Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ Pẹ̀lú Ọlọ́runÀpẹrẹ

Conversations With God

Ọjọ́ 8 nínú 14

Àwọn tí wọ́n fẹ́ àsọyèpọ̀ aládùn àtí ìjìnlẹ̀ pẹ̀lú Bàbá gbọ́dọ̀ kọ́ láti dúró-láti ní ìgbẹ́kẹ̀lẹ́ nínú ọgbọn, ipò ọba-aláṣẹ, ìfẹ́, àti àkókò Rẹ̀. Ṣùgbọ́n kí ló dé tí Ọlọ́run fi n béèrè sùúrù nígbà míràn? Ni ìsàlẹ̀, a rí àwọn ọ̀nà díẹ̀ tí ó dájú sí ti ìdàgbàsókè àti ìgbésí ayé àdúrà tí gbogbo wá fẹ́, ṣùgbọ́n tí a kò ní sùúrù láti dúró dé nígbà míràn.

Tí mo bá lè ṣe, máà kéde ìlànà àkọ́kọ́ yìí pẹ̀lú afefeyẹ̀yẹ̀ àti ariwo: Ó dára láti dúró ní apá iwájú àdúrà, ní ìjíròrò pẹ̀lú Ọlọ́run ṣáájú ìtọrọ àwọn ìbéèrè wa. Nínú oyè yìí, a dúró pé pẹ̀lú Olúwa láti ṣe àwárí ohun tí ó wà ní ọkàn Rẹ̀. Dídúró ṣe àfihàn ìjọ̀wọ́ àti ìfọríbalẹ̀ wa sí ìfẹ́ Rẹ̀. A nílọ̀ ọgbọ̀n Rẹ̀ láti béèrè ní ọ̀nà tí ó tọ́.

Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn bèèrè l'ọ́wọ́ Jésù láti kọ́ wọn láti gb'àdúrà, Ó kọ́ wọn láti sọ wípé “Kí ìjọba Rẹ dé; Ìfẹ́ tìrẹ ní kí a ṣe, bí ti ọrùn, bẹ́ẹ̀ni ní ayé” (Mat. 6:10). A tún lè bẹ̀rẹ̀ ẹ̀bẹ̀ wa nípa bíbéèrè l'ọ́wọ́ Jésù láti kọ́ wa láti gb'àdúrà. Bí Ó ṣe n ṣe ìfẹ́ Rẹ̀ lórí l'áyé bí ó ti wà ní Ọrùn, a wà ní ipò tí ó tọ́ láti bèèrè ohùn tí ó dá lórí ohun tí inú Rẹ̀ dùn sí láti pèsè. Bíbéèrè ní ọ̀nà yìí ní ìgbà kan náà á mú ìfẹ́ ẹ̀mí tiwa náà ṣẹ. Àṣà kan yìí ti yí ìgbésí ayé àdúrà mi padà. Mo gbà yín níyànjú láti gb'àdúrà ìfẹ́ Ọlọ́run padà si. Nínú ayé yìí, à n dúró de ìpadàbọ̀ Olúwa gẹ́gẹ́ bíi Olùdámọ̀ràn Ìyanu.

Ní àwọn àkókò míràn, ìdí láti dúró á wá lẹ́yìn ẹ̀bẹ̀ kan. Irú ìdúró yìí ní ohun gbogbo láti ṣe pẹ̀lú àkókò. Kìí ṣe ìgbà gbogbo ni àsìkò láti gbà. “Olúkúlùkù ohun ni àkókò wà fún, àti ìgbà fún iṣẹ́ gbogbo lábẹ́ ọ̀run. (Oniwasu 3:1). Dájúdájú àkókò tí ó yẹ yóò dé, ṣùgbọ́n kìí ṣe títí di àkókò tó tọ́. Àkókò tí ó tọ́ fún ìbùkún pẹ̀lú ìdáhùn àdúródè sí àwọn àdúrà wa jẹ́ ẹwà ọ̀nà méjì.

Ní ìparí, dídúró nínú àdúrà n mú ìfaradà wá, ìfaradà sì jẹ́ ohun ìdíyelé. Àwọn tí ó n gbèrò láti di ẹni tí ó dàgbà gbọdọ̀ rìn àwọn àtẹ̀gùn rẹ̀. Bíbélì fún ra rẹ̀ sọ pé ó yẹ kí a ṣe ayẹyẹ ìlànà tó l'aápọn yìí! A lè kẹ́gàn wàhálà ìsọdọ̀tun tí ìfaradà mú wá ní àkókò kan, ṣùgbọ́n nígbà tí ó bá yá, a kì yóò gba ohunkóhun fún ohun tí a ti jèrè. Ọlọ́run á bùkún wa nípa láì jẹ́ kí a lè yẹ ìlànà ìdúró nígbà gbogbo.

Ọjọ́ 7Ọjọ́ 9

Nípa Ìpèsè yìí

Conversations With God

Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ Pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́ ìfarajìn onínú dídùn sí ìgbésí-ayé àdúrà tó jinlẹ̀, pẹ̀lú àwọn ọ̀nà tí a lè gbà gbọ́ ohùn Ọlọ́run. Ọlọ́run fẹ́ kí a ní ìfọ̀rọ̀wérọ̀ tí kò ní ìdíwọ́ jálẹ̀ ayée wa—ìfọ̀rọ̀wérọ̀ tí yóò mú ìyàtọ̀ wá nínú ìṣísẹ̀, ìbáṣepọ̀, àti ìgbésí-ayé tó ní ìtumọ̀. Ètò yí kún fún àwọn ìtàn nípa bí a ti dé oókan àyà Ọlọ́run. Ó fẹ́ràn wa!

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Susan Ekhoff fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ lọ sí: https://www.amazon.com/Prayer-That-Must-Power-Conversational/dp/1496185560/ref=sr_1_1?ie=UTF8&qid=1498693709&sr=8-1&keywords=prayer+that+must%2C+the+power+of+conversational+prayer