Ìmọ̀lára Mímọ́ - Èsì Látinú Bíbélì sí Ìpèníjà GbogboÀpẹrẹ
O ní ọkàn o sì ní ẹ̀mí.
Ẹ̀mí ì rẹ ni ipele ìṣẹ̀dá rẹ tó ga jù tí ọkàn rẹ sì wà lábẹ́ ẹ rẹ̀. Ẹ̀mí náà ni ìlànà ìyè tí Ọlọ́run fi fún ẹ̀dá ènìyàn àti wípé ó jẹ́ ẹ̀yà ìṣẹ̀dá à rẹ tó lè wòye nípa àwọn ǹkan ayérayé. Ó máa ṣòro fún ọ láti rìn nípa ìgbàgbọ́ tí o kò bá ní ẹ̀mí. A rọ ẹ̀mí rẹ láti máa rìn nípa ìgbàgbọ́ àti ọkàn rẹ láti máa rìn nípa ti ara.
Martin Luther sọ wípé “ẹ̀mí jẹ́ ẹ̀yà ọmọnìyàn tó ga tó sì l'ọ́lá jùlọ, èyí tó lè mú u ní òye àwọn ǹkan tó takókó, ǹkan ayérayé, àti èyí tí a kò lè fojú rí.” said."
Ọkàn rẹ jẹ́ ibùjókòó ìwà rẹ, ìmọ̀lára rẹ, ìlépa, ǹkan tí o nífẹ̀ẹ́ sí, àti èyí tí o kórìíra. Lọ́rọ̀ kan, ọkàn rẹ ló ń bí gbogbo ìmọ̀lára ọmọnìyàn tí o ní. Nígbà tí Bíbélì bá sọ̀rọ̀ nípa ọkàn rẹ, ó ń sọ nípa ǹkan tó lè ṣúgbàà àwọn èsì ìmọ̀lára rẹ sí ìdojúkọ ayé.
Ní Lúùkù 12, Jésù sọ ìtàn nípa àgbẹ̀ ọlọ́rọ̀ kan tó rí t'ajé ṣe. Nígbà tí kò sí àyè mọ́ fún àgbẹ̀ ọlọ́rọ̀ yí láti kó erè oko rẹ̀ sí, ó pinu láti wó abà a rẹ̀ àtijọ́ lulẹ̀ ó sì kọ́ èyí tó tóbi, pẹ̀lú owó iyebíye. Inú ọmọkùnrin yìí dùn nípa ọrọ̀ ajé rẹ tó gbórí sókè tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tó sọ lọ́kàn rẹ wípé “ìwọ ọkàn mi, o ní ìṣúra tí yóò tó ọ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún; wọnú ìsinmi rẹ lọ, jẹ, mu, kí o sì máa yọ̀” (v. 19).
Ọlọ́run gbọ́ èrò ọkùnrin òní ìgbéraga yí inú rẹ̀ sì bàjẹ́ nítorí gbogbo ayé ọkùnrin náà dá lé kíkó ìṣúra jọ láì ronú nípa ayérayé. Àgbẹ̀ náà, tí ọkàn rẹ̀ kún fún ìdùnnú tí abà rẹ̀ sì kún fún erè oko, ní ẹ̀mí tó ṣófo tó sì ti kú pẹ̀lú.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Kristẹni ni ó máa ńṣe irú àṣìṣe tí àgbẹ̀ ọlọ́rọ̀ inú ìtàn Jésù yí ṣe. Gbogbo ìgbà ni à ń bọ́ ẹnu wá ṣùgbọ́n tí ẹ̀mí wa ń ṣófo. Tí gbogbo ìgbésí ayé rẹ bá dá lórí ìṣúra àti afẹ́ ayé, mọ̀ dájú wípé ọkàn rẹ máa yà bàrá kúrò ní ipasẹ̀ òtítọ́. Fún mi ní ìyànda láti bèrè ìbéèrè kan tó nííṣe pẹ̀lú bí a ti ń kó ìmọ̀lára wa ní ìjánu, Ìsọ̀rí ìṣẹ̀dá rẹ wo ló lágbára jù lọ? Ṣé ọkàn rẹ ni? Àbí ẹ̀mí rẹ? Fún oníkálukú onigbagbọ, èsì tó yẹ kí wọ́n fi dáhùn ni, "Ẹ̀mí ì mi!"

Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Ọlọ́run dá ọ Ó sì fi ọ sí àyè tí o wà ní irú àkókò yìí, to love the unlovable, bii àlàáfíà nínú rúkè rúdò, kí o sì fi ayọ̀ tí kò ṣeé dẹ́kun nínú ìṣẹ̀lẹ̀ gbogbo. À ti ṣe bẹ́ẹ̀ lè jọ pé kò ṣeéṣẹ, ṣùgbọ́n o le è ṣeé tí o bá kọ́ oun tí Bíbélì sọ nípa àwọn ìmọ̀lára ọkàn rẹ gẹ́gẹ́ bí ènìyàn àti bí o tilè ṣàkóso wọn. Ètò ẹ̀kọ́ yìí dá lórí àwọn ohun tí a kò kà sí àti nígbà míràn awon ohun ìdojúkọ tí kìí ṣe lásán tí à ń bá pàdé lojojúmọ́, ó sì fún wa ní ìtọ́kasí ẹsẹ̀ Bíbélì láti ṣàkóso ìmọ̀lára wa ní ọ̀nà bíi ti Ọlọ́run.
More
A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Carol McLeod and Just Joy Ministries fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé díẹ̀ síi, jọwọ lọsí: www.justjoyministries.com