Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ Pẹ̀lú Ọlọ́runÀpẹrẹ

Conversations With God

Ọjọ́ 12 nínú 14

Ìwé mímọ́ ṣe àkọsílẹ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ àwọn ìlànà àti ìtọ́nisọ́nà Olúwa nípasẹ̀ àlá. Jakobu, Josefu (ọmọ Jakọbu), àti Josefu (baba Jesu). Díè sí ni ìwọ̀nyí jẹ́.

ìbọ̀wọ̀ fún ìlànà bíbélì ti fún mi ní ìgboyà láti bèèrè l'ọ́wọ́ Ọlọ́run láti bá mi s'ọ̀rọ̀ nípasẹ̀ àlá. Kìí ṣẹlẹ̀ nígbà gbogbo, ṣùgbọ́n dájúdájú, Olúwa ti bá mi s'ọ̀rọ̀ ní irú ọ̀nà yìí.

Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kan, mo ní àlá tí mo ṣì rántí. Nínú àlá náà, mo rí gareji ọkọ̀ kan. Bí mo tí n wò ó, ọ̀rẹ́ mi kan rìn súnmọ́ ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kan, ó ṣí ilẹ̀kùn ẹ̀yìn, ó sì gbé ọmọ kékeré rẹ̀ sínú ijoko ọkọ̀ rẹ̀. Ọmọbìnrin kékeré náà n bínú ó sì n tàpá. Pẹ̀lú sùúrù, ọ̀rẹ́ mi di àwọn okùn àbò mọ́ o l'ára láàárín àtakò púpọ̀. Nígbà tí ó ṣe tán, ó joko sí ijoko awakọ̀. Ó ti rẹ̀ é.

Bí mo ṣé n wo ìṣẹ̀lẹ̀ náà, ìtẹramọ́ṣẹ́ rẹ̀ kàn mí l'ára ní pàtàkì jù lọ. Ó wú mi l'órí láti rí i, bákan náà, ìbànújẹ́ àti rúdurùdu rẹ̀ ṣe mí láàánú. Bí ìyá tó ti d'àgbà, mo mọ òtítọ́ inú rẹ̀ - àkókò kúkúrú ní ìṣẹ́ òbí ni èyí jẹ́. Àwọn iṣẹ́ rẹ̀ yóò so èso ní ìgbésí ayé ọmọbìnrin rẹ̀, ṣùgbọ́n kò gbọdọ̀ dáwọ́ dúró.

Ó dùn mí wípé kò mọ ohun tí mo lè rí ní gbangba, nítorí náà nínú àlá mi, mo bẹ̀rẹ̀ síí ké pè é, “Má ṣe dáwọ́ dúró! Dúró ṣinṣin!”

Bí mo tí n wò ó, ọ̀rẹ́ náà bẹ̀rẹ̀ síí tẹ fóònù alágbèéká rẹ̀ bí ẹni pé ó ti gbọ́ nkan ṣùgbọ́n kò ní ìdánilójú orísun rẹ̀. Kò mọ ẹni tí n s'ọ̀rọ̀ tàbí ohun tí a ti sọ. Ó pàpà wa'kọ̀ rẹ̀ lọ láìsí ìrísí ọgbọ̀n.

Nígbà tí mo jí, mo kọ àlá àti àwọn ìfihàn rẹ̀ sílẹ̀. Ní gbogbo òwúrọ̀ náà, mo tẹ̀ síwájú láti fi àdúrà ronú lórí ìtumọ̀ tí àlá náà lè ní.

Àwọn wákàtí díẹ̀ lẹ́hìn náà, Olúwa pín ìtumọ̀ rẹ̀ - ẹnú yà mí. Ọ̀rẹ́ mí jẹ́ èmi nínú àlá náà, ohùn Rẹ̀ sì ni ohùn tí a pariwo ọ̀rọ̀ ìwúrí. Àlá náà wáyé ní àkókò kan tí mo ní ìdààmú nínú ìṣẹ òbí mi. Ó fẹ́ kí n mọ̀ pé Ó kàn-án lára, àti pé ẹbí mi yóò kọjá lọ sí àwọn àkókò ìgbésí ayé míràn. Ìmọ̀ràn tí mo jèrè jẹ́ ẹ̀kọ́ tí nkò lè gbàgbé, nítorí ní ọ̀nà kan, mo ti gbé e nípasẹ̀ àlá náà.

Ọjọ́ 11Ọjọ́ 13

Nípa Ìpèsè yìí

Conversations With God

Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ Pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́ ìfarajìn onínú dídùn sí ìgbésí-ayé àdúrà tó jinlẹ̀, pẹ̀lú àwọn ọ̀nà tí a lè gbà gbọ́ ohùn Ọlọ́run. Ọlọ́run fẹ́ kí a ní ìfọ̀rọ̀wérọ̀ tí kò ní ìdíwọ́ jálẹ̀ ayée wa—ìfọ̀rọ̀wérọ̀ tí yóò mú ìyàtọ̀ wá nínú ìṣísẹ̀, ìbáṣepọ̀, àti ìgbésí-ayé tó ní ìtumọ̀. Ètò yí kún fún àwọn ìtàn nípa bí a ti dé oókan àyà Ọlọ́run. Ó fẹ́ràn wa!

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Susan Ekhoff fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ lọ sí: https://www.amazon.com/Prayer-That-Must-Power-Conversational/dp/1496185560/ref=sr_1_1?ie=UTF8&qid=1498693709&sr=8-1&keywords=prayer+that+must%2C+the+power+of+conversational+prayer