Ìmọ̀lára Mímọ́ - Èsì Látinú Bíbélì sí Ìpèníjà GbogboÀpẹrẹ

Holy Emotions - Biblical Responses to Every Challenge

Ọjọ́ 27 nínú 30

Àṣamọ̀-ọ̀rọ̀ kán wà tó ṣe iyebíye tí Krìstìẹ́nì pẹ̀lú ma ń lò fún ìtùnú nígbà ìnira àti àjálù-ibi, "Àkókò a máa wo gbogbo ọgbẹ́ sàn."

Ṣé kí n sọ fún ọ láì déènà p'ẹnu - MI Ò GBÀ BẸ́É!! Àkókò kò ní agbára nínú ara rẹ̀ láti wòsàn. Ọlọ́run nìkan ni Ó ní agbára ìwòsàn! Mo mọ àwọn obìnrin tí wọ́n kún fún ìkoro ọkàn àti ìbínú lónìí gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe wà ní ọdún mẹ́wàá sẹ́hìn. Àkókò kò ì tíì wo ọkàn wọn sàn. Mo mọ àwọn obìnrin tí wọ́n ń na ìka àbùkù lónìí ju bí wọ́n ti ṣe ní ọgbọ̀n ọdún sẹ́hìn lọ. Àkókò kò ì tíì wo àwọn obìnrin tí ó rẹ̀ kọjá ààla yìí sàn.

Jésù nìkan ni Ó ní agbára ìwòsàn nítorí náà bí o bá ní ọkàn tó gb'ọgbẹ́ tí o sì ń pòǹgbẹ fún ìtura, o ní làti wọ iwájú Rẹ̀ lọ níbití ìyanu ńṣelẹ̀ kìí ṣe látàrí àkókò ṣùgbọ́n látàrí Òun fúnra Rẹ̀. Ṣé ò ń gba ìbáṣepọ̀ tímọ́tímọ́ tì Ó ńfi fún àwọn ọlọkàn wúwo láàyè láti wò ọkàn rẹ sàn lónìí?

Kò sí ẹni tí ó lè wo ọkàn sàn àyàfi Olúwa. Ọ̀rọ̀ àwọn ènìyàn lè gbà ọ́ níyànjú kí ó sì mú ìwòsàn díẹ̀ wá ṣùgbọ́n ìwòsàn pátápátá ńwá láti ọ̀dọ̀ Olúwa nígbà gbogbo. Iṣẹ́ rere àti ọwọ́ ìfẹ́ lè mú ẹ̀dùn kúrò nínú ọkàn, ṣùgbọ́n kò sí ohun tàbí ẹni tí ó lè dé ayé rẹ l'ádé ìwòsàn tòótọ́ bíkòṣe Olúwa. Ó ní agbára, ìfẹ́ àti òye-iṣẹ́ àtọ̀runwá láti wò ọ́ sàn kúrò nínú ìrora kíkorò tí ò ń là kọjá.

Ọlọ́run lè mú ọkàn rẹ padà bọ̀ s'ípò kí Ó sì ṣe iṣẹ́ ìpààrọ̀ ọkàn ti ẹ̀mí fún ọ bí ó bá jẹ́ pé ohun tí ó gbà nìyẹn láti mú ọ lọ sí ibi ìlera àti ìrètí lẹ́ẹ̀kan síi. Èyí lè dàbí pé ó ṣòro nígbàtí ọkàn rẹ bá gb'ọgbẹ́ ṣùgbọ̀n kò ṣòro fún Ọlọ́run! Ìfẹ́ Ọlọ́run nígbà gbogbo ní láti mú padà bọ̀ sípò àti láti wòsàn.
Ohun tí Ẹ̀mí-mímọ́ ń sọ láti ẹnu onísáàmù pé, "- Ó di ọgbẹ́ wọn." lè tètè yé wa. Àwòrán ọ̀rọ̀ tí à ń yà fún wa pẹ̀lú èdè Hébérù yìí ni àpèjúwe aránṣọ tí ó ń rọra tún aṣọ ṣe tí ó sì ń rán aṣọ tí ó ti ya papọ̀. Bí o bá ní ọkàn tó gb'ọgbẹ́, ọ̀rẹ́, mo mọ Ẹnìkan tí Ó ní òye-iṣẹ́ akọ́ṣẹ́moṣẹ́ láti wo ọkàn rẹ sàn ní ìrọ̀rùn àti ní pátápátá. Kìí ṣe pé Ó lè tún ọkàn rẹ ṣe nìkan, ṣùgbón Ó ní ìfẹ́ síi láti ṣe bẹ́ẹ̀.

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 26Ọjọ́ 28

Nípa Ìpèsè yìí

Holy Emotions - Biblical Responses to Every Challenge

Ọlọ́run dá ọ Ó sì fi ọ sí àyè tí o wà ní irú àkókò yìí, to love the unlovable, bii àlàáfíà nínú rúkè rúdò, kí o sì fi ayọ̀ tí kò ṣeé dẹ́kun nínú ìṣẹ̀lẹ̀ gbogbo. À ti ṣe bẹ́ẹ̀ lè jọ pé kò ṣeéṣẹ, ṣùgbọ́n o le è ṣeé tí o bá kọ́ oun tí Bíbélì sọ nípa àwọn ìmọ̀lára ọkàn rẹ gẹ́gẹ́ bí ènìyàn àti bí o tilè ṣàkóso wọn. Ètò ẹ̀kọ́ yìí dá lórí àwọn ohun tí a kò kà sí àti nígbà míràn awon ohun ìdojúkọ tí kìí ṣe lásán tí à ń bá pàdé lojojúmọ́, ó sì fún wa ní ìtọ́kasí ẹsẹ̀ Bíbélì láti ṣàkóso ìmọ̀lára wa ní ọ̀nà bíi ti Ọlọ́run.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Carol McLeod and Just Joy Ministries fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé díẹ̀ síi, jọwọ lọsí: www.justjoyministries.com