Ìmọ̀lára Mímọ́ - Èsì Látinú Bíbélì sí Ìpèníjà GbogboÀpẹrẹ

Holy Emotions - Biblical Responses to Every Challenge

Ọjọ́ 19 nínú 30

Nígbà mìíràn àwọn ènìyàn tí a fẹ́ràn dénú-dénú ló máa ń mú aburú tó nípọn jùlọ jẹyọ nínú wa. Àwọn tí à ń ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú lójojúmọ́ ló sábà ma ń jo oje ìwàpẹ̀lẹ́ ẹ Kristẹni tó wà nínú wa títí tí wọn yóò fi ṣe àfihàn ìdibàjẹ́ tó wà nínú ìṣẹ̀dá wá.

Gbogbo wa la ní àwọn tó ṣòro láti k'ọ́wọ̀ọ́ rìn pẹ̀lú tí Ọlọ́run fúnra rẹ̀ dìídì fi sínú ayé e wa. Àbí ẹ ò rí ǹkan bí?! Ọlọ́run fẹ́ràn rẹ débi wípé ó jẹ́rìí rẹ láti fi inú rere bá àwọn èèyàn líle lò. Ọlọ́run fẹ́ kí èso Ẹ̀mí inú rẹ kí ó máa dàgbà síi, fún ìdí èyí Ó mú kí o fẹ́ obìnrin oní-ìdàrúdàpọ̀ láti po inú rẹ pọ̀ dáadáa. Ọlọ́run nílò àwọn ọkùnrin àti obìnrin ní ìran kààkan tó lè fẹ́ràn àwọn ènìyàn tí kò l'ẹ́ran ìfẹ́ lára, tó lè káàánú àwọn tí kò ní àánú, tó lè ní sùúrù lákòókò ìdàrúdàpọ̀ tí yó sì bùkún fún àwọn ènìyàn tó burú jọjọ.

Ọlọ́run dìídì dá ọ láti fẹ́ràn àwọn tí kò mọ ìwàá hù; Ó fi ọ́ síbí lákòókò yí nínú ìtàn àgbáyé nítorí Ó jẹ́rìí wípé o máa dàgbà ní tòótọ́ àti wípé o ma wá gba ògo Rẹ̀ láàyè láti tàn jáde nínú rẹ sínú òkùnkùn inú ọkàn àwọn ẹlòmíràn. O kò lè gbé eléyìí ṣe nípasẹ̀ ìwà àti kìkó ìmọ̀lára rẹ ní ìjánu, èyí tí o t'ọwọ́ àwọn òbí ì rẹ kọ́. O kò lè ṣe èyí àyàfi tí o bá pinu l'ọ́kàn rẹ wípé o fẹ́ dà bíi Jésù. Nígbà tí o bá ṣe ìpinnu wípé Jésù lofẹ́ f'ìwà jọ, dípò dídàbí ara rẹ. Nígbà tí o bá gbà wípé ọ̀nà Rẹ̀ dára ju tìrẹ lọ, wípé o kò mọ̀ ju Ọlọ́run lọ.

Nígbà tí o bá ṣe àfihàn ìfẹ́ ní àkókò wàhálà tí o sì yàn láti ṣe ìkáàánú dípò ìdàrúdàpọ̀, ǹkan tí ò ń gbìyànjú láti sọ ni wípé, "Mo máa hùwà bíi Baba mi! Inú ẹbí i Rẹ̀ ni mo wà àti wípé bí a ti má ńṣe nìyí! A fẹ́ràn àwọn tí kò l'ẹ́ran ìfẹ́ lára. Ojúṣe ẹbí wa ni láti máa fi ìkáàánú àtọ̀runwá tọrẹ fún àwọn ènìyàn òníjàngbọ̀n." Máṣe gbàgbé láéláé wípé olùbápín lo'jẹ́ nínú ìwà tí a fi fún ọ látọ̀run wá yìí tó mu kó ṣeé ṣe fún ọ láti fẹ́ràn àwọn òníjàngbọ̀n. Ǹkan tí àwọn Kristẹni ma ńṣe nìyí!

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 18Ọjọ́ 20

Nípa Ìpèsè yìí

Holy Emotions - Biblical Responses to Every Challenge

Ọlọ́run dá ọ Ó sì fi ọ sí àyè tí o wà ní irú àkókò yìí, to love the unlovable, bii àlàáfíà nínú rúkè rúdò, kí o sì fi ayọ̀ tí kò ṣeé dẹ́kun nínú ìṣẹ̀lẹ̀ gbogbo. À ti ṣe bẹ́ẹ̀ lè jọ pé kò ṣeéṣẹ, ṣùgbọ́n o le è ṣeé tí o bá kọ́ oun tí Bíbélì sọ nípa àwọn ìmọ̀lára ọkàn rẹ gẹ́gẹ́ bí ènìyàn àti bí o tilè ṣàkóso wọn. Ètò ẹ̀kọ́ yìí dá lórí àwọn ohun tí a kò kà sí àti nígbà míràn awon ohun ìdojúkọ tí kìí ṣe lásán tí à ń bá pàdé lojojúmọ́, ó sì fún wa ní ìtọ́kasí ẹsẹ̀ Bíbélì láti ṣàkóso ìmọ̀lára wa ní ọ̀nà bíi ti Ọlọ́run.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Carol McLeod and Just Joy Ministries fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé díẹ̀ síi, jọwọ lọsí: www.justjoyministries.com