Gẹn 43:23-28

Gẹn 43:23-28 YBCV

O si wi fun wọn pe, Alafia ni fun nyin, ẹ má bẹ̀ru: Ọlọrun nyin ati Ọlọrun baba nyin, li o fun nyin ni iṣura ninu àpo nyin: owo nyin dé ọwọ́ mi. O si mú Simeoni jade tọ̀ wọn wá. Ọkunrin na si mú awọn ọkunrin na wá si ile Josefu, o si fun wọn li omi, nwọn si wẹ̀ ẹsẹ̀ wọn; o si fun awọn kẹtẹkẹtẹ wọn li ohun jijẹ. Nwọn si ti mú ọrẹ na silẹ dè atibọ̀ Josefu lọsán: nitori ti nwọn gbọ́ pe nwọn o jẹun nibẹ̀. Nigbati Josefu si wọlé, nwọn si mú ọrẹ ti o wà li ọwọ́ wọn fun u wá sinu ile, nwọn si tẹriba fun u ni ilẹ. On si bère alafia wọn, o si wipe, Alafia ki baba nyin wà, arugbo na ti ẹnyin wi? o wà lãye sibẹ̀? Nwọn si dahun pe, Ara baba wa, iranṣẹ rẹ le, o wà sibẹ̀. Nwọn si tẹri wọn ba, nwọn si bù ọlá fun u.