Ìmọ̀lára Mímọ́ - Èsì Látinú Bíbélì sí Ìpèníjà GbogboÀpẹrẹ

Holy Emotions - Biblical Responses to Every Challenge

Ọjọ́ 26 nínú 30

Ọkàn tí ó bàjẹ lápọ̀jù tóbi ju ìbànújẹ́ láṣán ó sì jẹ́ pàṣán sínú ìgbẹ́ṣí ayé wa, pẹ̀lú agbára tí ó yí ohun gbogbo kúrò ní bí ó se rí láíláí. Ọkàn ìbànújẹ́ yóò mú ọ bàjẹ́ pẹ̀lú ìrora àti ìbànújẹ́ pẹ̀lú ìbànújẹ́. Ọkàn tí ó bàjẹ yóò fi ó sílẹ tó oó sì má wá èémí..

Ọlọ́run mọ̀ pé nígbà tí a bá ń gbé ìhà ọ̀run yìí, àwọn ènìyàn yóò wà, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àti àwọn ọ̀ràn tí yóò fọ́ ọkàn àwọn ọmọ Rẹ̀ àyànfẹ́ jẹ́ àti nítorí náà Ó ní ètò kan fún àkókò ìparun jùlọ nínú ìgbésí ayé rẹ.

Ọ̀rọ̀ tí à ńpè ní "bàjẹ́" ní Hébérù ni a pè ní shabar àti pé ó túmọ̀ sí "láti ya pẹ̀lú agbára, run tàbí fífún pa; láti di aláàbọ̀, arọ, láti fọ́ tàbí fọ́." Hébérù àtijọ́ jẹ́ èdè àsọyé púpọ̀ àti nítorínáà ọ̀rọ̀ shabar kò wà pẹ̀lú àsọyé nìkan, ṣùgbọ́n pẹ̀lú àwọn ipò tí o ti lò nínú àpèjúwe. Wọ́n lo ọ̀rọ̀ yìí láti fi ṣàpèjúwe àwọn ọkọ̀ òkun tí wọ́n ti fọ́, tí wọ́n sì ti ya kúrò nínú ìgbòrò rẹ̀ sí ìsàlẹ̀ ìjìnlẹ̀ nítorí ẹ̀fúùfù líle àti ti igbó. Wọ́n tún máa ń lò ó láti fi ṣàpèjúwe bí wọ́n ṣe ń fa ẹran ya, tí wọ́n sì ń fọ́ àwọn ẹranko ìgbẹ́ tí wọ́n ṣe sórí ẹran ọdẹ wọn. O le ṣe ìtumọ ọrọ yí gangan ní "awọn ọkàn tí ó ruru."

Ọ̀rọ̀ náà fún “ọkàn” nínú Ìwé-mímọ pàtó yìí ni ọ̀rọ̀ leb àti pé ó ń tọ́ka ṣí ẹ̀mí tàbí ọkàn ènìyàn. Ó níi se pẹ̀lú ìwá ìhùwàsí ènìyàn, ìyanilẹ́nu, ìmọ̀lára, Ìfẹ́ gidigidi àti pàápà ọkàn àti ìrántí.

Nígbà tí onísáàmù náà kéde pé “Olúwa sún mọ́ àwọn oníròbìnújẹ́ ọkàn,” àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ́ ọ̀rọ̀ tí a sọ pẹ̀lú ìṣọ́ra àti ìyọ́nú púpọ̀. Ó ń rán gbogbo àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì létí ní àwọn àkókò tí ń bọ̀ tí Olúwa ń fi tìfẹ́tìfẹ́ fetísílẹ̀ sí àwọn wọnnì tí wọ́n ń fara da ìrora tí kò ṣeé ronú kàn. Ìrora yìí lè jẹ́ ìjì líle nínú ìgbésí ayé rẹ tàbí láti ọ̀dọ̀ ẹhànnà àti oníwàkiwà ènìyàn, ṣùgbọ́n Olúwa dúró tì ọ́ tìṣọ́ratìṣọ́ra ní àfiyèsí taápọn sí ọkàn rẹ tí ó fọ́ tí ó sì ń sàn.

Tí o bá ti jìyà láti ipò ìdálóró yìí rí, Mo lè dá ọ lójú pé ìwọ kò jáde ní àbójútó Ọlọ́run. Tí ó bá jẹ pé, lónì, o ní ẹdùn ọkàn tí ó sì ṣe ìyàlẹnu báwo ni ìwọ yóò se la ọjọ́ kan sò kọjá, Mo fẹ́ láti tù ọ́ nínú pẹ̀lú ìdánilójú pé Òhun wà pẹ̀lú rẹ ní báyì.

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 25Ọjọ́ 27

Nípa Ìpèsè yìí

Holy Emotions - Biblical Responses to Every Challenge

Ọlọ́run dá ọ Ó sì fi ọ sí àyè tí o wà ní irú àkókò yìí, to love the unlovable, bii àlàáfíà nínú rúkè rúdò, kí o sì fi ayọ̀ tí kò ṣeé dẹ́kun nínú ìṣẹ̀lẹ̀ gbogbo. À ti ṣe bẹ́ẹ̀ lè jọ pé kò ṣeéṣẹ, ṣùgbọ́n o le è ṣeé tí o bá kọ́ oun tí Bíbélì sọ nípa àwọn ìmọ̀lára ọkàn rẹ gẹ́gẹ́ bí ènìyàn àti bí o tilè ṣàkóso wọn. Ètò ẹ̀kọ́ yìí dá lórí àwọn ohun tí a kò kà sí àti nígbà míràn awon ohun ìdojúkọ tí kìí ṣe lásán tí à ń bá pàdé lojojúmọ́, ó sì fún wa ní ìtọ́kasí ẹsẹ̀ Bíbélì láti ṣàkóso ìmọ̀lára wa ní ọ̀nà bíi ti Ọlọ́run.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Carol McLeod and Just Joy Ministries fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé díẹ̀ síi, jọwọ lọsí: www.justjoyministries.com