Ìmọ̀lára Mímọ́ - Èsì Látinú Bíbélì sí Ìpèníjà GbogboÀpẹrẹ
Ẹ́stérì jẹ́ ọmọ òrukàn, ọ̀kan nínú àwọn àbúrò àwọn òbí rẹ̀ tó jẹ́ àpọ́n tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Modikáì ló sì tọ́ ọ dàgbà. Nígbà tí Ọba Ahasérù pinnu láti fẹ́ ìyàwó tuntun, àwọn ẹmẹ̀wá rẹ̀ ṣeètò ìdíje fún àwọn arẹwà obìnrin írú eléyì tí ayé kò rí irú ẹ̀ rí.
Ẹ́sterì ló borí ìdíje náà ó sì rí ojú rere gbà lọ́dọ̀ gbogbo àwọn tó wà láàfin.
Nítorí pé Modekáì, ẹ̀gbọ́n Ẹ́sterì kọ̀ láti forí balẹ̀ fún Hámánì tó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ẹmẹ̀wá ọba, wọ́n pinnu pé Modekáì ní láti kú, Hámánì tún wa gba ìyọ̀nda láti ọ̀dọ̀ ọba láti pa gbogbo àwọn ìran Júù. Nígbà tí Modekáì gbọ́ nípa èrò búburú yìí, ó fa aṣọ ya mọ́'ra rẹ̀ lọ́rùn, ó gbé aṣọ ọ̀fọ̀ wọ̀ ó sì ku eérú lé ara rẹ̀ lórí, lẹ́hìn náà ló wá jáde lọ sí àárín ìgboro tó sì ń pohùnréré ẹkún.
Ìṣesí Modekáì sí àyídàyídà yíì lè jẹ́ bí ìwọ náà ṣe n hùwà sí àwọn nnkan tó ń lọ nínú ayé rẹ. Nígbà tí nnkan kò bá lọ bí o ṣe fẹ́, ìwọ náà máa ń ṣe bí Modekáì, ìwọ náà á gbé aṣọ ọ̀fọ̀ rẹ wọ̀, gbogbo ayé kò wá ní ré'tí gbọ́ràn nítorí kíkùn àti àròyé rẹ!
Tí o bá fi ìmọtara-ẹni-nìkan àti ìwà ọmọdé rin ìrìnàjò rẹ láyé pẹ̀lú aṣọ ọ̀fọ̀ ati eérú lórí rẹ, wàá pàdánù ore ọ̀fẹ́ láti rìn tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọba àwọn ọba! Àmọ́ ... Krìstẹ́nì lo ṣì jẹ́ o, wà sí tún ní ànfààní láti gbé pẹ̀lú Jésù títí láé, ṣùgbọ́n kíkó ìrora tí ò ń là kọjá lé góńgórí ẹ̀mí rẹ kò ní fún ọ ní ànfààní láti mọ adùn tó wà nínú ìdàpọ̀ pẹ̀lú Rẹ̀ nígbà tí o wà láyé.
A máa ń ṣe àṣìṣe kan pé tí a bá kígbe sókè dáadáa, Ọlọ́run yóò tẹ́'tí sí wa. Ṣùgbọ́n kò rí bẹ́ẹ̀, kọ́kọ́rọ́ tí ó ń gbé'ni dé iwájú Rẹ̀ ni ìdúpẹ́!
Nígbà tí Ayaba Ẹ́stérì gbọ́ nípa àrà tí È̩gbọ́n rẹ̀ Modekáì ń dá pẹ̀lú ẹkún àti aṣọ ọ̀fọ̀ níwájú ilé ọba, ó fi aṣọ tuntun ránṣẹ́ sí Modekáì ṣùgbọ́n ó kọ̀ láti wọ̀ ọ́. È̩mí Mímọ́ ti fún àwa náà ní aṣọ tuntun láti wọ̀, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ìgbà ni a máa ń kọ̀ láti gbé ẹ̀wù ìyìn wọ̀, dípò bẹ́ẹ̀, a máa ń yàn láti máa kiri ká ayé nínú aṣọ ìrora. Ọba àwọn ọba mọ̀ pé níwájú Òun ni ìgbé ayé ìṣẹ́gun rẹ wà, ilẹ̀kùn ibẹ̀ sì ṣí sílẹ̀ gbayawu fún ọ láti wọlé. Àmọ́, ó ṣe ni láànú pé o kò lè wọ inú àgbàlá àafin Rẹ̀ pẹ̀lú aṣọ tó ń tọ́ka sí ìjákulẹ̀ ayé rẹ.
Gbé agbádá ìyìn wọ̀! Dípò kí o máa yírà nínú ẹ̀dùn ọkàn ... ká ọwọ́ rẹ sókè kí o sì lọ síwájú Rẹ̀ pẹ̀lú ìyìn!

Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Ọlọ́run dá ọ Ó sì fi ọ sí àyè tí o wà ní irú àkókò yìí, to love the unlovable, bii àlàáfíà nínú rúkè rúdò, kí o sì fi ayọ̀ tí kò ṣeé dẹ́kun nínú ìṣẹ̀lẹ̀ gbogbo. À ti ṣe bẹ́ẹ̀ lè jọ pé kò ṣeéṣẹ, ṣùgbọ́n o le è ṣeé tí o bá kọ́ oun tí Bíbélì sọ nípa àwọn ìmọ̀lára ọkàn rẹ gẹ́gẹ́ bí ènìyàn àti bí o tilè ṣàkóso wọn. Ètò ẹ̀kọ́ yìí dá lórí àwọn ohun tí a kò kà sí àti nígbà míràn awon ohun ìdojúkọ tí kìí ṣe lásán tí à ń bá pàdé lojojúmọ́, ó sì fún wa ní ìtọ́kasí ẹsẹ̀ Bíbélì láti ṣàkóso ìmọ̀lára wa ní ọ̀nà bíi ti Ọlọ́run.
More
A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Carol McLeod and Just Joy Ministries fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé díẹ̀ síi, jọwọ lọsí: www.justjoyministries.com