Luk 6:46-49

Luk 6:46-49 YBCV

Ẽsitiṣe ti ẹnyin npè mi li Oluwa, Oluwa, ti ẹnyin kò si ṣe ohun ti mo wi? Ẹnikẹni ti o tọ̀ mi wá, ti o si ngbọ́ ọ̀rọ mi, ti o si nṣe e, emi o fi ẹniti o jọ hàn nyin: O jọ ọkunrin kan ti o kọ́ ile, ti o si walẹ jìn, ti o si fi ipilẹ sọlẹ lori apata: nigbati kíkun omi de, igbi-omi bilù ile na, kò si le mì i: nitoriti a fi ipilẹ rẹ̀ sọlẹ lori apata. Ṣugbọn ẹniti o gbọ́, ti kò si ṣe, o dabi ọkunrin ti o kọ́ ile si ori ilẹ laini ipilẹ; nigbati igbi-omi bilù u, lọgan o si wó; iwó ile na si pọ̀.

Àwọn fídíò fún Luk 6:46-49

Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú Luk 6:46-49