Ìmọ̀lára Mímọ́ - Èsì Látinú Bíbélì sí Ìpèníjà GbogboÀpẹrẹ

Holy Emotions - Biblical Responses to Every Challenge

Ọjọ́ 29 nínú 30

Lóòtọ́ ni a ní ọ̀tá tí ó ń fi ìgbà gbogbo bá wa jagun nítorípé kò fẹ́ kí a gbé ìgbé-ayé tí Ọlọ́run ní l'étò fún gbogbo wa.

Èṣù kò sinmi nínú ìgbìyànjú rẹ̀ làti jà ọ́ l'ólè ìgbé-ayé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ rẹ. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun-èlò ìjagun ọ̀tá jẹ́ àwọn èrò ara nítorípé kò lè f'ọwọ́kan ẹ̀mí wa látàrí èyí, ète búburú rẹ̀ ni láti bá ọkàn wa sọ̀rọ̀. Ọ̀tá yíó gbìyànjú làti tàn wá pé kí a l'érò pé a yẹ làti máa rìn nínú àìlèdáríjini tàbí pé kò sí ẹni tí ìrora wa jẹ́ l'ógún. Nígbàtí a bá f'ohùn ṣ'ọ̀kan pẹ̀lú rẹ̀ nínú ẹ̀tàn yìí, àwọn ìṣesí ara wa yíó jẹ́ èyí tí ó ṣe àfarawé ohun tí èṣù yàn dípò kí ó jẹ́ tí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Ọlọ́run.

Ọ̀kan l'ára àwọn ọ̀nà tó f'ojú hàn jùlọ tí Sàtàní ń gbà làti mú kí àwọn Krìstìẹ́nì kùnà làti gbé ìgbé-ayé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ni nípa mímúu dá wọn lójú pé wọ́n ní ẹ̀tọ́ sí èrò ara tí ó lòdì. Inú èṣù dún rékọjá nígbàtí o bá f'ẹnu kò pẹ̀lú rẹ̀ pé o l'ẹ́tọ̀ sí àníyàn, oò lè dáríji 'ni tàbí ò ǹ bínú òdì, nígbàyí ni yíó fò f'áyọ̀ nígbàtí ó ti tàn ọ́ láti fárígá, ba ara jẹ́ rékọjá. Ọlọ́run kò fẹ́ kí o f'ẹnu kò pèlú èṣù: Ó fẹ́ kí o dàbí Òun. Ọlọ́run fẹ́ràn rẹ débii pé yí Ó bá ọ wí títí oó fi gbà pé àti ìwọ o àti èṣù o kò sí ẹni tí èrò rẹ̀ dàra ju ti Ọlọ́run lọ!

Bóyá o jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́jọ́ 8 tàbí méjìdínláàdọ́rún 88, kò sí ẹni tí ó gbádùn ìbáwí. Ẹnikẹ́ni tí ó fẹ́ kí Ọlọ́run lo òun l'ọ́nà àrà, yíó ní òye pé ìgbésẹ̀ ẹ̀mí àkọ́kọ́ ní làti borí ìṣe ẹran ara. Ẹran ara rẹ, tí a tún lè dàpè ní èrò ẹni ti ara wà ní àtakò sí ẹ̀mí rẹ àti sí Ẹ̀mí Ọlọ́run nínú rẹ, àyàfi bí o bá ti kọ́ láti tẹ'rí ara ba àti láti pa ara run pẹ̀lú.

Bí ìpòǹgbẹ ọkàn rẹ tó ga jùlọ bá jẹ́ láti jẹ́ àfihàn ńlá èso Ẹ̀mí àti àkópọ̀ ìwà Ọlọ́run, ìdíyelé tí o gbọ́dọ̀ san ni pé kí o pa ara run àti kí o mú èrò ẹran ara rẹ wá sí ìtẹríba. Bí o bá lè f'ọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run nínú ìgbésẹ̀ tó ṣòro yìí, ò ǹ fi ara rẹ sí ààyè tí oó fi lè mú èròǹgbà ńlá Ọlọ́run ṣe ní àsìkò yìí nínú ìtàn ìran ènìyàn.

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 28Ọjọ́ 30

Nípa Ìpèsè yìí

Holy Emotions - Biblical Responses to Every Challenge

Ọlọ́run dá ọ Ó sì fi ọ sí àyè tí o wà ní irú àkókò yìí, to love the unlovable, bii àlàáfíà nínú rúkè rúdò, kí o sì fi ayọ̀ tí kò ṣeé dẹ́kun nínú ìṣẹ̀lẹ̀ gbogbo. À ti ṣe bẹ́ẹ̀ lè jọ pé kò ṣeéṣẹ, ṣùgbọ́n o le è ṣeé tí o bá kọ́ oun tí Bíbélì sọ nípa àwọn ìmọ̀lára ọkàn rẹ gẹ́gẹ́ bí ènìyàn àti bí o tilè ṣàkóso wọn. Ètò ẹ̀kọ́ yìí dá lórí àwọn ohun tí a kò kà sí àti nígbà míràn awon ohun ìdojúkọ tí kìí ṣe lásán tí à ń bá pàdé lojojúmọ́, ó sì fún wa ní ìtọ́kasí ẹsẹ̀ Bíbélì láti ṣàkóso ìmọ̀lára wa ní ọ̀nà bíi ti Ọlọ́run.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Carol McLeod and Just Joy Ministries fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé díẹ̀ síi, jọwọ lọsí: www.justjoyministries.com