Ìmọ̀lára Mímọ́ - Èsì Látinú Bíbélì sí Ìpèníjà GbogboÀpẹrẹ

Holy Emotions - Biblical Responses to Every Challenge

Ọjọ́ 23 nínú 30

Dáfídì jẹ́ irú ènìyàn tó wọ́pọ̀ ṣùgbọ́n òún ní irú ọkàn tí kò wọ́pọ̀. Ó tiraka pẹ̀lú ìbínú sùsù bí èmi àti ìwọ ṣe ń ṣe. Ó dúró létí bèbè ọọ̀fìn dúdú ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn láì mọ ye ìgbà, fún ìdí èyí ó mọ kíni ó pè fún láti ja irú ogun bayi. Dáfídì yàn láti pàṣẹ fún ọkàn rẹ, tí ń ṣe ilé ìgbẹ̀bí àwọn èrò wa, ìmọ̀lára ọkàn àti ìrínisí, láti bùkún fún Olúwa. A kọ gbólóhùn ọ̀rọ̀ yí ní ohùn dandan, èyí tí ó túmọ̀sí pé kò sí à ń yàn bíkòṣe ìpaláṣẹ. Ohun tí Dáfídì wáńsọni pé, "Ìwọ ọkàn, bí ó ti wù kí o má nìí àlàáfíà tó, ìwọ yóò bùkún fún Olúwa! Ìrínisí, dẹ́kun ìgbé ara ẹni ga kí o sì yin Olúwa! Nísinsìnyí! Ẹ̀dùn, dákẹ íhan àti ètè tí ó ún ṣàròyé kí o sì ṣí sókè láti sin Olúwa!"

Ìyìn yíò tún afẹ́fẹ́ àgbègbè ayé rẹ ní ọ̀nà tí ẹlòmíràn kò ní agbára láti ṣe. Ẹnìkan wà, àní ẹnì kan ṣoṣo tí ó ń dí ọ lọ́wọ́ láti yọ̀. O lè fẹ́ yíi mọ́ èṣù léṣe ṣùgbọ́n kò ní agbára láti dá ọkàn rẹ dúró ní bíbú sí orin. Ó hàn sí èṣù kedere pé òun kò nílò láti dí ẹ lọ́wọ́ lọ́nà láti sìn nítorí pé enìkejì yìí ti ṣe iṣẹ́ ribiribi tí àrekérekè èṣù gan-an kò fi wúlò mọ́. Tani alágbára olùdènà náà tó dúró láàrín ìwọ àti bíbú jáde símfóní ìyìn ti ìjọsìn? Ìwọ! Ìwọ ni! Ìwọ yàn láti má yọ̀ nígbàtí ìrònú bíi iṣu èèmọ̀ bá gbé ọ mì.

Ìdí kan ṣoṣo náà ló lè wà fún krìstẹ́nì tó fẹ́ràn Jésù tọkàntọkàn ṣe le yàn láti má yọ̀. Ìdí kan náà ló lè wà tí a sì le ṣàlàyé lóríṣiríṣi ọ̀nà. Ìmọtaraẹni. Ìgbé ayé tèminìkan sá Ìwoaráẹni. Fífi ojú síta fún nkan Kíní! Ìfi pamọ́ara ẹni. Ọ̀nà mi tàbí òpópónà. Tèmi l'ayé ń ṣe. Ohunkóhun ò wù mí. Mi ò nílò láti ṣe tí mi ò bá fẹ́.

Tìrẹ ni láti yàn. O lè yàn láti gbé ara rẹ ga lónìí tàbí kí o gbé Ọlọ́run ga. Yàn lónìí.

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 22Ọjọ́ 24

Nípa Ìpèsè yìí

Holy Emotions - Biblical Responses to Every Challenge

Ọlọ́run dá ọ Ó sì fi ọ sí àyè tí o wà ní irú àkókò yìí, to love the unlovable, bii àlàáfíà nínú rúkè rúdò, kí o sì fi ayọ̀ tí kò ṣeé dẹ́kun nínú ìṣẹ̀lẹ̀ gbogbo. À ti ṣe bẹ́ẹ̀ lè jọ pé kò ṣeéṣẹ, ṣùgbọ́n o le è ṣeé tí o bá kọ́ oun tí Bíbélì sọ nípa àwọn ìmọ̀lára ọkàn rẹ gẹ́gẹ́ bí ènìyàn àti bí o tilè ṣàkóso wọn. Ètò ẹ̀kọ́ yìí dá lórí àwọn ohun tí a kò kà sí àti nígbà míràn awon ohun ìdojúkọ tí kìí ṣe lásán tí à ń bá pàdé lojojúmọ́, ó sì fún wa ní ìtọ́kasí ẹsẹ̀ Bíbélì láti ṣàkóso ìmọ̀lára wa ní ọ̀nà bíi ti Ọlọ́run.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Carol McLeod and Just Joy Ministries fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé díẹ̀ síi, jọwọ lọsí: www.justjoyministries.com