emi si ma ṣà lẹhin awọn olukore ninu ití: bẹ̃li o wá, o si duro ani lati owurọ̀ titi di isisiyi, bikoṣe ìgba diẹ ti o simi ninu ile.