Ìmọ̀lára Mímọ́ - Èsì Látinú Bíbélì sí Ìpèníjà GbogboÀpẹrẹ

Holy Emotions - Biblical Responses to Every Challenge

Ọjọ́ 8 nínú 30

Ọ̀kan lára àwọn iṣẹ́-ṣíṣe ojoojúmọ́ tí oó k'ópa nínú rẹ̀ ni yíyàn láti lò àsìkò nínú ìjọsìn. Ó ṣe pàtàkì kí o ní òye pé àsìkò tí a bá lò nínú ìjọsìn yíó ró ọ l'ágbára láti d'ojúkọ ìjì ayé. Jíjọ́sìn fún Olúwa l'ójoojúmọ́ bí o ṣe ńb'omi sára n'ílé ìwẹ̀, wa ọkọ̀ lọ, tàbí nígbàtí o bá fẹ́ rìn ìrìn afẹ́, yíó fún ọ ní ìwòye ọ̀run l'órí sàkání ayé rẹ. Kíkọ orin nígbàtí o bá ńsisẹ́ ilé yíó ṣe k'óríyá fún ọ yíó sì fi ayọ̀ sí ọ̀kan rẹ. Ǹjẹ́ o jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn Krìsríénì tí ebi ẹ̀mí ńpa tí o jẹ pé Ọjọ́ Ìsinmi nìkan ni won màá ńk'ọrin ìjọ́sìn? Ohun tí ó dára jù nínú àyè ni ò ńpàdánú yìí! Wòó, gbà mí gbọ́ - o kò ní fẹ́ pàdánù ayọ̀ tó wà nínú f'ífọ eérú ayé rẹ dànù, mímú ọ̀fọ̀ kúrò àti gbígbé ẹ̀wù ìyìn tí Jésù pésè fún ọ wọ̀. Pàṣípààrọ̀ tó ga jùlọ nínú àkọsílẹ̀ ìtàn nìyìí: kó gbogbo ìnira àti ẹ̀dún ọkàn rẹ fún Un, Yíò sì fún ọ ní ẹ̀wù ìyìn!

Ìwé mímọ́

Day 7Day 9

Nípa Ìpèsè yìí

Holy Emotions - Biblical Responses to Every Challenge

Ọlọ́run dá ọ Ó sì fi ọ sí àyè tí o wà ní irú àkókò yìí, to love the unlovable, bii àlàáfíà nínú rúkè rúdò, kí o sì fi ayọ̀ tí kò ṣeé dẹ́kun nínú ìṣẹ̀lẹ̀ gbogbo. À ti ṣe bẹ́ẹ̀ lè jọ pé kò ṣeéṣẹ, ṣùgbọ́n o le è ṣeé tí o bá kọ́ oun tí Bíbélì sọ nípa àwọn ìmọ̀lára ọkàn rẹ gẹ́gẹ́ bí ènìyàn àti bí o tilè ṣàkóso wọn. Ètò ẹ̀kọ́ yìí dá lórí àwọn ohun tí a kò kà sí àti nígbà míràn awon ohun ìdojúkọ tí kìí ṣe lásán tí à ń bá pàdé lojojúmọ́, ó sì fún wa ní ìtọ́kasí ẹsẹ̀ Bíbélì láti ṣàkóso ìmọ̀lára wa ní ọ̀nà bíi ti Ọlọ́run.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Carol McLeod and Just Joy Ministries fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé díẹ̀ síi, jọwọ lọsí: www.justjoyministries.com