RUTU 2:5-7

RUTU 2:5-7 YCE

Boasi bèèrè lọ́wọ́ ẹni tí ó jẹ́ alákòóso àwọn tí ń kórè, ó ní, “Ọmọ ta ni ọmọbinrin yìí?” Iranṣẹ rẹ̀ náà bá dá a lóhùn, ó ní, “Obinrin ará Moabu, tí ó bá Naomi pada láti ilẹ̀ Moabu ni. Ó bẹ̀ wá pé kí á jọ̀wọ́ kí á fún òun ní ààyè láti máa ṣa ọkà tí àwọn tí wọn ń kórè ọkà bá gbàgbé sílẹ̀. Láti àárọ̀ tí ó ti dé, ni ó ti ń ṣiṣẹ́ títí di àkókò yìí láìsinmi, bí ó ti wù kí ó mọ.”