Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ Pẹ̀lú Ọlọ́runÀpẹrẹ
Olúwa a máa fi ohun rè tọ́ wa, àwa náà a máa f'èsì pèlú ohùn wa. Ṣé kò t'ọ̀ná pé eni tí ó pe ara rẹ̀ ní Ọ̀rọ̀ a máa f'igbá gbogbo s'ọ̀rọ̀? Átipè, Òun t'ó dá'wa láti bá Òun jíròrò, fi ara rẹ̀ 'rúbọ kí a baá lé padá s'ọ́dọ̀ rẹ̀. Ó mọ ohun tí a ó sọ kí a tóo sọọ́, Ó fé láti gbọ́ ohùn wa bí a tí n náà sọ̀rọ̀?
Ọpẹ́ ibẹ̀ ni wípé, ìjíròrò yìí tó ní ìtumọ̀ jùlọ kò dá lòríi bí a se dára tó, àwọn àmúye wá, tàbí lóríi bí àwọn ìbéèrè wa se dáńgájíá tó. Ánfáání ìgbọràn tiwa áti bí Ọlọ́run ti ń gbọ́ wa dá lóríi ìrúbọ Jésù nìkan.
Ìjíròrò yìí bẹ̀rẹ̀ nígbátí Olúwa bá kàn sí wa. Ìfẹ́ ni Ọlọrun àtipé ìfẹ́ rẹ̀gbọdọ̀ dé ibi ìbáṣepọ̀. Ojúṣe wa ni láti dá ohùn Rẹ̀ mọ̀ kí a sì dáa l'óhùn. Nígbà náà ni Òun pẹ̀lú yó dáhùn l'ódodo. Bí a ṣe ńretí ìdáhùn, a ó máa gbádùn ìwàláàyè rẹ̀, a o gbọ́ràn, a o sì gbékèlée. Mo lérò pé ìfọ̀rọ̀wérọ̀ yìí ni Pọ́ọ̀lù ńrọ̀ wà fún n'ígbà tí ó sọ pé "gbàdúrà nígbà gbogbo." Nínú àdúrà, à ń f'etí sílẹ̀ f'Ólúwa tàbí kí a tú ọkàn wa palẹ̀ fún un, kí a sì máa f'ojú sọnà fún èsì lat'ọdọ Rẹ̀. Ojúṣe àti ayọ̀ ayé wa nìyí. Lẹ́yìnọ̀reyìn, a ó ríi wípé a ò le wà láìsí Oluwa tí ń darí ìjíròrò wa. Ò pọndandan lati gbàdúrà.
Láì déènà p'ẹnu, àdúrá a máa gbé'ni ró, a sì máa ró 'ni l'ágbára. Ìjíròrò wa pèlú Olórun a máa fún wa ní ogbọ́n, a sì máa fi àlàáfíà jínkí wa. Ní'gbà tí ñkan bá r'újú, ádùrá ni ohun tó kàn láti ṣe. Àdúrà jẹ́ ìrọ̀rùn. Kò n'ira. Ìsinmi ní.
ìf'ọ̀rọ̀ jomitooro ọ̀rọ̀ pẹ̀ú Ọlórun ni ọ̀nà àbáyọ sí ìpòǹgbẹ wa láti ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lu Ọlórun - níkánkán. Gẹ́gẹ́ bíi ìfọ̀rọ̀wérọ̀ Tevya pẹlu Olorun nínú ìwé Fiddler on the Roof, à ń sọ̀rọ̀, a sì ńretí èsí l'ọ́jọ́ ayé wa gbogbo. Ìgbà gbogbo ni Olúwa npè wa tí Ó sì ń retí kí ìfojúsùn wa yípadà. Mo máa ńwòye èrèdìí rẹ̀ tí o fi máa n pẹ́ wa láti bá Olúwa kọ́wọ̀ọ́rìn. Ìgbàtí a bá yípadà, ọ̀gangan Rẹ̀ la ó se—Ẹni tó jẹ́ Èsì náà.
Nípa Ìpèsè yìí
Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ Pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́ ìfarajìn onínú dídùn sí ìgbésí-ayé àdúrà tó jinlẹ̀, pẹ̀lú àwọn ọ̀nà tí a lè gbà gbọ́ ohùn Ọlọ́run. Ọlọ́run fẹ́ kí a ní ìfọ̀rọ̀wérọ̀ tí kò ní ìdíwọ́ jálẹ̀ ayée wa—ìfọ̀rọ̀wérọ̀ tí yóò mú ìyàtọ̀ wá nínú ìṣísẹ̀, ìbáṣepọ̀, àti ìgbésí-ayé tó ní ìtumọ̀. Ètò yí kún fún àwọn ìtàn nípa bí a ti dé oókan àyà Ọlọ́run. Ó fẹ́ràn wa!
More