Ìmọ̀lára Mímọ́ - Èsì Látinú Bíbélì sí Ìpèníjà GbogboÀpẹrẹ

Holy Emotions - Biblical Responses to Every Challenge

Ọjọ́ 4 nínú 30

Lóòótọ́ mi o ni àwọn ìdáhùn onídán fún àwọn èrò ìmọ̀lára rè tó ń ru sókè, àmọ́ mo ni ìjìnlè òye nínú òrò Olórun fún e. Tí ó bá fé àgbàrá láti borí àtipe ti o bá yán hànhàn fún àgbàrá láti di ẹnì ti Olórun dá e láti jé, nígbà náà lo máa kókó béèrè fún àgbàrá E. Lẹ́yìn ìgbà ti o bá béèrè fún àgbàrá, ó máa dúró fún àgbàrá náà. Bí o ń se dúró fún àgbàrá náà, ó máa má se ìfọkànsìn pẹ̀lú àdúrà.

Àdúrà máa yi mi padà. Mo ń hùwà dáadáa nígbàti mo bá gbàdúrà. Àwọn ẹbí mi máa túbọ̀ féràn mi ti mo ba gbàdúrà nígbà ti mo ń dúró. Tí mo Bá gbàdúrà, mo máa ṣèpinnu tó mọ́gbọ́n dání, Mo máa jé ẹ̀dá ara mi tó láàánú to si dára. Bóyá ìdí ti o kò fi féràn ara e lásìkò rògbòdìyàn àwọn èrò ìmọ̀lára ni pé o i ti nirírí àgbàrá tàbí ipò ìdúró. Àwọn ènìyàn to lágbára ju ti mò ni àwọn arákùnrin àti arábìnrin Olórun tan féràn láti máa dúró dè Olórun nínú àdúrà lórí orúnkún won. Ìkúnlè kìí se ohun àjèjì, kìí se ohun to nira fún àwọn ènìyàn tón yí ìtàn pàdà nítorí wón ní òye pé àwọn èèyàn tón gbàdúrà lóòótọ́ ni a fi àgbàrá ọ̀run fún lójoojúmo ayé wón.

Ṣé o máa ń fojú kéré àkókò tí ó bá lọ lójoojúmo lórí orúnkún rẹ, èyí tó dájú pé o má ràn e lówó láti borí àwọn èrò ìmọ̀lára ̣lára rè ti apá kò ká. Àwọn èrò ìmọ̀lára máa jé asetinú, wón máa dàbí òdó àti nígbà mìíràn o máa gbóná àti òkan lára ipà tó lágbára jù lo láti kápá àwọn èrò ìmọ̀lára wa ni àkókò tí a bá fi gbàdúrà.
Ìwòsàn tó máa ṣẹlẹ̀ nínú ọkàn èèyàn nígbà ti ara mbè nípò àdúrà o jé ohun ìyé àti ohun ìyànu. Mi ò lè dá bi Jésù láìsí àkọ́kọ́ àdúrà lórí orúnkún mi.

Mo le "sé" bí Jésù láìsí àdúrà. Mo lè gba ẹ̀bùn fún rirẹ́rìn-ín músẹ́ àti kíka àwọn ọ̀rọ̀ dídùndídùn nígbà ti ọkàn mi kò ni ìsinmi ti o si ni èmí ìgbẹ̀san lọ́kàn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Mo mò ọ̀rọ̀ to yé láti sò, ó lè fé má ṣàkíyèsí èéfínń tó ńtú jáde látinú nínú etí mi méjèèjì! Jésù kò fẹ́ ki kan má se bi Òun lásán, àmọ́ O yán hànhàn fún mi láti dàbí Òun, ìyàtò ti a máa ṣèpinnu e mbè láàrín wón. Ìyàtò náà na ṣẹlẹ̀ nígbà ti o ba dúró ti mo gbàdúrà nítorí nígbà náà Lo má jé Olúwa lórí àwọn èrò ìmọ̀lára mi àti èrò mi pátá.
Ọjọ́ 3Ọjọ́ 5

Nípa Ìpèsè yìí

Holy Emotions - Biblical Responses to Every Challenge

Ọlọ́run dá ọ Ó sì fi ọ sí àyè tí o wà ní irú àkókò yìí, to love the unlovable, bii àlàáfíà nínú rúkè rúdò, kí o sì fi ayọ̀ tí kò ṣeé dẹ́kun nínú ìṣẹ̀lẹ̀ gbogbo. À ti ṣe bẹ́ẹ̀ lè jọ pé kò ṣeéṣẹ, ṣùgbọ́n o le è ṣeé tí o bá kọ́ oun tí Bíbélì sọ nípa àwọn ìmọ̀lára ọkàn rẹ gẹ́gẹ́ bí ènìyàn àti bí o tilè ṣàkóso wọn. Ètò ẹ̀kọ́ yìí dá lórí àwọn ohun tí a kò kà sí àti nígbà míràn awon ohun ìdojúkọ tí kìí ṣe lásán tí à ń bá pàdé lojojúmọ́, ó sì fún wa ní ìtọ́kasí ẹsẹ̀ Bíbélì láti ṣàkóso ìmọ̀lára wa ní ọ̀nà bíi ti Ọlọ́run.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Carol McLeod and Just Joy Ministries fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé díẹ̀ síi, jọwọ lọsí: www.justjoyministries.com