Ìmọ̀lára Mímọ́ - Èsì Látinú Bíbélì sí Ìpèníjà GbogboÀpẹrẹ

Holy Emotions - Biblical Responses to Every Challenge

Ọjọ́ 20 nínú 30

Ó ti jẹ́ ìrírí mi láti ma kùnà lóríi ìyànjú láti yí ìwà àwọn tó ń yọ mí lẹ́nu padà. Kí á má a fi ìmọ̀lára ọkàn dá àwọn ènìyàn tó ṣòro lóhùn kò so èso ìyípadà tó di alẹ́ kankan rí. Mo gbàgbó bóyá pé Ọlọ́run fi ọ́ sínú ayé ẹni tó ṣòro yíì kìí ṣe láti lọ darí ìwà ségesège won, ṣùgbọ́n bí kò ṣe láti gbàdúrà fún wọn. Ìṣirò tó rọrùn tí Ọlọ́run ti fún wa láti fi bá àwọn ẹni ìríra àti oníjọ̀gbọ̀n ẹ̀dá ènìyàn tò ni: Ìfẹ́ + Àdúrà = Ìṣẹ́gun.

Àgbékalẹ̀ Ọlọ́run kìí sáábà la ìmọ̀lára ọkàn lọ bíkòṣe òdiwọ̀n ìfẹ́ àti àdúrà tí a pòpọ̀ tó sì já sí ìṣẹ́gun tó dájú. Ọlọ́run Kò dá ọ láti dàbíi ìjì tó ń jà rànyìn rànyìn, àwọn tí ń fi ọ̀rọ̀ gún ni, fi pani lára, tí wọ́n sì fi ń mú ni dè. Ọlọ́run dá ọ gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin tàbí obìnrin tí ó ní akíkanjú sí Ìjọba Ọlọ́run ju sí ara rẹ̀ lọ. Àwọn ènìyàn tó ṣòro lè sá fún ọ̀rọ̀ rẹ, ṣùgbọ́n wọn kò lè sá fún àdúrà rẹ. A kò gbọdọ̀ a ò sì gbọdọ̀ já okùn ìsopọ̀ láàárín ohun tí a gbàgbọ́ àti bí a ti ṣe ń ṣe sí àwọn ẹlòmíràn, bótiwù ki wọ́n ṣòro tó.

Ààlọ́ àpagbè kan wà lórí ìkorò àti ìbínú; a ń pè é ní ìkáàánú. Ọ̀nà kan wà láti ṣẹ́gun ìbínú àti ariwo; a ń pè é ní ọkàn tútù. Bákannáà ní ọ̀nà tún wà láti ṣẹ́gun sí sọ ọ̀rọ̀ àbùkù; o jẹ jáde gẹ́gẹ́ bíi ìdáríjì.

O gba ìwà àgbà, àti onígbàgbọ́ tó ní ìwà bí Ọlọ́run láti súre fún àwọn tó ń ṣe inúnibíni láyé. À ń fi ahọ́n wa súre, À ń fi ìṣe sí àyà wa súre, ìmọ̀lára ọkàn, àti ìṣe wa. Àwọn kan nínú yín lè máa rò, "Bẹ́ẹ̀ni, ṣùgbọ́n Karo, o kò mọ àntí Matilda mi! Kò fi nkankan jọ ẹnití àá bá fẹ́ràn!" O lè má fẹ́ gbọ́ ìdáhùn mi sí ọ̀rọ̀ àntí Matilda rẹ ṣùgbọ́n báyìí ló rí, Ẹnìkan fẹ́ràn àntí Matilda re orúkọ Rẹ̀ a sì máa jẹ́ Olúwa, fún ìdí èyí tètè bẹ̀rẹ̀ sí hùwà bíi Baba rẹ!

Gbogbo wa ni kò yé ní ẹnití àá fẹ́ ní ọ̀nà kan tàbí òmíràn, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Gbogbo wa la lè jẹ́ ẹlẹ́nu mímú, aláìlè-dákẹ́, àti alárìíyànjiyàn láti ìgbà dé ìgbà, ṣùgbọ́n mo gbàgbọ́ pé ìdí rẹ̀ tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ wa kò ṣe yẹ lẹ́ni tí àá fẹ́ràn nipé ní ọ̀gbun ayé wa lọ́hùn-ún àń sọkún fún ìfẹ́. Ọ̀pọ̀ ìgbà wà tó ṣe pé ìfẹ́ tí a ní sí Ẹ̀luùlú a máa káa lọ́wọ́ kò láti gún ni.

Tí o bá kọ̀ láti dárí jì kí o sì bùkún fún àwọn ènìyàn tí ó fún ọ ní ìṣòro nínú ayé, ìwọ gan-an wà nínú ewu àti di ènìyàn tó ṣòro? Ìṣirò yí kò le yẹ yíò sì ṣe àrídàjú ìṣẹ́gun ní ìkẹyìn:

Ìfẹ́ + Àdúrà = Ìṣẹ́gun!

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 19Ọjọ́ 21

Nípa Ìpèsè yìí

Holy Emotions - Biblical Responses to Every Challenge

Ọlọ́run dá ọ Ó sì fi ọ sí àyè tí o wà ní irú àkókò yìí, to love the unlovable, bii àlàáfíà nínú rúkè rúdò, kí o sì fi ayọ̀ tí kò ṣeé dẹ́kun nínú ìṣẹ̀lẹ̀ gbogbo. À ti ṣe bẹ́ẹ̀ lè jọ pé kò ṣeéṣẹ, ṣùgbọ́n o le è ṣeé tí o bá kọ́ oun tí Bíbélì sọ nípa àwọn ìmọ̀lára ọkàn rẹ gẹ́gẹ́ bí ènìyàn àti bí o tilè ṣàkóso wọn. Ètò ẹ̀kọ́ yìí dá lórí àwọn ohun tí a kò kà sí àti nígbà míràn awon ohun ìdojúkọ tí kìí ṣe lásán tí à ń bá pàdé lojojúmọ́, ó sì fún wa ní ìtọ́kasí ẹsẹ̀ Bíbélì láti ṣàkóso ìmọ̀lára wa ní ọ̀nà bíi ti Ọlọ́run.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Carol McLeod and Just Joy Ministries fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé díẹ̀ síi, jọwọ lọsí: www.justjoyministries.com