Ìmọ̀lára Mímọ́ - Èsì Látinú Bíbélì sí Ìpèníjà GbogboÀpẹrẹ

Holy Emotions - Biblical Responses to Every Challenge

Ọjọ́ 12 nínú 30

Olúwa dá ọ láti gbèrú àti láti gbilẹ̀ láì l'ábùtán. Ó mọ ọ́ ní ẹ̀mí fún ìmọ̀lára ọkàn àti ẹ̀mí tó bùyààrì ní ìgbà yíò wù ọjọ́ ayé rẹ. Kìí ṣe ètò Rẹ̀ rárá fún ọ láti rán nínú ìmọ̀lára ọkàn rẹ tàbí kí á tẹ̀ ọ́ mọ́lẹ̀ pẹ̀lú ìbínú àti ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn tàbí ìrònú. Ọlọ́run mọ̀ pé gbogbo wa yóò la afẹ́fẹ́ ìjì líle àti ìbàjẹ́ àṣà wa knew, ṣùgbọ́n ọgbọ́n ìṣẹ̀dá Rẹ̀ ti ṣe ọ̀nà àbáyọ fún wa láti dúró ṣinṣin nínú Àjàrà náà nígbàtí à ń la àwọn rúkè rúdò ìgbà kọjá. Ìfé Ọlọ́run fún ọ ni pé kí o gbèrú ní gbogbo agbọndan ayé rẹ èyí sì pẹ̀lú ìmọ̀lára ọkàn rẹ!

Ọ̀rọ̀ tí a túmọ̀ sí "gbèrú" ní èdè Hébérù ní ìtumọ̀ tó níye ní ìtumọ̀ àti ìlò. Ọ̀rọ̀ yìí ní gbogbo ìgbà má a ń sọ nípa oun kan tàbí ẹnìkan tí óún gbòòrò si ní kóyá kóyá. "Gbèrú" jẹ́ ọ̀rọ̀ tó ń fi àwòrán irúgbìn tí a ti kọ pé yóò dàgbà láì sí ìdíwọ́ láì fi ti ojú ọjọ́ tàbí ọ̀dá ṣe.

Oní Sáàmù kéde pé, "Olódodo yóò gbèrú bí i igi ọ̀pẹ." Tí Bíbélì bá pe ènìyàn ní "olódodo," o túmọ̀ sí pé ẹni bẹ́ẹ̀ ti finú fẹ́dọ̀ yàn láti darapọ̀ mọ́ Ọlọ́run. Wọ yóò gbèrú, lẹ́yìn náà, ní bí sí sopọ̀ wọn pẹ̀lú Ọlọ́run bá ṣe rí! Tí o bá yàn láti máa gbá yùn níwájú Rẹ̀ lojojúmọ́ àti láti lo àkókò nínú Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ àti nínú àdúrà, ayé rẹ yóò di àjítanáwò gàgàrà ìtẹ̀síwájú tí óún jẹ yọ nípa sí so pọ̀ pẹ̀lú òdodo Rẹ̀.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Kristẹni ni ó ṣì ní àsopọ̀ sí ìrora àtijọ́ ju bí wọ́n ṣe mọ tòótọ́ wíwà-pẹ̀lú Ọlọ́run ní ojojúmọ́. Ó ṣe kókó fún ọ nínú ìmọ̀lára ọkàn rẹ bóyá o ka ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lojojúmọ́. Ó ṣe kókó ní tòótọ́ fún ọ ní ìmọ̀lára ọkàn rẹ bí o bá tàbí o kò bá jọ́sìn láì bìkítà ìjákulẹ̀ rẹ. Ó ṣe kókó ní tòótọ́ fún ọ ní ìmọ̀lára ọkàn rẹ bí o bá gbàdúrà fún àwọn tó ti wùwà àìláàánú sí ọ. Ó ṣe kókó ní tòótọ́.

Tí o bá yàn dára dára, Ọlọ́run Á mú kí ìdàgbàsókè wa! Wà á má dàgbà si ní kóyá kóyá nínú ẹ̀mí ati ní ìmọ̀lára ọkàn nítorí pé òun gbà ìyè láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Èso ti ẹ̀mí yóò sọ ọ́ di ẹnití ó ní ìwà bí Ọlọ́run, ní ọ̀nà ìyanu.

O gbọ́dọ̀ ṣíṣe ní ìfọwọ́ ṣọwọ́ pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run títí tí ìgbónára àti ìfèsìpadà rẹ sí oun tó yí ọ ká yóò fi túmọ̀sí ìbáṣepọ̀ tó jinlẹ̀ tó tún níye lórí pẹ̀lú Rẹ̀.
Ọjọ́ 11Ọjọ́ 13

Nípa Ìpèsè yìí

Holy Emotions - Biblical Responses to Every Challenge

Ọlọ́run dá ọ Ó sì fi ọ sí àyè tí o wà ní irú àkókò yìí, to love the unlovable, bii àlàáfíà nínú rúkè rúdò, kí o sì fi ayọ̀ tí kò ṣeé dẹ́kun nínú ìṣẹ̀lẹ̀ gbogbo. À ti ṣe bẹ́ẹ̀ lè jọ pé kò ṣeéṣẹ, ṣùgbọ́n o le è ṣeé tí o bá kọ́ oun tí Bíbélì sọ nípa àwọn ìmọ̀lára ọkàn rẹ gẹ́gẹ́ bí ènìyàn àti bí o tilè ṣàkóso wọn. Ètò ẹ̀kọ́ yìí dá lórí àwọn ohun tí a kò kà sí àti nígbà míràn awon ohun ìdojúkọ tí kìí ṣe lásán tí à ń bá pàdé lojojúmọ́, ó sì fún wa ní ìtọ́kasí ẹsẹ̀ Bíbélì láti ṣàkóso ìmọ̀lára wa ní ọ̀nà bíi ti Ọlọ́run.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Carol McLeod and Just Joy Ministries fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé díẹ̀ síi, jọwọ lọsí: www.justjoyministries.com