Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ Pẹ̀lú Ọlọ́runÀpẹrẹ
Gẹ́gẹ́bí ìyá tó ń kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ ní ẹ̀kọ́ ilé-ìwé ní ilé, mo máa ń ṣètò àkókò mi láti kọ àwọn àfojúsùn àti ìlépa ẹ̀kọ́ tí mo máa lò. Ní ọdún 1999 ni ǹkan fẹ́ yàtọ̀ díẹ̀, àyàfi wípé àfojúsùn mi nípọn ju ti àtẹ̀yínwá lọ nítorí mo lóyún ọmọ wa ìkéje lákòókò náà. Lẹ́sẹẹsẹ ni mò ń ṣe àgbéyèwò ohun kàààkan tí àníyàn yí fi padà sú mi.
Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbèrò, ó wá ku ìpinnu kan láti ṣe. Sámúẹ́lì, ọmọ mi tó ṣẹ̀ pé ọdún mẹ́rin, kò tíì lè sọ̀rọ̀. Mo wá wòye wípé ìtọ́jú lọ́dọ̀ àwọn akọ́ṣẹ́-mọṣẹ́ nípa ọ̀rọ̀ sísọ ni yóò yanjú ìpèníjà náà. Àmọ́ nínú ètò ẹ̀kọ́ tí ǹkan yẹpẹrẹ bíi ìpè orí ago ti lè da ǹkan rú, ìpàdé pàjáwìrì lè mú kí ètò gbogbo ẹbí fún ọjọ́ kan dorí kodò. Ní ìdà kejì, tó bá lọ jẹ́ wípé ọdún yí ló dáráju láti kọ́ Sámúẹ́lì ní ẹ̀kọ́ èdè ńkọ́, tí mo sì ńṣe ìmẹ́lẹ́ láti kọ ní àwọn ǹkan tó yẹ?
Mo rántí, àfi bí àná, ọ̀sán ọjọ́ àbámẹ́ta kan tí mo nọ'sẹ̀ jáde pẹ̀lú ìpinnu láti bá Ọlọ́run jíròrò. Ǹkan tí mo báa sọ lọ báyìí: “Ǹkan tí mofẹ́ mọ̀ nìyí: Njẹ́ O faramọ kí Sámúẹ́lì lọ fún ìtọ́jú ọ̀rọ̀-sísọ lọ́dún yìí, àbí mo ní láti dúró di ìgbà tó bá pé ọmọ ọdún márùn-ún?” Ìbéèrè náà kò jù báyìí lọ. Ìdákẹ́-rọ́rọ́ ló wá tẹ̀le, àmọ́ èyí kò ṣẹ̀rù bàmí. Ọlọ́run ma padà dá mi lóhùn. Mo mọ èyí dájú nítorí wípé Ó ti ńṣe é fún ọjọ́ pípẹ́. Fún ìdí èyí mo dúró pẹ̀lú ìrètí.
Ọjọ́ tó tẹ̀le jẹ́ ọjọ́ Àìkú, gbogbo mọ̀lẹ́bí ló sì lọ fún ìjọsìn bí a ti máa ńṣe. Nígbàtí àkókò tó fún ìwàásù, olùṣọ́-àgùntàn wa Jessica Moffatt gb'ọ̀nà àrà yọ nígbà tí ó lọ sórí pẹpẹ pẹ̀lú aṣọ àbáláyé tó mú kí ó dà bíi Suzanna Wesley (màmá John Wesley, olùdásílẹ̀ ìjọ Methodist). Nínú ọ̀rọ̀ tó tẹ̀le, ó ṣe àkàwé bí ìgbà tí ènìyàn bá ń sọ ìtàn ìgbésí ayé rẹ̀ nípa ìrírí títọ́ àwọn ọmọ mọ́kàn-dín-lógún! Ó ṣe àlàyé bí òhun ṣe gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run l'ọ́pọ̀ ìgbà, àti ìdà mú lórí ọmọkùnrin rẹ̀ Samuel. Etí mi nà. “Susanna” tẹ̀síwájú pẹ̀lú àlàyé wípé ní ọmọ ọdún márùn-ún Samuel kò tíì sọ ọ̀rọ̀ kan ṣoṣo jáde lẹ́nu. Lọ́jọ́ kan ló kàn ṣàdédé bẹ̀rẹ̀ sí ní sọ̀rọ̀ tó dá ṣáká.
Bí mo ti ń tẹ́tí gbọ́ ìwàásù yí láti ibi tí mo jókòó sí, ni ohùn Ọlọ́run ń kọ sí mi látinú ọ̀rọ̀ náà. “Sámúẹ́lì kò ní nílò láti sọ̀rọ̀ títí di ìgbà tó bá pé ọdún márùn-ún. Ní sùúrù di ọdún tó ḿbọ̀ kí o tó dábàá ìtọ́jú ọ̀rọ̀-sísọ fún ọmọ náà.” A wá tẹ àwọn ìlépa mi fún ọdún náà ní ìdí pẹ̀lú ìgboyà lẹ́yìn tí mo gbọ́ ọ̀rọ̀ náà. Sámúẹ́lì ọmọ mì padà bẹ̀rẹ̀ sí ní sọ̀rọ̀ lọ́dún tó tẹ̀le, ìṣọwọ́ sọ̀rọ̀ rẹ̀ wá ní ìlọsíwájú òjijì.
Ọlọ́run fẹ́ kí a bèrè àwọn ìbéèrè tó ṣe pàtàkì lọ́wọ́ rẹ̀ kí a sì máa daríi wa nípa ìfẹ́ Rẹ̀. Lóòótọ́ ni àpèjúwe wa tó kéré jù lọ ṣe pàtàkì sí I.
Nípa Ìpèsè yìí
Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ Pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́ ìfarajìn onínú dídùn sí ìgbésí-ayé àdúrà tó jinlẹ̀, pẹ̀lú àwọn ọ̀nà tí a lè gbà gbọ́ ohùn Ọlọ́run. Ọlọ́run fẹ́ kí a ní ìfọ̀rọ̀wérọ̀ tí kò ní ìdíwọ́ jálẹ̀ ayée wa—ìfọ̀rọ̀wérọ̀ tí yóò mú ìyàtọ̀ wá nínú ìṣísẹ̀, ìbáṣepọ̀, àti ìgbésí-ayé tó ní ìtumọ̀. Ètò yí kún fún àwọn ìtàn nípa bí a ti dé oókan àyà Ọlọ́run. Ó fẹ́ràn wa!
More