Ìmọ̀lára Mímọ́ - Èsì Látinú Bíbélì sí Ìpèníjà GbogboÀpẹrẹ
Ní gbogbo ọ̀gànjọ́ òru tí agogo bá lu méjìlá, o kìí ń yi padà di elégédé ṣùgbọ́n o jẹ́ olùrígbà ẹ̀bùn iyebíye tó ń dán. Gbogbo wa ni à ń rí ẹ̀bùn yìí gbà ní òdinwọ̀n kan náá láì fi bí a ṣe tóbi tó, ọjọ́ orí, ẹ̀kọ́, ẹwà, iṣẹ́ tàbí bóyá èèyàn ti ní ọkọ tàbí ìyàwó ṣe. Bí ojúmọ́ ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ti ń mọ́ ni ìwọ́ nìkan ṣoṣo ń rí 1440 (òjìlénírinwó àti ẹgbẹ̀rún) ọ̀kan lára àwọn ọjà tí ó lágbára jù nínú ìtàn ọmọnìyàn gbà. Ní dédé ìṣẹ́jú-àáyá kan lẹ́hìn agogo méjìlá òru lójoojúmọ́, ọ̀run máa ń ṣí àwọn fèrèsé rẹ̀ láti fún ọ ní 1440 (òjìlénírinwó àti ẹgbẹ̀rún) ìṣẹ̀jú tuntun oníyebíye láti lò. Bí ó ba ṣè wù ọ́ lo ṣe lè lo àwọn ìṣẹ́jú náà! Ọ̀fẹ́ ni àsìkò, ṣùgbọ́n ó ṣe iyebíye
O lè máa ṣ'ofófó tàbí kí o máa sin Ọlọ́run - o lè kún fún ìbínú tàbí ìmoore - o lè sáré ìdárayá fún ibùsọ̀ márùnún tàbí kí o fi gbogbo ọjọ́ wo tẹlifíṣàn - o lè kà'wé tàbí kí o lọ s'ílé ìtajà. Ìwọ nìkan ṣoṣo lo lè pinnu bí o ṣe fẹ́ lo ẹ̀bùn aláìníye tó bù yààmú yìí lọ́nà tó dára. O lè pinnu láti rẹ́rìnín tàbí sunkún - kí o máa ráhùn tàbí kí o máa yọ̀ - kí o máa ronú òdì tàbí ronú ohun rere - kí o kún fún ìkorò tàbí kí o máa tẹ̀síwájú. Tìrẹ nìkan ní ìwọ̀n 1440 (òjìlénírinwó àti ẹgbẹ̀rún) ìṣẹ́jú yìí, kìí ṣe fún ẹlòmíràn! Wọn kìí ṣe fún ọkọ rẹ tàbí ọ̀gá rẹ tàbí àwọn ọmọ rẹ láti lò.
Lóòtọ̀ ni pé àwọn nnkan wà tí a ní láti ṣe. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ wa ni a ní láti ṣiṣẹ́ ṣùgbọn a máa ń yan ọ̀nà tí a ó gbà ṣe iṣẹ́ wa. T'ó bá wù wá, a lè lọ sí ilé isẹ́ wa pẹ̀lú ẹ̀mí ìkanran àti ìfínràn, kí á kún fún ìbínú àti èrò òdì, t'ó bá sì wù wá, a lè kún fún ayọ̀, ẹ̀mí tó ṣetán láti ṣiṣẹ́ kárakára tí ó sì kún fún àdúrà fún àwọn alábáṣiṣẹ́pọ̀ wa. O lè kórìrá gbogbo ìṣẹ́jú t'o fi wà níbi iṣẹ́ tàbí kí o máa f'àsìkò ṣòfò nípa sísọ̀rọ̀ ẹ̀hìn pẹ̀lú àwọn obìnrin l'ọ́ọ́fììsì, o lè máa ṣeré lórí ẹ̀rọ kòmpútà tàbí kí o máa yọ́ jáde l'ọ́ọ́fììsì kí àsìkò lílọsílé tóó tó. O sì lè rí i pé Ọlọ́run fi ẹ́ sínú ọọ́fììsì yìí láti jẹ́ ẹni ìbùkún kí o lè jẹ́ àpẹẹrẹ ọ̀nà tí ó dára jù lọ láti ṣiṣẹ́ àti ìwà mímọ́ Ọlọ́run.
Nítòótọ́, o níláti tọ́jú àwọn òbí rẹ tó ti ń d'ogbó, tọ́ àwọn ọmọ rẹ, kí o sì da pàntí t'ó wà nílú ilé nù. Síbẹ̀síbẹ̀, o ní láti pinnu ọ̀nà tí oò gbà ṣe àwaon nnkan tí o níláti ṣe. O lè la ayé kọjá pẹ̀lú àjàgà wúwo àti ìbànújẹ́ ọkàn, nídà kejì, o lè ṣe gbogbo ojúṣe rẹ láyé pẹ̀lú sùúrù, ìfẹ́ àti ayọ̀.

Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Ọlọ́run dá ọ Ó sì fi ọ sí àyè tí o wà ní irú àkókò yìí, to love the unlovable, bii àlàáfíà nínú rúkè rúdò, kí o sì fi ayọ̀ tí kò ṣeé dẹ́kun nínú ìṣẹ̀lẹ̀ gbogbo. À ti ṣe bẹ́ẹ̀ lè jọ pé kò ṣeéṣẹ, ṣùgbọ́n o le è ṣeé tí o bá kọ́ oun tí Bíbélì sọ nípa àwọn ìmọ̀lára ọkàn rẹ gẹ́gẹ́ bí ènìyàn àti bí o tilè ṣàkóso wọn. Ètò ẹ̀kọ́ yìí dá lórí àwọn ohun tí a kò kà sí àti nígbà míràn awon ohun ìdojúkọ tí kìí ṣe lásán tí à ń bá pàdé lojojúmọ́, ó sì fún wa ní ìtọ́kasí ẹsẹ̀ Bíbélì láti ṣàkóso ìmọ̀lára wa ní ọ̀nà bíi ti Ọlọ́run.
More
A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Carol McLeod and Just Joy Ministries fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé díẹ̀ síi, jọwọ lọsí: www.justjoyministries.com