O. Daf 100

100
Orin Ìyìn
1Ẹ ho iho ayọ̀ si Oluwa, ẹnyin ilẹ gbogbo.
2Ẹ fi ayọ̀ sìn Oluwa: ẹ wá ti ẹnyin ti orin si iwaju rẹ̀.
3Ki ẹnyin ki o mọ̀ pe Oluwa, on li Ọlọrun: on li o dá wa, tirẹ̀ li awa; awa li enia rẹ̀, ati agutan papa rẹ̀.
4Ẹ lọ si ẹnu ọ̀na rẹ̀ ti ẹnyin ti ọpẹ, ati si agbala rẹ̀ ti ẹnyin ti iyìn: ẹ ma dupẹ fun u, ki ẹ si ma fi ibukún fun orukọ rẹ̀.
5Nitori ti Oluwa pọ̀ li ore; ãnu rẹ̀ kò nipẹkun; ati otitọ rẹ̀ lati iran-diran.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

O. Daf 100: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa