Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ Pẹ̀lú Ọlọ́runÀpẹrẹ

Conversations With God

Ọjọ́ 10 nínú 14

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti lọ sí ọ̀run ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ṣáájú ìgbéyàwó mi sínú ẹbí náà, mo gbọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìtàn nípa ìyá-ìyá ọkọ mi Emma Bald Ekhoff. Ogún rẹ̀ ni àwọn àdúrà gbígbóná rẹ̀. Ọ̀rẹ́ kan jẹ́wọ́, “Àwọn àdúrà Emma kan ọ̀run.” Nítorí náà, o lè ro bí ìdùnnú mi ti pọ̀ tó ní ọ̀sán ọjọ́ kan nígbà tí a túlé tí a sì rí díẹ̀ nínú àwọn ẹrù Emma, tí ọ̀kan lára wọn sì jẹ́ ìwé àkọọ́lè rẹ̀! Mo ṣí ìwé dúdú kékeré náà, mo ṣì bẹ̀rẹ̀ síí kà á pẹ̀lú ìrètí. Àkọsílẹ̀ wà fún púpọ̀ nínú ọjọ́ ti ọdún 1942. Mo kà á títí dé ọ̀rọ̀ ìkẹhìn, lẹ́hìn náà mo pa á dé mọ sí gbe tì s'ẹ̀gbẹ́. Òtítọ́ kikorò ibẹ̀ ni wípé: Kò sí nkankan níbẹ̀.

Oṣù Kẹta Ọjọ́ 3: “Mo lo aṣọ mo sì gán àwọn ìbọ̀sẹ̀.”

Oṣù Kẹta Ọjọ́ 8: “Gbogbo wá lọ sí ilé ìjọsìn. Douglas wá síbí fún oúnjẹ alẹ́. Afẹ́fẹ́ fẹ́ púpọ̀.”

Oṣù Kẹta Ọjọ́ 9: “Mo ṣe ìmọ́tótó ilé oúnjẹ. Ọjọ́ òní l'ẹ́wà. Kọ àwọn lẹ́tà.”

Njẹ́ ó dùn láti kà? Bẹ́ẹ̀ni, nítorí ìwọ̀nyí ni àwọn àlàyé ìgbésí ayé àgbẹ̀ ti aarin-ọrundun. Ṣùgbọ́n ó jẹ́ ìwòye kékeré nípa ohun tí ó tóbi. Gbólóhùn ọ̀rọ̀ tí ó ní ìtara jùlọ ní ọdún kan ni, “Òní ni ọjọ́-ìbí Dick (ọkọ rẹ̀). Mo nífẹẹ rẹ̀ gan.”

Wòye pẹ̀lú mi. Kíni o rò pé yóò ti túmọ̀ sí fún mi láti ni ẹsẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀, tàbí àwọn ìlépa rẹ̀ fún ọdún kan? Báwo ni ipa ìmọ̀ràn dídára kan ìbá ti wúlò tó, tàbí ohun tí ó fẹ́ràn nípa Jésù àti ìdí rẹ̀? Báwo ni ìbá ti ṣe pàtàkì tó láti ni àdúrà kíkọ kan ṣoṣo - bó ti lè jẹ́ ọ̀kan?

Ìwé kékeré Emma wà níwájú mi báyìí, mo sí n rò ó: Njẹ́ yóò ti kọ oríṣiríṣi nkan nípa ìbáṣepọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run tí ó bá mọ̀ wípé màá fẹ́ láti mọ̀? Njẹ́ yíò fẹ́ kí ìrírí rẹ̀ nínú àdúrà wà nínú ìwé mi lórí àdúrà? Bẹ́ẹ̀ni. Dájúdájú.

Aadọrin ọdún sí ìgbà yìí, nígbà tí àpótí wa náà bá jẹ́ ṣíṣí nípasẹ̀ ìran tí a kò tíì pàdé, kíni ìkíni tí yóò ṣàn jáde ní ìmọlẹ̀ fèrèsé ayé wa? Njẹ́ ohunkóhun wà tí a yóò fẹ́ sọ nípa ẹbí? Nípa ÌGBÀGBỌ́? Njẹ́ àdúrà kan wà nínú ọkàn wa fún àwọn tí yóò wá lẹ́hìn wa?

Àwọn ìjíròrò ìkọ̀kọ̀ wa pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́ ohun tí ó níye lórí — tí ó níye lórí púpọ̀, wọ́n sì ní agbára láti f'ọwọ́ tọ́ àwọn ìran tí a kò ní pàdé láíláí.

Ọjọ́ 9Ọjọ́ 11

Nípa Ìpèsè yìí

Conversations With God

Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ Pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́ ìfarajìn onínú dídùn sí ìgbésí-ayé àdúrà tó jinlẹ̀, pẹ̀lú àwọn ọ̀nà tí a lè gbà gbọ́ ohùn Ọlọ́run. Ọlọ́run fẹ́ kí a ní ìfọ̀rọ̀wérọ̀ tí kò ní ìdíwọ́ jálẹ̀ ayée wa—ìfọ̀rọ̀wérọ̀ tí yóò mú ìyàtọ̀ wá nínú ìṣísẹ̀, ìbáṣepọ̀, àti ìgbésí-ayé tó ní ìtumọ̀. Ètò yí kún fún àwọn ìtàn nípa bí a ti dé oókan àyà Ọlọ́run. Ó fẹ́ràn wa!

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Susan Ekhoff fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ lọ sí: https://www.amazon.com/Prayer-That-Must-Power-Conversational/dp/1496185560/ref=sr_1_1?ie=UTF8&qid=1498693709&sr=8-1&keywords=prayer+that+must%2C+the+power+of+conversational+prayer