Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ Pẹ̀lú Ọlọ́runÀpẹrẹ
Díẹ̀ nínú àwọn ǹkan ìdùnnú tí mo rántí nípa ìgbà èwe mi dá lórí àga kan tó wà ní yàrá ìdáná Mama mi àgbà l'ábúlé. Ní àkókò kan tí ó kun yàrá yìí ní àwọ̀ pupa, ló pinu láti kun àga yìí bákannáà. Ọ̀pọ̀ ìgbà tí a bá lọ kí màmá àgbà ni mo máa jókòó lórí àga yìí, tí n ó tọ́sẹ̀ tí n ó sì máa wòye ǹkan tó ń lọ ní yàrá ìdáná náà pẹ̀lú ìdùnnú.
Mo ṣì lè fojú inú rí Mama àgbà, bí wọ́n ti ń lọ-bọ̀ nínú yàrá yìí tí àwọn apẹ ìdáná náà ń sọkutu, pẹ̀lú adìẹ dídín lóríi pẹpẹ, tí èmi àti wọn yóò sì máa jomi-toro ọ̀rọ̀ bí wọ́n ṣe ńṣe àwọn ǹkan wọ̀nyí. Ara Mama àgbà a máa yá tí àwọn èèyàn bá wà ní sàkání wọn. Wọ́n fẹ́ràn mi, mo sì mọ̀ bẹ́ẹ̀, èmi pẹ̀lú sì fẹ́ràn wọn tọkàntọkàn.
Mama àgbà Easley ti sípò padà fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, àmọ́ àwọn ìjíròrò tí mo bá wọn ní lórí àga yìí sì ma ń jẹ́ ìwúrí fún mi títí d'òní. Ó wà lára àwọn àjogúnbá mi.
Ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn màmá mi fi àga pupa Mama àgbà yí ta mí lọ́rẹ—óda, mo tọrọ fún un ní màámi fi yàǹda rẹ̀! Àárín iléè mi ni àga yìí fi ìkàlẹ̀ sí báyìí, ibi tó dára láti ka ìtàn, láti bá ọ̀rẹ́ àti ojúlùmọ̀ jíròrò, àti bíbá ọmọ-ọmọ mi ṣeré. Nígbà tí n kò bá sí lórí àga yìí, ọkàn mi a máa fà síbẹ̀.
Ní ọ̀nà kan náà tí èmi àti màmá àgbà fi ní ìdàpọ̀ aládìńdùn nígbà yẹn tí mo kéré, àti bí ó ti ń mú mi jókòó sí sàkání àwọn tí mo fẹ́ràn lónìí, ṣíṣí Bíbélì a máa mú wa wọ àgbàlá láti ṣe àbẹ̀wò pẹ̀lú Olúwa fún ìgbà díẹ̀. Nígbà tí a kò bá sí ní ìjókòó pẹ̀lú Rẹ̀, ọkàn Rẹ̀ a máa fà sí wa—pẹ̀lú ìpòǹgbẹ.
Ìfẹ́ Jésù ni láti mú wa ṣe àṣàrò nínú Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ níbi tí a ó ti máa wòye bí ó ti fẹ́ wa tó àti bí a ti lè fi ìfẹ́ hàn síi. Bí a ti ń wà lọ́dọ̀ Rẹ̀, ọgbọ́n nípa ìfihàn Rẹ̀ tí ó ti wà ní àkọsílẹ̀—gbogbo èrò àti èrèdí rẹ̀—ni yóò hàn sí wa kedere. Àwọn tó fi ọkàn mímọ́ àti ìpọkànpọ̀ ṣe àṣàrò nínú Ìwé Mímọ́ kò lè wà bákannáà mọ́ láíláí—gbogbo èrò ọkàn àti ìgbésẹ̀ wọn ni ayée Rẹ̀ yóò máa tọ́. Pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Rẹ̀ tó ti wà ní àkọsílẹ̀ ni yóò kọ àwọn ìní àìnípẹ̀kun sórí ọkàn wa. Bí Ó sì ti ńṣe èyí, a ó pa wá lára dà látinú ògo lọ sínú ògo.
Nípa Ìpèsè yìí
Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ Pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́ ìfarajìn onínú dídùn sí ìgbésí-ayé àdúrà tó jinlẹ̀, pẹ̀lú àwọn ọ̀nà tí a lè gbà gbọ́ ohùn Ọlọ́run. Ọlọ́run fẹ́ kí a ní ìfọ̀rọ̀wérọ̀ tí kò ní ìdíwọ́ jálẹ̀ ayée wa—ìfọ̀rọ̀wérọ̀ tí yóò mú ìyàtọ̀ wá nínú ìṣísẹ̀, ìbáṣepọ̀, àti ìgbésí-ayé tó ní ìtumọ̀. Ètò yí kún fún àwọn ìtàn nípa bí a ti dé oókan àyà Ọlọ́run. Ó fẹ́ràn wa!
More