Ìmọ̀lára Mímọ́ - Èsì Látinú Bíbélì sí Ìpèníjà GbogboÀpẹrẹ

Holy Emotions - Biblical Responses to Every Challenge

Ọjọ́ 21 nínú 30

Kíni àìsí-ìwúrí gan-an ná? A kò lè pe ẹ̀dùn ọkàn yí ní "ìkárísọ" tààrà nítorí o ṣì lè ṣe àwọn ǹkan mélòó kan pẹ̀lú àìsí-ìwúrí tó dojú kọ ọ́. O ṣì ń gbìyànjú, bó tilẹ̀ jẹ́ pẹ̀lú ìmẹ́lẹ́, láti gbé ẹsẹ̀ l'ọ̀kànkàn. O ṣì lè ní ìtàkúrọ̀sọ pẹ̀lú àwọn èèyàn, bí àwọn èsì rẹ kò tilẹ̀ ní aápọn kankan nínú. O kò tíì lọ fara ṣoko sínú ihò àmọ́ àmọ́ abẹ́ aṣọ ìbora ni ìwọ gọ sí, kò sí ẹni tí kò wùn láti sun àsùnpiyè níbi tó dákẹ́ rọ́rọ́. Lójojúmọ́. Jálẹ̀ ọjọ́ kàànkan.

O ní àǹfààní láti dìde ní òwúrọ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àbọ̀ ohun tí o lè gbé ṣe ni ò ń dáwọ́lé. O kò ní ìkárísọ, àmọ́ bẹ́ẹ̀ ni inú rẹ kò dùn o kò sì ní ìwúrí nípa ǹkankan. Ọjọ́ kan ń tẹ̀lé òmíràn nínú àìrí-kan-ṣèkan. Ó máa ń gbìyànjú láti rẹ́ẹ̀rín lẹ́ẹ̀kàn kan àmọ́ kìíṣe èyí tó dénú. Ò ńṣe àmúlò ìpèníjà láti dìde àti gbé ǹkan ṣe. Ǹkan tí a wá ń sọ yìí. A kò lè sọ pàtó ìwúlò rẹ gan!

Ètò àti ọ̀nà tí o ní lọ́kàn nìyí láti gbé ìgbésí ayé rẹ lójojúmọ́ àti láti borí àwọn àìní-ìwúrí. Ọjọ́ kàànkan tí Ọlọ́run ti fún ọ nínú ọlá ńlá Rẹ̀ jẹ́ àǹfààní titun láti ṣe àkọ́so ọjọ́ kàànkan pẹ̀lú ìyìn. Ọlọ́run ló fi òní dá ọ l'ọ́lá Ó ṣì ní ọ lọ́kàn nígbà tí Ó ṣẹ̀dá rẹ̀. Ó tí ṣètò fún ọjọ́ kàànkan ìwàláàyè rẹ èyí tó ní ìyìn tó níwọ̀n nínú. Tí o bá fẹ́ mọ̀ dájú wípé o wà ní ipasẹ̀ ìfẹ́ Ọlọ́run fún ìgbésí ayé ẹ lójojúmọ́, ó ṣe kókó fún ọ láti bẹ̀rẹ̀ ọjọ́ kàànkan pẹ̀lú ìyìn, èyí tó túmọ̀ sí ṣíṣe ìjọsìn jalẹ̀ ọjọ́ kàànkan àti fífi ìdúpẹ́ ṣe pòkárí ẹ̀. Ní kété tí o bá lajú sáyé dìgbà tí o bá fẹ́ sùn ní àṣálẹ́, fi ṣe ojúṣe láti máa bu ọlá fún Olúwa àti láti má fìgbà kankan yẹ̀ẹ́ lọ́wọ́ wò. A kìíṣe ọmọ tí ń dá Olúwa rẹ̀ l'ẹ́bi, ènìyàn tí ń fi ògo fún Olúwa ni àwa a jẹ́!

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 20Ọjọ́ 22

Nípa Ìpèsè yìí

Holy Emotions - Biblical Responses to Every Challenge

Ọlọ́run dá ọ Ó sì fi ọ sí àyè tí o wà ní irú àkókò yìí, to love the unlovable, bii àlàáfíà nínú rúkè rúdò, kí o sì fi ayọ̀ tí kò ṣeé dẹ́kun nínú ìṣẹ̀lẹ̀ gbogbo. À ti ṣe bẹ́ẹ̀ lè jọ pé kò ṣeéṣẹ, ṣùgbọ́n o le è ṣeé tí o bá kọ́ oun tí Bíbélì sọ nípa àwọn ìmọ̀lára ọkàn rẹ gẹ́gẹ́ bí ènìyàn àti bí o tilè ṣàkóso wọn. Ètò ẹ̀kọ́ yìí dá lórí àwọn ohun tí a kò kà sí àti nígbà míràn awon ohun ìdojúkọ tí kìí ṣe lásán tí à ń bá pàdé lojojúmọ́, ó sì fún wa ní ìtọ́kasí ẹsẹ̀ Bíbélì láti ṣàkóso ìmọ̀lára wa ní ọ̀nà bíi ti Ọlọ́run.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Carol McLeod and Just Joy Ministries fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé díẹ̀ síi, jọwọ lọsí: www.justjoyministries.com