Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ Pẹ̀lú Ọlọ́runÀpẹrẹ
Nígbà tí Ọlọ́run bá ṣe tán láti farahàn nínú ayé wa, ìfihàn a máa jẹ yọ ní ìgbà kéréje—kódà ní ìṣẹ́jú-àáyá, a sì lè ré kọjá sínú ipele ìgbàgbọ́ tó ṣe kàyéfì sí wa tẹ́lẹ̀. Èyí ni ìjẹ́rìí sí irúfẹ́ ìsọnijí ti ẹ̀mí tó ṣẹlẹ̀ nínú ayé mi.
Ìrírí náà bẹ̀rẹ̀ nígbà tí mo gbọ́ wípé a ti pe àwọn ènìyàn Ọlọ́run láti ní ìbáṣepọ̀ ara-ẹni pẹ̀lú Ẹ̀mí Mímọ́. Mo ti kà nípa Ẹ̀mí Mímọ́ nínú Bíbélì, mo ti jẹ́ ìgbádùn díẹ̀ nínú àwọn ẹ̀bùn Rẹ̀, mọ àǹfààní ìwàláàyè Rẹ̀, ti ṣe àmúlò àwọn èso Rẹ̀ àmọ́ n kò mọ̀ Ọ́ . Bí mo ṣe kùnà ipele ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú Ẹ̀mí yìí, wá jẹ́ kàyéfì fún mi. Àmọ́ ní ìdàkejì ọ̀nà wo ni ìyá ọlọ́mọ wẹ́wẹ́ mẹ́ta ṣe fẹ́ wá àyè àti okun láti bá Ọlọ́run rìn ní kíkún láì ní ìdíwọ́?
Mo wá padà pinu pẹ̀lú ìgbésẹ̀ láti ṣètò ibi kọ́lọ́fín kan nínú ilé mi pẹ̀lú àwọn ohun èlò ìkẹ́kọ̀ọ́, àga, tábìlì kan tí a kò lò mọ́, lẹ́yìn èyí ni mo wá gbé ẹ̀rọ-ìtanijí mi sí ago mẹ́rin-àbọ̀ ìdajì, bẹ́ẹ̀ni, mẹ́rin-àbọ̀! Bí oúnjẹ ẹ̀mí ti ń pa mí tó nìyí.
Nígbà tí ẹ̀rọ ìtanijí yìí bá figbe ta fún mi láti dìde, mo máa wá bẹ̀rẹ̀ sí ní pàrọwà fún ra mi wípé ǹkan tí mo nííṣe ṣe pàtàkì, títí n ó fi ká ìbora kúrò. Ibi kọ́lọ́fín tí mo ṣètò kò tún wá mú ìwúrí wá. Lẹ́yìn wá gbogbo rẹ̀, inú ẹ̀fọn ni mo máa ń dé ara mi mọ́ níbẹ̀. Ojú mi pẹ̀lú á wá ṣú tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí ó máa ń nira láti ríran. Mo ti wá dé'bẹ̀ báyìí, àmọ́ kí ló kù? Báwo ni èèyàn tilẹ̀ ṣe lè dá Ẹ̀mí Ọlọ́run mọ̀ ná?
Lọ́pọ̀ ìgbà ni mo máa ń bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú orin kíkọ àti kíka Bíbélì jáde nítorí èyí yóò ràn mí lọ́wọ́ láti má padà sùn, ṣùgbọ́n lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ oṣù ìwà yí wá di bárakú fún mi. Mo kọ́ bí a ti ń gbẹ́kẹ̀lé Ẹ̀mí Mímọ́ láti ṣe ìfihàn àwọn èrò Baba àti láti gbàdúrà lórí ohun tí a fi hàn mí. Ìwé Mímọ́ wá di ọ̀tun pẹ̀lú ìtọ́ni Ẹ̀mí Mímọ́. Àdúrà ń bọ́ pẹ̀lú ìgboyà—Olúwa sì ń fi ìdáhùn sí àwọn àdúrà mi.
Nínú ìtiraka àtètèkọ́ṣe, mo fẹ́rẹ̀ẹ́ kọ gbogbo ìlépa mi sílẹ̀. Àmọ́ nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí ní gbọ́ràn sí ìpè Ẹ̀mí tó nípọn láti wa kọ́ nípa Rẹ̀, ó wá kọ́ mi láti fẹ́ràn Rẹ̀ bí Ènìyàn Ẹlẹ́ran Ara. Ní báyìí mo mọ̀ látinú ìrírí wípé a ṣẹ̀dá wa láti ní ìbáṣepọ̀ ìfẹ́ tó nípọn pẹ̀lú Ẹ̀mí Mímọ́. Òhun ni yóò wá pilẹ̀ṣẹ̀ gbogbo ìfọ̀rọ̀wérọ̀ láàárín wa.
Nípa Ìpèsè yìí
Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ Pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́ ìfarajìn onínú dídùn sí ìgbésí-ayé àdúrà tó jinlẹ̀, pẹ̀lú àwọn ọ̀nà tí a lè gbà gbọ́ ohùn Ọlọ́run. Ọlọ́run fẹ́ kí a ní ìfọ̀rọ̀wérọ̀ tí kò ní ìdíwọ́ jálẹ̀ ayée wa—ìfọ̀rọ̀wérọ̀ tí yóò mú ìyàtọ̀ wá nínú ìṣísẹ̀, ìbáṣepọ̀, àti ìgbésí-ayé tó ní ìtumọ̀. Ètò yí kún fún àwọn ìtàn nípa bí a ti dé oókan àyà Ọlọ́run. Ó fẹ́ràn wa!
More