Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ Pẹ̀lú Ọlọ́runÀpẹrẹ

Conversations With God

Ọjọ́ 11 nínú 14

Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà, Olúwa á s'ọ̀rọ̀ nípasẹ̀ ẹbí, àwọn ọ̀rẹ́, àwọn olùṣọ́-àgùntàn, tàbí pàápàá àwọn ònkọ̀wé tí a kò ní pàdé láíláí. Gẹ́gẹ́ bí Ọ̀rọ̀ Olúwa ti wá sí ọ̀dọ̀ Dafidi nípasẹ̀ Natani, sí Esteri nípasẹ̀ àbúrò bàbá rẹ̀ Mordekai, àti sí Timotiu nípasẹ̀ Paulu, ìṣírí àti àpẹẹrẹ àwọn ẹlòmíràn lè ní ipa ìjìnlẹ̀ lórí wa.

Mo lè pín ọ̀pọ̀lọpọ̀ òtítọ́ tí mo jèrè nípasẹ̀ jijoko ní abẹ́ ìkọ́ni àwọn olùkọ́ni; ní tòótọ́, àwọn ìwé mi kún fún irú àwọn ọgbọ̀n wọ̀nyí, ṣùgbọ́n ẹyọ̀kan ni mo máa m'ẹ́nu bà.

Ní ọdún díẹ̀ sẹ́yìn, ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìgbà, mo ní ànfààní láti pàdé olùkọ́ kan, eni tí òye rẹ̀ ti wúlò fún mi. Nígbà tí mo jíròrò pẹ̀lú rẹ̀ nípa ìṣesí mi láti jẹ́ olórí, àti ìfẹ́ mi láti fà sẹ́yìn, ó ṣ'àlàyé pé ohun tí ó bẹ̀rẹ̀ ní ìgboyà ìgbàgbọ́ lè di iyèméjì ara-ẹni. Ẹ̀mí á fò á sì ga nígbà tí ọkàn bá bẹ̀rù láti fò. Á máa rò wípé, “Kíni ò n rò? Kíni ìdí tí o fi gba irú eewu bẹ́ẹ̀? Nítorí Ọlọ́run, padà sẹ́yìn!”

Láti ṣ'àpèjúwe, ó fa àga kan sí àárín yàrá náà ó sì gun orí ìjòkó náà láti ṣe àfihàn gbígba àyè olórí tuntun. Ó gbà mí n'íyànjú pé nígbà tí Olúwa bá pè mí láti “dìde,” kí n di akọni tí ó tó láti dúró nínú ìgbàgbọ́ àti láti wo àyíká mi láti ipò tuntun náà. Lẹ́yìn náà, tí Olúwa bá fẹ́, kí n pàṣẹ fún ọkàn mi láti tẹ̀ síwájú ní ẹ̀gbẹ́ ẹ̀mí mi tí ó ti kún fún ìgbàgbọ́, dípò gbígba ọkàn mi láàyè láti sá sẹ́yìn.

Mo sì n gbé lórí ìmọ̀ràn yìí. Ní àwọn ìgbà míràn, mo ti dá lọ sí yàrá tí ó farasin àpèjúwe ìpèníjà olórí, gbé ijoko kan sí àárín rẹ̀, mo sì ti gun orí ijoko náà. Láti àyè yẹn, mo ṣe àṣàrò lórí ibi àṣẹ tí Olúwa ti pè mí sí. Láti orí òkè náà, mo gb'àdúrà fún àwọn mìíràn àti fún ara mi. Ní ohùn òkè, mo pàṣẹ fún ọkàn mi láti dúró ní ipò tuntun náà àti láti wà ní àlàáfíà. Mo sọ bẹ́ẹ̀ni sí Olúwa àti rárá sí àwọn iyèméjì mi. Ìmọ̀ràn yẹn ti di ọgbọ̀n tí ó dájú fún ìgbésí ayé mi, ohùn Olúwa nípasẹ̀ olùkọ́ tí mo gbẹ́kẹlé.

Ọjọ́ 10Ọjọ́ 12

Nípa Ìpèsè yìí

Conversations With God

Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ Pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́ ìfarajìn onínú dídùn sí ìgbésí-ayé àdúrà tó jinlẹ̀, pẹ̀lú àwọn ọ̀nà tí a lè gbà gbọ́ ohùn Ọlọ́run. Ọlọ́run fẹ́ kí a ní ìfọ̀rọ̀wérọ̀ tí kò ní ìdíwọ́ jálẹ̀ ayée wa—ìfọ̀rọ̀wérọ̀ tí yóò mú ìyàtọ̀ wá nínú ìṣísẹ̀, ìbáṣepọ̀, àti ìgbésí-ayé tó ní ìtumọ̀. Ètò yí kún fún àwọn ìtàn nípa bí a ti dé oókan àyà Ọlọ́run. Ó fẹ́ràn wa!

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Susan Ekhoff fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ lọ sí: https://www.amazon.com/Prayer-That-Must-Power-Conversational/dp/1496185560/ref=sr_1_1?ie=UTF8&qid=1498693709&sr=8-1&keywords=prayer+that+must%2C+the+power+of+conversational+prayer