Ìrìn àjò lo si Ìbùje EranÀpẹrẹ

Journey To The Manger

Ọjọ́ 9 nínú 70

Jésù Jé Ìbàtan -Olúdáǹdè

Májèmú láéláé se àpẹẹrẹ ìṣáájú fún olúdáǹdè tó máa gbà aráyé la lówó ìgbèkùn àti oko erú. Àmì kan tí ìgbàlà ní ipò ìbàtan-olúdáǹdè, mẹ́ńbà ìdílé tímótímó tó lè yàn láti gbà mọ̀lẹ́bí rè là nípa sisan gbèsè.

Bí ìmúse àmí yìí, Jésù dí Ìbátan- Olúdáǹdè. Ó dí eran ara àti ẹ̀jẹ̀ kí Ó lè pìn nínú èdá ènìyàn wa, dídí Omo ènìyàn tàti Omo Olórun. Ó rìn pèlú wa, a dá mò pèlú wa kí Ó bá lè san gbèsè wa àti ṣàfihàn ònà padà sódó Asèdá wa. Kò sì elómíràn tó lè gbà wa là lówó àwon èsè wa àti tu wa sílè lówó ìgbèkùn.

Isé Sisé: Dín àwon oúnje aládùn kan kí o tójú àwon aládùúgbò tàbí alábàáṣiṣẹ́ sí ohun dídùn kan.

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 8Ọjọ́ 10

Nípa Ìpèsè yìí

Journey To The Manger

Ní alẹ́ ìdákẹ́ rọ́rọ́ kan ní ọdún 2000 sẹ́yìn, àwọn angẹli mu ìròyìn ìbí Olùgbàlà wá fún ẹgbẹ́ àwọn daran-daran kan níbi tí wọn ti ń da ẹran wọn. Lẹ́yìn tí wọ́n gbọ́ ìròyìn náà, àwọn daran-daran wọ̀nyí fi ohun gbogbo sí'lẹ̀ láti wá ìkókó tí ó wà ní ibùjẹ ẹran ní Bẹtilẹhẹmu. Lẹ́yìn gbogbo àwọn ọdún wọ̀nyí, ìpè yìí kò tíì yí padà. Ẹ̀ bá Dr. Charles Stanley rìn bí ó ṣe ń ràn yín l'ọ́wọ́ láti súnmọ́ Olùgbàlà, àti láti mú ọkàn yín le láti wá àyè láti sinmi nínú ìfẹ́ Bàbá ní àkókò yíì. 

More

A fé láti dúpé lówó Isé òjísé Touch fún ìpésé ètò yìí. Fún ìsọfúnni síwájú sí, E jòó ṣèbẹ̀wò visit: https://intouch.cc/yv18