Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ Pẹ̀lú Ọlọ́runÀpẹrẹ

Ṣíṣe àkíyèsí àti jíjẹ ìgbádùn ohùn Ọlọ́run ti wá di ìdáwọ́lé mi tó móríwú jùlọ. Ohùn Rẹ̀ a máa mú ìwàláàyè àti ìfaramọ́ Rẹ̀ hàn sí mi. Bí Ó ti ń fọhùn, ni Ó ń fi ìfẹ́ Rẹ̀ rọ̀gbà yí mi ká. Fún ìdí yìí gbígbọ́ ohùn Rẹ̀ túmọ̀ sí níní ìbápàdé pẹ̀lú Rẹ̀.
Ìrírí ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ wípé ń kò nílò láti fòyà wípé Jésù fẹ́ fọhùn nítorí ohùn yí a máa fi ìwàláàyè Rẹ̀ hàn, àti wípé ìṣẹ̀dá Rẹ̀ jẹ́ èyí tó láàánú—kódà nígbà ìbáwí. A máa buyì fún ni bí ọkọ-ìyàwó ti ń bọlá fún aya rẹ̀. Inú rere Rẹ̀ tí kò nípẹ̀kun ń kọ́ mi láti máa jẹ́rìí Rẹ̀ síbẹ̀.
Ǹkan àkọ́kọ́ tí máa ń mú mi mọ dájú wípé Ọlọ́run ń bá mi sọ̀rọ̀ ni wípé ohùn Rẹ̀ yóò gba ọkàn mi kan. Ní irú àkókò yí kò lè sí iyèméjì nípa ìbáraẹnìsọ̀rọ̀ náà. Àmọ́ ọ̀rọ̀ Rẹ̀ lè fẹ́ farajọ èrò ọkàn mi tàbí ìmọ̀ràn àwọn tó wà ní àyíká mi. Nígbà náà ni ń ò wá máa wòye wípé, “Ǹjẹ́ Ọlọ́run ń sọ̀rọ̀ bí, àbí ọkàn, ìpinnu àti ìmọ̀lára mi ló ń tàn mí jẹ?”
Nígbà kan mo gbàdúrà s'Ọ́lọ́run nípa ìpèníjà dídá ohùn Rẹ̀ mọ̀. Ǹkan tó fihàn mí jẹ́ ìyàlẹ́nu. Ó sọ wípé ní ọ̀pọ̀ ìgbà tí mo ń fara balẹ̀ láti wòye bóyá òhun ló ń sọ̀rọ̀, òhun ló padà jẹ́. Ọkàn mi wá pòrùúru nítorí ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo ti kọ etí-ìkún sí ọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ Rẹ̀ èyí tó túmọ̀ sí àìgbọràn. Òfin tí mo wá padà tẹ̀lé nìyí: tí mo bá nílò láti dúró láti tọ pinpin àti láti béèrè wípé, “Ǹjẹ́ Ọlọ́run ni èyí?”—Ọlọ́run ló ma fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́! Òye nípa bí o ṣe máa tẹ̀síwájú ni yóò wá kàn lẹ́yìn tí o bá ti gbà wípé Òhun ló ń sọ̀rọ̀.
Ní ṣeni òǹgbẹ fún ìbáraẹnisọ̀rọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run wá ń gbẹ mí. Èrò nípa Rẹ̀ a máa fúnni ní ọgbọ́n aláìlábùkù, ní ìyàtọ̀ kedegbe sí àwọn ìlépa ẹran-ara tí ń jọba nínú mi. Nígbà tó bá sọ̀rọ̀, a máa mú òtítọ́ jẹyọ, pẹ̀lú ìmúgbòòrò òye mi nípasẹ̀ ìmọ̀ràn Rẹ̀. Nínú ìfihàn àti ìtọ́ni ọ̀tun Rẹ̀, mo ma ń rí ìyápadà ìyanu nínú òye mi tóbẹ́ẹ̀gẹ́ tí àìlóye mi nípa ǹkankan yóò yí padà sí òye kíkún láàárín ìṣẹ́jú-àáyá; tí n ó sì kọ hà wípé, “Kódà! Ó ti yémi báyìí.”
Bí ẹ̀mí mi ti ń wòye ìbánisọ̀rọ̀ àti ìwàláàyè Rẹ̀, àlàáfíà yóò wọlé yóò sì yí mi ká pẹ̀lú, tàbí kí ayọ̀ aláìlábùkù máa sun nínú ọkàn mí. Omijé lè tẹ̀lé. Mo lérò wípé ìkáàánú Rẹ̀ ló máa ń mú wa rí èsì gbà ní onírúurú ọ̀nà. Ohùn Rẹ̀ ní máa mú èsì yí wáyé—èyí tí yóò mú wa lọ sí ipele tókàn nínú ìfọ̀rọ̀wérọ̀ pẹ̀lú Rẹ̀.
Nípa Ìpèsè yìí

Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ Pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́ ìfarajìn onínú dídùn sí ìgbésí-ayé àdúrà tó jinlẹ̀, pẹ̀lú àwọn ọ̀nà tí a lè gbà gbọ́ ohùn Ọlọ́run. Ọlọ́run fẹ́ kí a ní ìfọ̀rọ̀wérọ̀ tí kò ní ìdíwọ́ jálẹ̀ ayée wa—ìfọ̀rọ̀wérọ̀ tí yóò mú ìyàtọ̀ wá nínú ìṣísẹ̀, ìbáṣepọ̀, àti ìgbésí-ayé tó ní ìtumọ̀. Ètò yí kún fún àwọn ìtàn nípa bí a ti dé oókan àyà Ọlọ́run. Ó fẹ́ràn wa!
More