Ìmọ̀lára Mímọ́ - Èsì Látinú Bíbélì sí Ìpèníjà GbogboÀpẹrẹ
Kò sí èyíkéyìí ìpòrúùru ọkàn tí ò ń d'ojúkọ tí o sì ń bá jìjàkadì lónìí, nígbàtí o bá na'wọ́ gán ọgbọ́n tí ń bẹ nínú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti agbára Ẹ̀mímímọ́, ìdánilójú wà pé oó borí ogunkógun tí o bá d'ojúkọ. O kìí ṣe ẹrú ìpòrúùru ọkàn àti réderède ṣùgbọ́n o ju aṣẹ́gun lọ nítorí ìfẹ́ ńlá Krístì sí ọ.
Ọlọ́run ní ètò fún ìgbé ayé rẹ ojoojúmọ́, ètò Rẹ̀ sì jẹ̀ ti ayọ̀, àlááfìa àti ìṣẹ́gun. Ọlọ́run fẹ́ kí o borí gbogbo ìpòrúúru ọkàn nítorípé o jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára ètò ńlá Rẹ̀ fún àkókò yìí. Bí o bá ńtẹ̀síwájú nínú ìráhùn, ìbínú àti nínú ìkárísọ, aráyé yíò pàdánù àǹfààní ẹ̀bùn tí a dá ọ láti jẹ́. O kò gbọdọ̀ rò pé bánkúnjọ lásán lo jẹ́ lọ́dọ̀ Ọlọ́run tàbí pé o kàn lè máa fẹ ìjákulẹ̀ àti ẹ̀rù rẹ lójú kọjá bó ṣe yẹ. O kìí ṣe ọ̀kan lásán lára ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ẹ̀dá ayé, ṣùgbọ́n o jẹ́ ohun èlò iyebíye tí ó lè mú ìyàtọ̀ tó yanrantí bá ayé ní àkókò mánigbàgbé yìí.
Ṣé wàá pinnu láti jẹ́ ẹ̀dà ara rẹ tí o dára jùlọ? Tàbí o fẹ́ jẹ́ àwọn ẹni òdì tí ó yapa kúrò nínú ètò Ọlọ́run fún ayé wọn? Ọlọ́run níílò rẹ! Ó níílò kí o jẹ́ àpẹẹrẹ ààyè ti ayọ̀ àti àlááfíà nígbàtí ayé rẹ bá polúkúrúmusu. Ó níílò kí o jẹ́ iṣẹ́-ọnà tí òdodo atí sùúrù tí ó dàra jùlọ ní àwùjọ tó ti ya ẹhànnà yìí. Ọlọ́run níílò àwọn ọkùnrin àti obìnrin ní ìran gbogbo tí wọn yíó kéde wípé, "Ayé mi kìí ṣe fún mi nìkan. Ayé mi wà láti sin Ọlọ́run àti kí n fi ìṣe Rẹ̀ hàn fún aráyé!"
Ṣé a ó rántí rẹ fún orin ọkàn rẹ tàbí fún ariwo ayé rẹ? Gbogbo wa ni a ó fi ìtàn tí àkójọ rẹ̀ jẹ́ gbogbo ohun tí a fi èrò wa yàn balẹ̀. Àwọn ìyọrísí èrò àti ìṣe ẹ̀mí tí a bá fi sílẹ̀ fún ìran wa gbé ìwọ̀n ju ọrọ̀, ilé tàbí ilẹ̀ tí a fi sílẹ̀ lọ. Bí o ṣe ń wo àwọn èrò ara tí àṣà, àwọn ohun àjogúnbá ẹbí rẹ àti àyídáyidà ayé rẹ mú wá fún ọ, máṣe gbàgbé pé Ọlọ́run ń fi ohun tí ó dára jùlọ fún àwọn tó bá jẹ́ kí Ó Yàn fún àwọn!

Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Ọlọ́run dá ọ Ó sì fi ọ sí àyè tí o wà ní irú àkókò yìí, to love the unlovable, bii àlàáfíà nínú rúkè rúdò, kí o sì fi ayọ̀ tí kò ṣeé dẹ́kun nínú ìṣẹ̀lẹ̀ gbogbo. À ti ṣe bẹ́ẹ̀ lè jọ pé kò ṣeéṣẹ, ṣùgbọ́n o le è ṣeé tí o bá kọ́ oun tí Bíbélì sọ nípa àwọn ìmọ̀lára ọkàn rẹ gẹ́gẹ́ bí ènìyàn àti bí o tilè ṣàkóso wọn. Ètò ẹ̀kọ́ yìí dá lórí àwọn ohun tí a kò kà sí àti nígbà míràn awon ohun ìdojúkọ tí kìí ṣe lásán tí à ń bá pàdé lojojúmọ́, ó sì fún wa ní ìtọ́kasí ẹsẹ̀ Bíbélì láti ṣàkóso ìmọ̀lára wa ní ọ̀nà bíi ti Ọlọ́run.
More
A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Carol McLeod and Just Joy Ministries fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé díẹ̀ síi, jọwọ lọsí: www.justjoyministries.com