Rutu 2:5-7

Rutu 2:5-7 YCB

Boasi sì béèrè lọ́wọ́ olórí àwọn olùkórè wí pé, “Ti ta ni ọ̀dọ́mọbìnrin yẹn?” Ìránṣẹ́ tí ó jẹ́ olórí àwọn olùkórè náà sì fèsì pé, “Ọ̀dọ́mọbìnrin ará Moabu tí ó tẹ̀lé Naomi wá láti ilẹ̀ Moabu ni. Ó sọ wí pé, ‘Kí ń jọ̀wọ́ jẹ́ kí òun máa ṣá ọkà lẹ́yìn àwọn olùkórè.’ Ó sì ti ń ṣe iṣẹ́ kárakára láti òwúrọ̀ títí di ìsinsin yìí nínú oko àyàfi ìgbà tí ó lọ láti sinmi fún ìgbà díẹ̀ lábẹ́ ibojì.”