Ìlàkàkà Mímọ́: Dìrọ̀mọ́ Ìgbé-Ayé Iṣẹ́-àṣekára, àti ti Ìsinmi Àpẹrẹ
Mo wa láti ìdílé tí àwọn obìnrin wọn má n ṣiṣẹ́, bí mo sì ṣe nṣe iṣẹ tí mo fẹ́ràn, mo gbàdúrà pé kí ọmọ mi obìnrin kọ láti ṣiṣẹ́ tọ àlàa rẹ̀, kí o ṣiṣẹ́ kara kara, kí o sì gbórò sí Ọlọrun, níbikíbi tí o bá ti pè é. Mo gbàdúrà pé yíò kọ láti ọwọ́ ọ mi wípé iṣẹ́ mimọ àṣẹ karakara túmọ̀ sí kí a gba iṣẹ́ tí a fún wa, sùgbón kí a wà bí a ṣe tọ l'ọdọ ẹni tí o dá wa láti ṣe iṣẹ́ náà. Iṣẹ́ wa níye lórí àti ohun tí a nṣe láti sin Ọlọrun, àwọn alabagbe wa àti àwọn ìdílé wa ṣe pàtàkì - sùgbón kìí ṣe èyí ni o jẹ́ odiwọn wa.
Ọrọ Ọlọrun sọ nípa bí iṣẹ́ wa ṣẹ niyye:
Nínú lẹta tí Pọọlu kọ sí àwọn Efesu, o rán won létí wípé Ọlọrun ti pèsè iṣẹ́ rere fún àwọn ọmọ rẹ àti wípé a dá wa láti ṣe àwọn i yìí (Iwe Efesu 2:10).
Nínú lẹta míràn tí Pọọlu kọ, o gba àwọn ará Korinti níyànjú wípé kí wọn wà ní ìdúróṣinṣin, kí wọn ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ohun tí o dára jùlọ, nitori iṣẹ́ tí wọ́n bá se fún Ọlọrun kìí ṣe lásán (Ìwé Kọrinti kínní 15:58).
Arábìnrin ti inú ìwé òwe ori kokanlelogbon ṣiṣẹ láti ọkàn rẹ wà; o ra ile, o sì ta ilẹ pẹlu owó tí o ko jọ; o ṣẹ̀dá; o gbìn; o si ṣàkóso(Ìwé Òwe 31:10-31).
Debora ṣiṣẹ gẹgẹ bí adajọ o sì jẹ adari àwọn ọmọ ogun (Ìwé Àwọn Adajo 4-5).
Wo èrò rẹ, èyí tí o dára àti èyí tí kò dára, nípa iṣẹ́ è rẹ. Kínni ọkan rẹ má nso nípa àwọn iṣẹ́ tí o nṣe lojojumọ? Ṣe o rò pé iṣẹ́ è rẹ níye lórí, tàbí ṣé o rò pé kò sí ohun tó dára lọ títí tí o bá wòó pẹ̀lú Iṣẹ́, ojuse àti ipa a tí àwọn ẹlòmíràn? Njẹ́ iwọ rò pé o nlo àsìkò rẹ danu lásán bí o sẹ nwọ computa, tí àwọn ìdílé è rẹ̀ nilo rẹ, abi o n ronú nítori kò sí àsìkò láti wà pẹlú ìdílé ẹ Bí a bá wòó , ṣe o ní èrò tí o dára, tàbí èrò búburú, tàbí èrò ijẹbi, tàbí aibikita nípa iṣẹ́ è rẹ?
Iṣẹ́ tí a nṣe níye lórí bí a bá n ṣe é fún ògo Ọlọrun àti pẹ̀lú inú dídùn. Nígbàtí Ọlọrun bá pè wá láti ṣiṣẹ́, níbikíbi tí o bá wà àti bí o se wù kì órí, o jẹ́ ara ìpinnu u rẹ fùn wa, ara bí a ṣe dá wa láti sìn àti láti féràn enìkejì wa.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Iwọntunwọnsi. O jẹ ohun tí a nfẹ nínú ayé wa bí a se ngbo ariwo ti "iṣẹ́ asekara" létí kan, àti iṣọrọ kelekele ti "sinmi díẹ̀ sí" létí Kejì. Tó bá jẹ́ wípé èrò Ọlọ́run fún wa kìí kàn se ọna kan tàbí èkejì nkọ? Ẹjẹ́ kí a wo iṣẹ́ ṣíṣe ní ònà mimọ - ìgbé ayé tí Iṣẹ́ asekara àti isinmi dáradára ní àwọn ọ̀nà tí o bu Ọlá fún Ọlọrun.
More