Ìmọ̀lára Mímọ́ - Èsì Látinú Bíbélì sí Ìpèníjà GbogboÀpẹrẹ
Àwọn ìmọ̀lára rẹ a máa yára ní ìlọ́po ọ̀kẹ́ méjì ju èrò ọkàn lọ. Èyí yani lẹ́nu àbí? Àlàyé kan ṣoṣo yìí ràn wá lọ́wọ́ láti lóye èrèdí rẹ̀ nígbà tí aburú bá ṣẹlẹ̀, a máa ní ìmọ̀lára tí ń gbo'ni àti èyí tí a kò lè fọwọ́ bò, àmọ́ a kì í lè rántí ohun tí a ní láti ṣe tàbí ẹni tí a lè ké pè lẹ́sẹ̀kẹkẹ̀. Ní ìdàkejì, irúfẹ́ ìrírí yìí náà la máa ń ní nígbà tí ǹkan ìyanu bá ṣẹlẹ̀ tí ìdùnnú àti ìmọ̀lára bá kún inú wa, ní irú àkókò yí a kò ní ọgbọ́n àpilẹ̀rọ nípa ìgbésẹ̀ tó kàn. Lẹ́yìn tí gbogbo ìmọ̀lára wa bá ti farahàn tán ni a tó lè gbèrò àti sọ ọpọlọ kalẹ̀.
Ìṣọwọ́ yára àwọn èsì ìmọ̀lára wa sí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ayé wa máa ń ràn wá lọ́wọ́ láti mọ èrèdí rẹ̀, kódà, àwọn Kristẹni pẹ̀lú a máa hùwà pẹ̀lú ìdarí ìmọ̀lára dípò ọgbọ́n àpilẹ̀rọ. Ohun kan - tàbí Ẹnìkan - ní láti jẹ́ ìjánu fún ìmọ̀lára rẹ, tó ń sáré àsá-pajúdé, tí kò sì fẹ́ tẹríba fún àwọn ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́. Tí o bá tẹ̀síwájú láti gba ìmọ̀lára láàyè láti máa darí ìgbésí ayé rẹ, gbogbo ìgbà lo máa ma sọ àwọn ǹkan tí ń dójú tini, hùwà ní ọ̀nà tí kò bójúmu, àti wípé ó máa ṣòro láti di irúfẹ́ ènìyàn tí Ọlọ́run gbèrò fún ọ láti dà. Ìgbẹ̀yìn rẹ á wá dàbí ìdúgbàmù àpáta gbígbóná, tí ń pa gbogbo ǹkan tó wà lọ́nà rẹ̀ run.
Àwọn ǹkan tó ṣe pàtàkì tó ṣíṣe ìpamọ́ ìṣàkóso ọkàn wa kò wọ́pọ̀.
Nígbà tí a bá lo ọ̀rọ̀ yí "ọkàn," pàápàá jù lọ nínú Májẹ̀mú Láéláé, ó ń tọ́ka sí orísun òye, ìmọ̀lára àti ìtara wa. Ọkàn rẹ ló máa ńṣe ìpinnu bí o ṣe máa hùwà ní ipòkipò tí o bá wà, àti wípé òun ni ibùjókòó gbogbo èrèdí àti ìwúrí fún ìwàláàyè rẹ. Bíbélì gbà wá n'ímọ̀ràn láti "dáàbò bo" tàbí láti "ṣọ́" ipele ìgbésí ayé wa yìí pẹ̀lú àkíyèsí tó nípọn.
Ọkàn rẹ ṣe iyebíye sí Ọlọ́run àti wípé o ní láti tọ́jú rẹ̀ bíi ìṣúra iyebíye.
Ọkàn yí gan-an wá ní ìjọ̀gbọ̀n ibẹ̀: ọkàn rẹ kò káràmásìkí ìdáàbòbò. Ó wùn ún láti máa fọ gbogbo èrò àti ìpinnu àti èròngbà rẹ̀ jáde. Ọkàn rẹ ní ìtara láti ṣe àfihàn àti láti sọ nípa gbogbo ìrírí ìmọ̀lára tí ó ti ní. Bíbélì kò fìgbà kankan sọ wípé a ní àǹfààní láti sọ gbogbo ohun tí ó bá wá sí wa lọ́kàn - ó kàn ní kí a ṣe ìdáàbòbò rẹ ni.

Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Ọlọ́run dá ọ Ó sì fi ọ sí àyè tí o wà ní irú àkókò yìí, to love the unlovable, bii àlàáfíà nínú rúkè rúdò, kí o sì fi ayọ̀ tí kò ṣeé dẹ́kun nínú ìṣẹ̀lẹ̀ gbogbo. À ti ṣe bẹ́ẹ̀ lè jọ pé kò ṣeéṣẹ, ṣùgbọ́n o le è ṣeé tí o bá kọ́ oun tí Bíbélì sọ nípa àwọn ìmọ̀lára ọkàn rẹ gẹ́gẹ́ bí ènìyàn àti bí o tilè ṣàkóso wọn. Ètò ẹ̀kọ́ yìí dá lórí àwọn ohun tí a kò kà sí àti nígbà míràn awon ohun ìdojúkọ tí kìí ṣe lásán tí à ń bá pàdé lojojúmọ́, ó sì fún wa ní ìtọ́kasí ẹsẹ̀ Bíbélì láti ṣàkóso ìmọ̀lára wa ní ọ̀nà bíi ti Ọlọ́run.
More
A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Carol McLeod and Just Joy Ministries fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé díẹ̀ síi, jọwọ lọsí: www.justjoyministries.com