Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ Pẹ̀lú Ọlọ́runÀpẹrẹ

Conversations With God

Ọjọ́ 5 nínú 14

Ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn, èmi àti Richard (ọkọ mi) bẹ̀rẹ̀ sí ní jíròrò nípa bóyá ó ma ṣeé ṣe láti wá ilé-ìjọsìn míràn láti máa lọ lẹ́yìn bíi ọdún mẹ́wàá. À ńṣe ìpòǹgbẹ fún ètò ìjọsìn ìgbàlódé a kò sì rí èyí tó fi taratara yàtọ̀ ní ìtòsí. Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ oṣù, a rí ìjọ méjì-mẹ́ta tí a lè lọ a sì bẹ̀rẹ̀ sí ní gbaradì láti darapọ̀ mọ́ ọ̀kan nínú wọn. 

Bí a ti ń múra àti tẹ̀síwájú, a pinu láti darapọ̀ mọ́ ìsọjí òpin ọ̀sẹ̀ kan. Àwọn ọkùnrin ní yóò kọ́kọ́ ṣe tiwọn, àwọn obìnrin yóò sì ní ìsọjí tiwọn ní ọ̀sẹ̀ méjì lẹ́yìn àwọn ọkùnrin. Ojú wa wà lọ́nà fún àǹfààní láti ní ìpàgọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run ní àkókò ìrékọjá láti ìjọ kan sí òmíràn yí. 

Wákàtí méjì-lé-ní-àádọ́rin ti Richard lò níbi ìpàgọ́ yìí di àkókò ìsọjí—nítorí mo ríi kedegbe lójú rẹ̀ ní alẹ́ ọjọ́ Àìkú tó padà dé. Bí ó ti ń ṣàlàyé bí ìsọjí náà ti lọ, mo bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe ìpòǹgbẹ fún àkókò ìsọjí àwọn obìnrin. 

Lẹ́yìn onírúurú àlàyé, ó wá fi ọ̀rọ̀ rẹ tì s'órí èyí tó ti mọ̀ọ́mọ̀ fi pamọ́ di ìkẹyìn. Pẹ̀lú ìṣọ́ra, ó ṣàlàyé wípé Ọlọ́run fi han òhun l'àkókò ìpàgọ̀ náà wípé a kò gbọ́dọ̀ kúrò nínú ìjọ tí a ti ń jọ́sìn—wípé a ní láti tẹ̀síwájú pẹ̀lú ìjọ wa àtijọ́. Nígbà tí mo máa fèsì, mo dáhùn wípé Ọlọ́run kò fi èyí hàn sí èmi, àti wípé ó ṣeé ṣe kó má gbọ́ Ọlọ́run dáradára, pẹ̀lú ọgbọ́n ó dáhùn wípé òhun yóò ní sùúrù fún mi láti gbọ́ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. 

Láàárín ìsìn, l'ọ̀jọ̀ tí ìpàgọ́ àwọn obìnrin máa parí, Ọlọ́run kọsí èmi pẹ̀lú. Ní wákàtí kan mo dà bí aláìmọ̀kan, lọ́gán ni Ọlọ́run sì ṣí mi ní iyè: A ní láti fi ìkàlẹ̀ sínú ìjọ tí a wà. Lóbátán. Ìpinnu mi àtẹ̀yín wá rọ́lu ti Ọlọ́run tí kò lè yẹ̀, ìpinnu tó nípọn bíi irin ìdákọ̀ró tí ọkọ̀-ayọ́kẹ́lẹ́ tó wà lórí eré rọ́lù.

Nínú ìpòrúru ọkàn, mo bẹ̀rẹ̀ sí ní sọkún pẹ̀lú ìbànújẹ́ ọkàn. A ti bèrè fún ìgbọràn mi. Ọlọ́run ń rọ̀ wá láti dúró, àmọ́ èrò Ọlọ́run l'àkókò náà rú mi lójú. Ó gbà mí ní ìrírí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún láti ní òye èrèdíi rẹ̀. Pẹ̀lú pẹ̀lú rẹ̀ a yàn láti gbọ́ràn àti láti dúró.

Ohun tó tẹ̀lée ní ọgbẹ́ kíkan sí ìwà ìgbéraga mi—yéè, èyí tí ẹ̀kọ́ nípa ìrẹ̀lẹ̀ tẹ̀lé—yéèpà. Àwọn ẹ̀kọ́ ayé mi tó ṣe pàtàkì jù lọ ni mo rí gbà nítorí mo gbọ́ràn àti wípé a kàn án nípa fún mi láti kọ́ wọn. 

Ó wá jẹ́ ìyàlẹ́nu fún mi wípé ìjọ tí à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yí ní àyípadà ọ̀tún nígbà tí Ọlọ́run s'ọpé óyá. Ní báyìí mo mọ̀ wípé kò sí ẹnìkan tí Ọlọ́run kò lè yí padà—láì yọ ara mi sílẹ̀. Ṣíṣe ìjẹ́rìí sí ìsọjí nínú ìjọ mi tóó ṣe sùúrù fún. Ìbùkún a máa tẹ̀lé ìgbọràn. 

Ọjọ́ 4Ọjọ́ 6

Nípa Ìpèsè yìí

Conversations With God

Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ Pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́ ìfarajìn onínú dídùn sí ìgbésí-ayé àdúrà tó jinlẹ̀, pẹ̀lú àwọn ọ̀nà tí a lè gbà gbọ́ ohùn Ọlọ́run. Ọlọ́run fẹ́ kí a ní ìfọ̀rọ̀wérọ̀ tí kò ní ìdíwọ́ jálẹ̀ ayée wa—ìfọ̀rọ̀wérọ̀ tí yóò mú ìyàtọ̀ wá nínú ìṣísẹ̀, ìbáṣepọ̀, àti ìgbésí-ayé tó ní ìtumọ̀. Ètò yí kún fún àwọn ìtàn nípa bí a ti dé oókan àyà Ọlọ́run. Ó fẹ́ràn wa!

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Susan Ekhoff fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ lọ sí: https://www.amazon.com/Prayer-That-Must-Power-Conversational/dp/1496185560/ref=sr_1_1?ie=UTF8&qid=1498693709&sr=8-1&keywords=prayer+that+must%2C+the+power+of+conversational+prayer