Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ Pẹ̀lú Ọlọ́runÀpẹrẹ
Nígbà míràn ìsísẹ̀ tí ó kàn nínú àdúrà ni kí á jọ̀wọ́ ara wa fún Ọlọ́run. Pẹpẹ ti ẹ̀mí yìí jẹ́ àkókò kan pàtó àti ibi tí a ó yọ̀nda tàbí jọ̀wọ́ ìfẹ́ wa sí ọwọ́ Ọlọ́run, tí a ó sì jọ̀wọ́ èsìn àdúrà sí ìkáwọ́ rẹ̀. Ní àwọn àkókò báyì, à ńgbé ibi tí ó se kókó jùlọ nípa ẹni tí ajẹ́ àti àwọn tí a fẹ́ràn sílẹ̀ níwájú rẹ̀, tí a ó sì sún sẹ́yìn láìmọ̀dájú ohun tí yíò ṣẹ̀lẹ̀ lẹ́yìn náà. Àkókò yí le dúró tiri tí yíò sì dàbí wípé o wà nínú ewu.
Jíjọ̀wọ́ ara wa sílẹ̀ jẹ́ àdúrà ìbásẹpọ̀ tí ó fẹsẹ̀múlẹ̀ nínú ìbásẹpọ̀ ìfẹ́ pẹ̀lú Jésù. Nítorí jíjọ̀wọ́ ìfẹ́ ara wa àti ti àwọn tí a fẹ́ràn le roni lára púpọ̀- Ó mo eléyì nípa ohun tí ó ti làkọjá-Jésù ńtìwá lẹ́yìn nínú gbogbo rẹ̀. Bí a se ńjọ̀wọ́ ara wa, È̩mí mímọ́ ńfún wa ní ore ọ̀fẹ́, wíwà níwájú rẹ̀ yíò di ìbùkún. Ìyìn ni fún orúkọ rẹ̀! Bí a se ńjọ̀wọ́ ara wa, à ńgbé ara wa sínú ọwọ́ ìfẹ́ rẹ̀.
Dúró kí o se ìrántí àwọn akíkanjú nínú bíbélì, ìtàn àti ní òde òní tí wọ́n ní ipa nínú ayé wa. Ohun tí ó wọ́pọ̀ nínú wọn ni ìrírí pẹpẹ àdúrà wọn. Ní irú àkókò yì wọ́n fi ohun tí wọ́n ti lérò sílẹ̀ láti tọ ètò tí Ọlọ́run ní fún lọ, wọ́n sì yàn láti jọ̀wọ́ ara wọn-pàápàá tí ó bá jẹ́ pé wọn ó yááfì àwọn nkàn tí ó ṣẹ pàtàkì sí wọn tàbí tí yíò bá mú ìjìyà lọ́wọ́. Lẹ́yìn gbogbo ìlàkọjá yì, ìrora ohun tí wọ́n yááfì padà jẹ́ àkókò tí ó jọjú jùlọ, àwọn ìsẹ̀lẹ̀ tí yíò tẹ̀le á sì jẹ́ èyí tí yíò ní ipa tí yíò pẹ́ títí. Ní ọ̀nà yì, tí a bá fi àwọn ètò tí a ti se fún ara wa sílẹ̀, tí a sì gba ètò àti ìpè Ọlọ́run, a dara pọ̀ mọ́ ìròyìn ńlá, àti ìrìn àjò ìjọba Ọlọ́run tí yíò mú wa kọjá ohun tí a rò.
Sùgbọ́n kíni yíò sẹlẹ̀ tí a bá rí bí àdúrà ìjọ̀wọ́ ara ẹni se níye lórí, sùgbón tí ẹ̀rù ńbà wá láti gba àdúrà báyí? Àdúrà tí ó dára jù lẹ́yìn èyí ni "Ọlọ́run, mo setán kí o ràn mí lọ́wọ́ láti setán." Gbígba àdúrà yí, yíò jẹ́ kí agbára rẹ̀ ràn ó lọ́wọ́ láti se ohun tí ó jẹ́ síse. "[Kìí se ní agbára tìrẹ] nítorí Ọlọ́run ni ó tí ńsisẹ́ nínú rẹ̀ láti ìgbàyí [ó ń fún o ní okun, o sì ń dá agbára àti ìfẹ́ láti se sínú rẹ], láti setán àti láti siṣẹ́ fún ìdùnnú tí ó dára àti ìtẹ́lọ́rùn àti ìdùnnú" (Phil. 2:13, AMPC). A le Gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run nínú gbogbo ìgbésẹ jíjọ̀wọ́ ara wa. Kòsí ohun tí ó sòro fún, àti pé gbogbo ohun tí ó se pàtàkì sí wa wà ní ìpamọ́ rẹ̀.
Nípa Ìpèsè yìí
Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ Pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́ ìfarajìn onínú dídùn sí ìgbésí-ayé àdúrà tó jinlẹ̀, pẹ̀lú àwọn ọ̀nà tí a lè gbà gbọ́ ohùn Ọlọ́run. Ọlọ́run fẹ́ kí a ní ìfọ̀rọ̀wérọ̀ tí kò ní ìdíwọ́ jálẹ̀ ayée wa—ìfọ̀rọ̀wérọ̀ tí yóò mú ìyàtọ̀ wá nínú ìṣísẹ̀, ìbáṣepọ̀, àti ìgbésí-ayé tó ní ìtumọ̀. Ètò yí kún fún àwọn ìtàn nípa bí a ti dé oókan àyà Ọlọ́run. Ó fẹ́ràn wa!
More