Ìmọ̀lára Mímọ́ - Èsì Látinú Bíbélì sí Ìpèníjà GbogboÀpẹrẹ

Holy Emotions - Biblical Responses to Every Challenge

Ọjọ́ 7 nínú 30

Tí ìpòǹgbẹ rẹ bá jẹ́ pé kí o ní ẹ̀mí tó l'ágbára, o ní láti fún ẹ̀mí rẹ ní oúnjẹ tó d'ọ́ṣọ́ tó sì ṣe ara lóore. O ní láti ka Bíbélì rẹ l'ójoojúmọ́ láti mú kí okun ẹ̀mí rẹ le kí o sì lè ní àníkún ìdúróṣinṣin nínú ẹ̀mí. A ńka Bíbélì kìí ṣe fún ìròyìn lásán ṣùgbọ́n fún ìyípadà àti agbára ìyanu tí a rí nínú Ọ̀rọ̀ náà tó jẹ́ ohun aṣaralóore àrà-ọ̀tọ̀ tí ó ń fi ìdí ìlera ẹ̀mí wa múlẹ ní ọjọ kọọkan ayé wa.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ló maá ńwá àwáwí fún ìdí rẹ̀ tí wọn kò fi lè ka Bíbélì l'ójoojúmọ́. Àkọ́kọ́ nínú àwáwí náà ni pé, "Kòyé mi. Ó kàn dàbí ọ̀rọ̀ ojú ìwé lásán sí mi ni." Jẹ́ kíngbà ọ́ ní ìyànjú lónìí pé bí ètíbá jẹ́ àwáwí rẹ: tẹ̀síwájú láti máa kàá! Ọlọ́run yíó bá ọ pàdé níbẹ̀ bóyá ọkàn rẹ gba Òtítọ́ ayérayé tí a rí nínú Ọ̀rọ̀ náà àbí kò gbàá. Kódà bí ọkàn rẹ kò bá 'gba mú" ... ẹ̀mí rẹ ńfàá sínú!

Ohun tí ó yẹ kí o yàn ni láti máa fún ẹ̀mí rẹ ní ohun aṣaralóore tí yíò jẹ́ kí ó l'ágbára tí yíó sì sanra kódà nígbàtí ọkàn rẹ bá ṣáko. Kíka Bíbélì rẹ lóòrèkóòrè ni àkọ́kọ́ nínú ìwà tí o ní láti kọ́ nípa t'ẹ̀mí kí o baà lè jẹ́ ẹni tí ó lera tí ó sì jáfáfá nínú èrò ara.

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 6Ọjọ́ 8

Nípa Ìpèsè yìí

Holy Emotions - Biblical Responses to Every Challenge

Ọlọ́run dá ọ Ó sì fi ọ sí àyè tí o wà ní irú àkókò yìí, to love the unlovable, bii àlàáfíà nínú rúkè rúdò, kí o sì fi ayọ̀ tí kò ṣeé dẹ́kun nínú ìṣẹ̀lẹ̀ gbogbo. À ti ṣe bẹ́ẹ̀ lè jọ pé kò ṣeéṣẹ, ṣùgbọ́n o le è ṣeé tí o bá kọ́ oun tí Bíbélì sọ nípa àwọn ìmọ̀lára ọkàn rẹ gẹ́gẹ́ bí ènìyàn àti bí o tilè ṣàkóso wọn. Ètò ẹ̀kọ́ yìí dá lórí àwọn ohun tí a kò kà sí àti nígbà míràn awon ohun ìdojúkọ tí kìí ṣe lásán tí à ń bá pàdé lojojúmọ́, ó sì fún wa ní ìtọ́kasí ẹsẹ̀ Bíbélì láti ṣàkóso ìmọ̀lára wa ní ọ̀nà bíi ti Ọlọ́run.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Carol McLeod and Just Joy Ministries fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé díẹ̀ síi, jọwọ lọsí: www.justjoyministries.com