Ìmọ̀lára Mímọ́ - Èsì Látinú Bíbélì sí Ìpèníjà GbogboÀpẹrẹ

Holy Emotions - Biblical Responses to Every Challenge

Ọjọ́ 10 nínú 30

Ọ̀nà tó lágbára kan ti o fi lè ri dájú pé ò ń dàgbà nínú ẹ̀mí lọ́nà tó lààmì laaka ni gbígbàdúrà láìsinmi. N kò sọ pé máa ráhùn láìsinmi o - ohun tí mo sọ ni pé máa gbàdúrà láìsínmi.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Krìstẹ́nì ló ń gbé ìgbésí ayé wọn nípa kíkùn àti ríráhùn sí Olúwa, tó bá yá wọn á máa wá wòye pé kínni ìdí tí àdúrà àwọn kò fi gbà! Nígbà tí o bá ń gbàdúrà, gbàdúrà pẹ̀lú ayọ̀! Nígbà tí o bá ń gbàdúrà, lọ síwájú Rẹ̀ pẹ̀lú ìgboyà àti agbára! Nígbà tí o bá fẹ́ gbàdúrà, gbé ìmọ̀lára tì sẹ́gbẹ̀ kan kí o sì lọ pẹ̀lú ẹ̀mí tí ó dángájíá sínú Yàrá Ìtẹ́ Mímọ́ kí o sì máa gbádùn ìwàláàyè ìyanu Olúwa!

Ọlọ́run fẹ́ràn rẹ nígbà tí o bá ń ráhùn ... ṣùgbọ́n ìgbà tí o bá da ẹ̀mí rẹ pọ̀ mọ́ È̩mí Ọlọ́run nínú ìyìn tó lágbára ni àwọn ọ̀run máa tó bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ lórí ọ̀rọ̀ rẹ. Gẹ́gẹ́ bíi Krìstẹ́nì, a kìí ṣe àwọn tó jẹ́ pé ìgbà tí nnkan bá ń dán àbí tí nnkan bàbàrà bá ṣẹlẹ̀ ni à ń kọrin tí a sì ń yọ̀, ṣùgbọ́n a jẹ́ àwọn ènìyàn tó ti pinnu láti gbàdùrà tayọ̀tayọ̀ bí nnkan bá tilẹ̀ dàbí pé kò lọ bí ó ti yẹ. Ara ìṣẹ̀dá wa ni kí a wá sí iwájú Rẹ̀ pẹ̀lú ọpẹ́ láìbìkítà ohun tí a ó mú kúrò níwájú Rẹ̀.

Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin Hébérù mẹ́ta yin Ọlọ́run nínú iná àìléru! Pọ́ọ̀lù àti Sílásì kọrin lọ́gànjọ́ òru nínú túbú. Stẹ́fánì jọ́sìn bí wọ́n ṣe ń ju òkúta lù ú! Hánà jọ́sìn nígbà tí kò tíì lóyún! Dara pọ̀ mọ́ àwọn àìlónkà onígbàgbọ́ káàkìri àgbáyé àti láti ìrandíran tí wọ́n ti pinnu láti máa gbàdúrà sí Ọlọ́run tayọ̀tayọ̀.
Ọjọ́ 9Ọjọ́ 11

Nípa Ìpèsè yìí

Holy Emotions - Biblical Responses to Every Challenge

Ọlọ́run dá ọ Ó sì fi ọ sí àyè tí o wà ní irú àkókò yìí, to love the unlovable, bii àlàáfíà nínú rúkè rúdò, kí o sì fi ayọ̀ tí kò ṣeé dẹ́kun nínú ìṣẹ̀lẹ̀ gbogbo. À ti ṣe bẹ́ẹ̀ lè jọ pé kò ṣeéṣẹ, ṣùgbọ́n o le è ṣeé tí o bá kọ́ oun tí Bíbélì sọ nípa àwọn ìmọ̀lára ọkàn rẹ gẹ́gẹ́ bí ènìyàn àti bí o tilè ṣàkóso wọn. Ètò ẹ̀kọ́ yìí dá lórí àwọn ohun tí a kò kà sí àti nígbà míràn awon ohun ìdojúkọ tí kìí ṣe lásán tí à ń bá pàdé lojojúmọ́, ó sì fún wa ní ìtọ́kasí ẹsẹ̀ Bíbélì láti ṣàkóso ìmọ̀lára wa ní ọ̀nà bíi ti Ọlọ́run.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Carol McLeod and Just Joy Ministries fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé díẹ̀ síi, jọwọ lọsí: www.justjoyministries.com