Ìmọ̀lára Mímọ́ - Èsì Látinú Bíbélì sí Ìpèníjà GbogboÀpẹrẹ

Holy Emotions - Biblical Responses to Every Challenge

Ọjọ́ 28 nínú 30

Ọlọ́run kò dẹ́kun àti máa jẹ́ Ọlọ́run látàríi pé o wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀. Kò dẹ́kun àti máa jẹ́ Ọlọ́run olóore àti aláàánú nítorípè a já ọ kulẹ̀ tàbí o ní ọgbẹ́ ọkàn.

Gbogbo wa ni ó wù láti gbé ìgbè-ayé wa lórí òkè. Gbogbo wa ni yíò fẹ́ láti mí afẹ́fẹ́ ìtura tútù orí-òkè sínú kí a sì wo òye tí ó rẹwà láti orí-òkè yìí. O lè rí àwọn ǹǹkan lórí òkè tí o kò le rí láí ní pẹ̀tẹ́lẹ̀. Gbogbo ǹǹkan ni ó ma ń ṣe rẹ́gí bí a bá wò wọn láti orí-òkè. Bíi ẹni tí ó wà lókè téńté ayé ni. Ibi tí ó yẹ fún ayaba - ayaba orí-òkè!

Kò sí ẹni tí ó fẹ́ ra ilé sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ ìdààmúdààbo àti ìjákulẹ̀. Àdínkù wà nínú ohun tí ènìyàn lè rí ní ibi kòtò, a kò sì ní lè rí ju àwọn ọ̀gbun igi iwájú wa lọ.

Síbẹ̀ pẹ̀tẹ́lẹ̀ ni àwọn ewébẹ̀ àti òdòdó ti ń wù. Kò sí ìdàgbàsókè lórí òkè ṣùgbọ̀n a ó rí òkúta wẹ́wẹ́ àti ńlá níbẹ̀. Orí òkè kìí ṣe ibi tí a ti lè fi gbòǹgbò múlẹ̀ - pẹ̀tẹ́lẹ̀ ni ìyẹn ti maá ń ṣẹlẹ̀. Ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ ni ìdàgbàsókè ayé rẹ tó ga jù yíó ti wáyé àti pé ibẹ̀ ni èso Ẹ̀mí yíò tí hù nínú alagbalúbú ọ̀pọ̀ yanturu. Jẹ́ kí n kàn sọọ́ báyìí: Ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ níbití ọkàn rẹ ti gb'ọgbẹ́ ni yíó jẹ́ ibi ìkórè rẹ tó ga jùlọ.

Ọlọ́run fẹ́ kí aago rẹ kún àkúnwọ̀sílẹ̀ kìí ṣe nígbàtí ayé bá dáa nìkàn tí gbogbo ǹǹkan rọ̀ ṣọ̀mù; Ó fẹ́ kí aago wa kún àkúnwọ̀sílẹ pẹ̀lú ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ ìrora àti aṣálẹ̀ ìfọ́ká yángá. Ọlọ́run gbé tábìlì ìbùkún ka iwájú rẹ tí yíó wo ọkàn ọgbẹ̀ rẹ sàn tí yíí sì bọ́ ọkàn rẹ tí ebi ń pa.

Ọlọ́run fẹ́ kí o jẹ́ ọkùnrin tàbí obìnrin tí ó mọ̀ pé ìjákulẹ̀ kò ní agbára láti mú òun kúrò. Ọlọ́run fẹ́ kí o jẹ́ ẹni tí yíó súnmọ́ iwájú Rẹ̀ l'àkókò ìbànújẹ́ áti ìpayà. Ọlọ́run fẹ́ kí o jẹ́ Krìstìẹ́nì tí kìí rá'hùn ṣùgbọ́n tí ó maá ń sú're nígbà gbogbo. Ọlọ́run fẹ́ kí o jẹ́ onígbàgbọ́ tí ó ń so èso l'àkókò tí ayé burúkú jù.

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 27Ọjọ́ 29

Nípa Ìpèsè yìí

Holy Emotions - Biblical Responses to Every Challenge

Ọlọ́run dá ọ Ó sì fi ọ sí àyè tí o wà ní irú àkókò yìí, to love the unlovable, bii àlàáfíà nínú rúkè rúdò, kí o sì fi ayọ̀ tí kò ṣeé dẹ́kun nínú ìṣẹ̀lẹ̀ gbogbo. À ti ṣe bẹ́ẹ̀ lè jọ pé kò ṣeéṣẹ, ṣùgbọ́n o le è ṣeé tí o bá kọ́ oun tí Bíbélì sọ nípa àwọn ìmọ̀lára ọkàn rẹ gẹ́gẹ́ bí ènìyàn àti bí o tilè ṣàkóso wọn. Ètò ẹ̀kọ́ yìí dá lórí àwọn ohun tí a kò kà sí àti nígbà míràn awon ohun ìdojúkọ tí kìí ṣe lásán tí à ń bá pàdé lojojúmọ́, ó sì fún wa ní ìtọ́kasí ẹsẹ̀ Bíbélì láti ṣàkóso ìmọ̀lára wa ní ọ̀nà bíi ti Ọlọ́run.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Carol McLeod and Just Joy Ministries fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé díẹ̀ síi, jọwọ lọsí: www.justjoyministries.com