Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ Pẹ̀lú Ọlọ́runÀpẹrẹ

Conversations With God

Ọjọ́ 6 nínú 14

Ohùn Olórun kìí sábà m'áriwo dání. Èmí Mímó sábà máa ń sọ̀rọ̀ wúyẹ́wúyẹ́ àti léraléra. Níbi tí o bá tí rọra fi aájò pe àkíyèsí wa sí ǹkan, ó ma dára tí a kò bá jáfara láti yọ ara wa kúrò nínú pańpé tó lè wà nítòsí. Bákan náà, nígbà tí O bá fí ìbùkún hàn, a lè yàn lati se ìgbọ́ràn wọnú anfààní nípa ìgbàgbọ́. Olúwa kìí sábà ṣe atótónu pẹ̀lú àwọn ìpàkíyèsí Rẹ̀, nítorí náà a gbọ́dọ̀ máa tẹ́tí sí ohùn àti ìṣe Rẹ̀.

Lósán ọjọ kan nígbà ẹ̀ẹ̀rùn, Mo gbà àmọ̀ràn ṣókí tó yí ìtọ́sọ́nà mi padà. Púpọ̀ nínú àwọn ọmọ mi tín lọ sí ilè ìwé kéréjè tí Kristẹni kan ní agbègbè wa. Ẹnìkan nínú Ẹgbẹ́ ìgbìmọ̀, tó tún jé òré mi tímọ́tímọ́, pé láti bèèrè bóyá máa ronú nípa ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò fún ipò kékeré tí ọ̀gá akẹ́ẹ̀kọ́ ònkòwé gíga fún sáà ilè ìwé tó kàn.

Èyí bá mi lójijì. Mo rántí dáadáa ìgbéléwọ̀n tó ń lọ nínú ọkàn bí a tí ń sọ̀rọ̀ lórí fóònù. Èrò ìtakò àkọ́kọ́ tó wá sí mi lọ́kàn: Ẹ̀kọ́ tí mo kọ́ gboyè ní ilé ẹ̀kọ́ gíga kò ní ǹkankan ṣe pẹ̀lú ètò ẹ̀kọ́ . Ó ṣeni láànú wípé ǹkan kéréje ni mọ nípa bí a ti ń kọ ìwé èkọ́ koríkúlomú. Ó ti lé ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún tí iṣẹ́ ti gbé mi kúrò nílé kọ́ìn. Kíkọ́ ẹ̀kọ́ n'íta ilée wá máa da òkúta sí bí ìgbésí ayé inú ẹbí ti ń lọ ní wọ́rọ́wọ́. Ipò titun yìí máa túmọ sí iṣẹ́ àṣẹ kára—yèè! N kò ní mọ ibi tí máà tí bẹ̀rẹ̀. Àti wípé kí ló fún mi ní ìrètí wípé wọ́n máa gbà mí fún iṣẹ́ náà láàrín àwọn olùkọ́ mìíràn tí wọ́n máa fọ̀rọ̀wálẹ́nuwò fún ipò náà?

Lẹ́yìn náà la rí àwọn àmúyẹ rere tó wà níbẹ̀: Tí èyí bá jẹ́ ọ̀nà láti gé owó tí à ń san fún ilé-ìwé ńkọ́? Kódà àfikún owó kékeré kún owó oṣù mi ma mú ètò ìṣúná wa gbé pẹ́ẹ́lí díẹ̀ si. Yàtọ̀ sí èyí mo fẹ́ràn láti máa kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́, àti wípé iṣẹ́ tí mo mọ̀ọ́ ṣe dáadáa ni. Anfààní láti kọ́ni níta ilé wa máa jé ìpèníjá tó da láti téwogbà—odára! Tí Ọlọ́run bá ti yàn mí fún iṣẹ́ yìí, ǹjẹ́ kò ní pèsè ọgbọ́n àti agbára láti ti iṣẹ́ náà lẹ́yìn?

Nínú ìpòrúru àkókò náà, Olúwa fọhùn. Bí ìgbà tó bá fọwọ́ tọ́ mi léjìká ló ti rí. Lóbátán o. O fí hàn wípé láti se ìfòròwánilénuwò náà yóò yọrí sí ìbùkún.

Wón gbà mí s'íṣẹ́ láàrin oṣù náà. Láàrín oṣù méjì Olúwa ti fi ìran isé èkó náà hàn mí. Ní oṣù kéta, Mo ti ń kọ koríkúlomú, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́, sí ìyanu fún mi— mo gbádùn bí gbogbo rẹ̀ ti lọ. Ní báyìí mo wá mọ̀ dájú wípé láìsí Ìpèníjá ipò olùkọ́ yìí, n kò lè ní òye àti ìgboyà tí mo nílò láti kòwe tí mo padà kọ nípa ádùrá. Àwọn ìbùkún tó tẹ̀lé ìgbọràn yí kò l'óǹkà.

Day 5Day 7

Nípa Ìpèsè yìí

Conversations With God

Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ Pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́ ìfarajìn onínú dídùn sí ìgbésí-ayé àdúrà tó jinlẹ̀, pẹ̀lú àwọn ọ̀nà tí a lè gbà gbọ́ ohùn Ọlọ́run. Ọlọ́run fẹ́ kí a ní ìfọ̀rọ̀wérọ̀ tí kò ní ìdíwọ́ jálẹ̀ ayée wa—ìfọ̀rọ̀wérọ̀ tí yóò mú ìyàtọ̀ wá nínú ìṣísẹ̀, ìbáṣepọ̀, àti ìgbésí-ayé tó ní ìtumọ̀. Ètò yí kún fún àwọn ìtàn nípa bí a ti dé oókan àyà Ọlọ́run. Ó fẹ́ràn wa!

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Susan Ekhoff fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ lọ sí: https://www.amazon.com/Prayer-That-Must-Power-Conversational/dp/1496185560/ref=sr_1_1?ie=UTF8&qid=1498693709&sr=8-1&keywords=prayer+that+must%2C+the+power+of+conversational+prayer