Ìmọ̀lára Mímọ́ - Èsì Látinú Bíbélì sí Ìpèníjà GbogboÀpẹrẹ

Holy Emotions - Biblical Responses to Every Challenge

Ọjọ́ 16 nínú 30

Tí ó bá ní ìṣòro pẹ̀lú ìbẹ̀rù àti àìbálẹ̀ ọkàn, mo lè sọ fún ọ ní pàtó ibi tí ó tí wá! Àwọn Kristẹni tí wọ́n gbà ìbẹ̀rù àti àìbálẹ̀ ọkàn láyè nínú ayé wọn a máà kọ́kọ́ gbọ́ àlàyé láti ọ̀dọ̀ Èṣù fúnra rẹ̀. Jẹ́ kí ń sọ fún Ọ̀ ní konko níbí pé- ó ǹtẹ́tí sí ohùn tí kò tọ́! Ṣe àtúnṣe kí ó sì ṣí Bíbélì rẹ!

Ọrọ Gíríìkì fún "ẹrú" nínú Hébérù àtijọ́ àti Gíríìkì, túmọ̀ sí kí ènìà máà sá lọ fún nkankan tàbí kúrò lọ́dọ̀ ẹnìkan. Nítorí náà, nígbà tí Bíbélì bá pàṣẹ fún wa láti "má bẹ̀rù " nkan tí ó nsọ ní pàtàkì ní pé, "má ṣe sá!" Àwọn díẹ̀ nínú wa lóòtọ́ ní ó ńsa nípa tí ara fún àwọn ohun tí ó ńdẹ́ru bá wà, ṣùgbọ́n ibi tí a tí ńsa gangan ní ọkàn olúkúlùkù wa.

Àwọn ọ̀rọ̀ "má ṣe bẹ̀rù" hàn ní ẹ̀rìnlélógóje ọ̀nà ó kéré jù nínú Bíbélì! Á tí pé nígbà tí Bíbélì bá sọ pé "má ṣe bẹ̀rù", ó túmọ̀ sí wípé má ṣe sá lọ. Nígbà tí ó bá ń bẹ̀rù tàbí dààmú, èyí tí ó fí ńsa lọ, ohun tí ó ní láti ṣe ní láti sá lọ bá Ọlọ́run fún ohun gbogbo tí ó ní fún ọ̀. Ìdí tí Èṣù fí ń gbìyànjú láti fún ọ ní ẹ̀mí ìbẹ̀rù ní pé kí ó lè sá kúrò ní ibi tí ìbùkún àti agbára Ọlọ́run wà. Ìdàkéjì sìsá ni làti tẹ sìwájú. Nígbà tí ó jẹ ọmọ Ọlọ́run ti Ó ga julọ tí ó sì mọ òtítọ́ adùn tí ó wà nínú bí a tí ń sìn Kristi, ìwọ yíò tẹ síwájú. Má ṣe ní èrò míràn tí ó wà láti ọ̀dọ̀ bàbà gbogbo àwọn òpùrọ́, ṣùgbọ́n tẹ síwájú sí ibi àfojúsùn rẹ!

Tí ó bá ńbẹ̀rú ó ńsisẹ́ padà sẹ́hìn sì ìgbà àtijọ́ rẹ àti fún ọ láti jìnà réré sí Ọlọ́run. Bí ó bá tẹ síwájú ó nlọ sí ibi èrè ìpè gíga Ọlọ́run nínú Kristi!

Bí ó tí mọ pé a kò fún ọ ní ẹ̀mí ìbẹ̀rù láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, kíni ohun náà tí Ọlọ́run fí fún ọ? Ó fí Ẹ̀mí agbára, àti tí ìfẹ́ àti tí ọkàn tí ó ye kòóro fún ọ. Ọpọlọ rẹ nílò láti gbá ìfiránsẹ́ pé ó jẹ́ adíye alágbára kan! Ǹjẹ́ o mọ pe Èṣù pápá mọ pe o lágbára? Kò fẹ́ kí ó mọ pe o lágbára rárá! Ṣe ìkéde rẹ loni - kí ó sì pariwo sókè - àti láì bẹ̀rù nkankan:

Èmi kò ní bẹ̀rù ṣùgbọ́n èmi yíò tẹ síwájú sí ọ̀nà gbogbo tí Ọlọ́run bá tọ mí sí! Nibẹ - ṣe ìyẹn kò dára tó?
Ọjọ́ 15Ọjọ́ 17

Nípa Ìpèsè yìí

Holy Emotions - Biblical Responses to Every Challenge

Ọlọ́run dá ọ Ó sì fi ọ sí àyè tí o wà ní irú àkókò yìí, to love the unlovable, bii àlàáfíà nínú rúkè rúdò, kí o sì fi ayọ̀ tí kò ṣeé dẹ́kun nínú ìṣẹ̀lẹ̀ gbogbo. À ti ṣe bẹ́ẹ̀ lè jọ pé kò ṣeéṣẹ, ṣùgbọ́n o le è ṣeé tí o bá kọ́ oun tí Bíbélì sọ nípa àwọn ìmọ̀lára ọkàn rẹ gẹ́gẹ́ bí ènìyàn àti bí o tilè ṣàkóso wọn. Ètò ẹ̀kọ́ yìí dá lórí àwọn ohun tí a kò kà sí àti nígbà míràn awon ohun ìdojúkọ tí kìí ṣe lásán tí à ń bá pàdé lojojúmọ́, ó sì fún wa ní ìtọ́kasí ẹsẹ̀ Bíbélì láti ṣàkóso ìmọ̀lára wa ní ọ̀nà bíi ti Ọlọ́run.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Carol McLeod and Just Joy Ministries fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé díẹ̀ síi, jọwọ lọsí: www.justjoyministries.com